Kí ló wà nínú òfin iná mọ̀nàmọ̀nà tuntun tí Ààrẹ Tinubu búwọ lù

Aworan Aare Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, ASIWAJU BOLA AHMED TINUBU/FACEBOOK

Aarẹ Naijiria, Bọla Ahmẹd Tinubu ti buwọ lu abadofin tuntun fun ina mọnamọna lorileede yii, eyi ti wọn pe ni Electricity Act Amendment Bill (2024).

Ọjọ Ẹti, ọsẹ yii, ọjọ kẹsan, oṣu keji, ọdun 2024 ni Aarẹ Tinubu buwọ lu iwe ofin tuntun ọhun.

Abadofin tuntun ti ọdun 2024 yii ni wọn fi mu iyipada ba bi wọn ṣe n ṣeto ipese ati pipin ina mọnamọna ni Naijiria.

Ọjọ kẹsan, oṣu kẹfa, ọdun 2023 ni Aarẹ Tinubu ti kọkọ buwọ lu agbeyẹwo ofin ti wọn ṣe tẹlẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Aṣoju-ṣofin Babajimi Benson to n ṣoju ẹkun Ikorodu Federal Constituency nipinlẹ Eko nile igbimọ aṣofin kekere l’Abuja lo gbe abadofin naa siwaju ile.

Lẹyin eyi ni wọn tun gbe e lọ siwaju ile igbimọ aṣofin agba, ko to di pe o de iwaju Aarẹ Tinubu to ṣẹṣẹ buwọ lu.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2023 ni ile igbimọ aṣofin ti kọkọ fontẹ lu abadofin yii.

Aworan ibi ipese ina

Oríṣun àwòrán, Ibi ipese ina/Getti Images

Ki ni ofin yii tunmọ si fun awọn ọmọ Naijiria

Ofin tuntun yii jẹ eyi ti wọn ṣagbeyẹwo rẹ si ti ọdun 2024, nibi ti awọn idagbasoke ti waye nipa awọn agbegbe ti ọrọ kan.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Yoo mu ki awọn adugbo ti ina mọnamọna gba kọja maa gba ida marun-un ninu owo ti ileeṣẹ to n pese ina mọnamọna (GENCOs) n pa lọdọọdun.

Ofin yii yoo ya owo idagbasoke sọtọ fun awọn agbegbe yii, awọn alakoso ti awọn agbegbe yii ati ileeṣẹ GENCO ba yan ni yoo gba owo naa, ti wọn yoo si ṣamojuto bi idagbasoke agbegbe ọhun ṣe n lọ si.

Ofin tuntun yii yoo tun jẹ ki idagbasoke de ba bi ina ṣe n wa lawọn agbegbe ati igberiko kaakiri.

Pẹlu ofin tuntun yii, gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogiji patapata yoo ni anfaani lati pese ina mọnamọna funra wọn, bẹẹ ni yoo tun fun ipinlẹ, ileeṣẹ, awọn eeyan lanfaani lati pese ina, ki wọn si tun pin in funra wọn.

Ofin yii yoo gba awọn ipinlẹ laaye lati fun awọn ileeṣẹ aladani ni iwe ẹri lati ni ibi ipese ina alabọde ati ẹrọ to n pese ina laarin ipinlẹ kọọkan.

Ileeṣẹ to n mojuto ina mọnmọna lorileede Naijiria, iyẹn Nigerian Electricity Regulatory Commission (NERC) yoo ṣi tun maa ṣakoso awọn ileeṣẹ to n pese ina ni Naijiria fun awọn ipinlẹ ti ko ni awọn alabojuto.

Ofin yii tun sọ pe agbara ti ileeṣẹ NERC ni ko ni di awọn ipinlẹ lọwọ lati gbe ofin ati ilana ti wọn kalẹ, ati lati pese ọja ina mọnamọna.

Bakan naa, ofin yii yoo tun kan an nipa fun awọn ileeṣẹ mọnamọna lati maa pese ina yala lati ọdọ awọn alagbata to n tun ina ta, tabi pe ki wọn maa ra ina tuntun nibi ti agbara ina wa.