Ìdí tí àdínkù ṣe bá iná mọ̀nàmọ́ná káàkiri Nàìjíríà rèé - Minisita

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Minisita fun eto agbara lorilẹede Naijiria, Adebayo Adelabu ti salaye idi ti adikun fi de ba ina mọnamọna kaakiri orilẹede Naijiria.

Adelabu ni eyi ko sẹyin bi afẹfẹ gassi ko se de sọdọ awọn ileeṣẹ to n sawari ina lorilẹede Naijiria.

Minisita salaye ọrọ yii ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Bolaji Tunji fi lede fun awọn akọroyin lọjọ Ẹti to kọja .

Ninu alaye rẹ, Adelabu ni ijọba apapọ n sisẹ karakara pe gbogbo gbese lo di sisan fun awọn ileeṣẹ to n sawari ile ina mọnamọna lati wa ojutu si adikun naa.

“Eyi ko sẹyin bi afẹfẹ gassi ko se de ọdọ awọn ileeṣẹ to n sawari ina lorilẹede Naijiria.

“Isẹlẹ yii lo fa ti adikun fi de ba ina mọnamọna sugbọn ayipada yoo waye laipẹ.

“Gbogbo ohun to sẹlẹ ni a mọ, ti a si ti n gbe igbesẹ lati ri pe nnkan pada si bo se wa, ti ina mọnamọna yoo si dara ju ti tẹlẹ lọ.