Àwọn àgbẹ̀ ké gbàjarè lọ sí ààfin Soun Ogbomoso lórí ìkọlù àwọn darandaran

Awọn oluwọde naa ni ilu Ogbomosho

Oríṣun àwòrán, OgbomosoInsightonline

Ọgọrọ awọn agbẹ lati ijọba ibilẹ Oriire ni agbegbe Ogbomọṣọ ti pariwo sita lori ikọlu awọn darandaran to n waye ni lemọlemọ ni ayika wọn.

Awọn agbẹ naa fi aidun inu wọn han l'Ọjọbọ, lasiko ti wọn ṣe ifẹhonuhan lọ si aafin Ṣọun ilẹ Ogbomọṣọ, Ọba Afolabi Ghandi Olaoye.

Wọn parọwa si Ọba alade naa ati awọn alẹnulọrọ lati gba wọn lọwọ ikọlu awọn ẹni afẹsunkan naa.

Aṣoju ẹgbẹ awọn agbẹ to le iwaju ifẹhonuhan naa, Aremu Ogundare ṣe alaye wi pe lati ilu mẹta ọtọọtọ ni awọn agbẹ naa ti korajọpọ lati pariwo sita. Awọn ilu naa ni, Kedo Arigbeyo, Kedo Salami, ati Mosunmaje.

Ogundare gbarata wi pe iranlọwọ Ọba alade naa ni awọn nilo lati dẹkun awọn ikọlu to n ṣe akoba fun okoowo ati dukiya wọn.

Awọn oluwọde naa ni ilu Ogbomosho

Oríṣun àwòrán, OgbomosoInsightonline

O ni, "Awọn maalu ti ṣe ọpọlọpọ akoba fun wa. Wahala yii bẹrẹ ni bii ọdun mẹrin si marun un sẹyin. A ko gbadun oko dida bii tẹlẹ mọ, gbogbo oko ẹgẹ ti a gbin ati kaṣu si ni wọn ti da maalu wọ. Ati bọ awọn aya ati ọmọ wa ti le koko de ibi pe a ko ri owo ile ẹkọ awọn ọmọ wa san".

Aṣoju ẹgbẹ awọn agbẹ naa fi kun ọrọ rẹ wi pe ọpọlọpọ igba ni awọn ti lọ fi ẹjọ sun alaga ijọba ibilẹ ati ileeṣẹ ọlọpaa, ṣugbọn pabo ni igbiyanju wọn ja si. O ni ọpọlọpọ igba ni awọn darandaran yii maa n ṣa awọn agbẹ ni ada, ti wọn a si pa ẹnikẹni to ba gbiyanju lati da wọn duro; idi si niyii ti awọn fi wọde wa si aafin Ṣọun ilẹ Ogbomọṣọ lati beere fun iranwọ.

Laipẹ yii ni BBC Yoruba jabọ iroyin lori pasitọ kan ti awọn afurasi darandaran pa sinu oko rẹ ni agbegbe Ogbomọṣọ.

Awọn oluwọde naa ni ilu Ogbomosho

Oríṣun àwòrán, OgbomosoInsightonline

Oloogbe naa, Segun Adegboyega tawọn afurasi Fulani darandaran ṣeku pa loko rẹ ni agbegbe Gege to wa ni opopona Ogbomoso si ilu Iseyin ti sọ pe lasiko ti o n kilọ fawọn darandaran to da ẹran jẹ oko rẹ ni wọn gun un lọbẹ pa.

Awọn darandaran naa ni won ko ẹran wọn jẹ oko Pasitọ Adegboye lọjọ Ajẹ ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kinni ọdun yii ti oloogbe naa si koju wọn lati dẹkun iwa ibi wọn.

Ẹgbọn oloogbe naa, Taiwo Adegboyega sọ fun BBC Yoruba pe "ile ẹkọ ni pasito Segun wa nigba ti iyawo rẹ pe e lati wa ba awọn darandaran to da ẹran wọn gba inu oko iṣu rẹ. Lẹyin ọrẹyin ni ẹmi ẹni to ni oko ba bọ si ọwọ awọn to daran jẹko.