Nǹkan tí a mọ̀ nípa tọkọtaya Adelabu tí wọ́n déédé bá òkú wọn nínú ilé wọ́n l’Akure

Ọkunrin ati obinrin to jẹ ololufẹ

Oríṣun àwòrán, PER-ANDERS PETTERSSON

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abayọmi Ọladipọ ti paṣẹ pe ki iwadii kikun bẹrẹ lori ohun to ṣokunfa iku gbajugbaja oniṣowo kan niluu Akurẹ, Sesan Adelabu ati iyawo rẹ, Boluwatife Adelabu.

Adelabu ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Emirate kaakiri igboro ni iroyin ti a ko ti i le fidirẹ mulẹ sọ pe o gbẹmi ara rẹ lojiji, lẹyin to ti ṣa iyawo rẹ, Bolu pa ninu ile wọn to wa ni Alagbaka niluu Akurẹ.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami fi sita, o ni ọga awọn ti paṣẹ fun ẹka ileeṣẹ wọn to n ri si iwa ọdaran, lati tọpinpin ohun to ṣokunfa iku tọkọ-taya naa.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe niṣe ni Adelabu to ni ile-epo Emirate gbe oogun apẹfọn mu lati fi gba ẹmi ara rẹ lalẹ ọjọ Ẹti, ọsẹ to pari.

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni a ko tii gbọ kulẹkulẹ ohun to fa idi ti wọn ni Adelabu fi ṣa iyawo rẹ pa, t'oun naa si tun gba ẹmi ara rẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe ni ọjọ kẹsan, oṣu Keji, ọdun 2024, ni ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun ‘A’ niluu Akurẹ gba ipe pajawiri lati ọdọ awọn alaabo ọkunrin naa

“Ọlọpaa to n ṣọ oloogbe naa nile rẹ to wa ni luuadugbo Alagbaka ni Akurẹ lo gba ipe lati ọdọ ọmọ oloogbe naa ni nnkan bi agogo mẹfa irọlẹ, to si n beere baba rẹ.

“Ọmọ naa sọ pe baba oun ko gbe ipe rẹ. Ọlọpaa naa lọ sinu ile lati sọ fun ọga to n ṣọ nipa ọmọ rẹ to n pe e ti ko gbe e, to si jẹ iyalẹnu nigba to ba oloogbe naa to doju delẹ.

“Ẹnu ọna baluwẹ ni oku oloogbe naa wa, nigba to ba oku iyawo oloogbe naa lori bẹẹdi inu yara wọn pẹlu ọgbẹ ada lara, lori ati oju rẹ.

Ike ofifo to jẹ ti oogun apẹfọn ni wọn tun ba nitosi iṣẹlẹ ọhun.