Àwọn ọ̀dọ́ l'Osun ṣe ìwọ́de nítorí ọ̀wọ́ngógó tó gbòde

Aworan Olufẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Alhaji Waheed Lawal

Ogunlọgọ awọn ọdọ niluu Osogbo, to jẹ olu ilu ipinlẹ Osun lo bẹ sita lati se iwọde lori bi ọwọngogo se gba ode lorilẹede Naijiria.

Awọn ọdọ naa kesi ijọba lati mu idẹrun ba inira ti ọpọ awọn ọdọ lorilẹede Naijiria n la kọja lasiko yii.

Awọn olufẹhonuhan lo tu sita pẹlu awọn asia to n pe ijọba si akiyesi lati se ohun to tọ ati ohun to yẹ nipa iṣejọba ti yoo mu dẹ araalu lọrun.

“A wa o le mu mọra mọ o, eeyan ni wa, ẹ ma ṣe fiya jẹ wa gẹgẹ bii araalu.,” eyi ni awọn orin ti awọn olufẹhonuhan mu bọ ẹnu.

Ọpọ awọn ọlọpaa lo wa pẹlu awọn lasiko ti wọn se iwọde yii sugbọn eyi ko dẹkunj kikọ orin ti wọn mu bọ ẹnu lati salaye bi nnkan se ri lasiko yii fun araalu.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Waheed Lawal. Alaga Osun Civil Societies Coalition, jẹ ko di mimọ pe iwọde yii yoo tẹsiwaju titi ijọba apapọ yoo ojuti si bi nnkan se niran fun awọn orilẹede Naijiria bayii.

“Ijọba gbọdọ wa nnkan se si bi nnkan se si bi ara se n ni awọn eeyan. Wọn gbọdọ wa gbogbo ọna ti wọn mọ lati ri pe awọn eeyan gbe igbe aye to rọrun.

“Awọn ọmọ Naijiria ni lati gbe aye to dara. Wọnse ileri fun wa ko ni igbagbọ ninu awọn sugbọn iya lo ba de fun wa.

“A kabamọ pe a ni igbagbọ ninu wọn nitori iya ati inira ni wọn mu wa fun ati eto ọrọ aje wa.

”Nnkan ti awọn ọmọ Naijiria fẹ ni lati gbe igbe aye alaafia. A ko fẹ bi eto abo se mẹyẹ ni agbegbe wa mọ. A ko le rin irinajo lati Osogbo lọ si Ibadan lai jaya. Gbogbo ero wa ni pe wọn yoo ji wa gbe.

“Bi wọn se n ji awọn lọbalọba gbe ti jẹ ohun lemọlemọ bayii. A rọ ijọba lati pese eto abo fun ẹmi ati dukia awọn araalu. Ẹtọ wa ni, ti a lẹtọ si labẹ ofin.

Ki lo sẹlẹ saaju?

Bẹẹ ba gbagbe, awọn olugbe ilu Minna to jẹ olu ilu ipinlẹ Niger naa fọn si igboro lati fi ẹhonu han lori ọwọngogo ohun jijẹ ati lilo lorilẹede Naijiria.

Awọn oluwọde naa di gbogbo opopona to ṣe pataki ni ilu naa lasiko ifẹhonu han ọhun

Awọn obinrin ati ọdọ pọ lara awọn oluwọde naa ti wọn si n kọ orin ẹhonu lọlọkan o jọkan lori bi nnkan ṣe gbe owo lori ni Naijiria.

Lara awọn oluwọde naa to ba BBC News sọr ṣalaye pebi ọwọngogo ṣe jọba lori eto ọrọ aje ni Naijiria ti ko si da bi ẹni pe ijọba apapọ orilẹede Naijiria n ṣe ohun to to loju awọn lati wagbo dẹkun si i.