Ǹjẹ́ oúnjẹ tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ pèsè yóò mú ìrọ̀rùn bá aráàlú

Oríṣun àwòrán, Ounje/Getti Images
Laipẹ yii ni ijọba apapọ orileede Naijiria kede awọn ọna abayọ mẹta ti yoo mu adinku ba iṣoro ti awọn araalu n koju lasiko yii.
Lara awọn ọna abayọ akọkọ ni pinpin ounjẹ tirela nla ẹgbẹrun mejilelogoji (42,000tons) lati inu ile iko ounjẹ pamọ si ti ileeṣẹ to n ri sọrọ iṣẹ agbẹ ati ọgbin, eyi ti yoo mu igbe aye dẹrun fun araalu.
Lẹyin eyi ni ijọba tun sọ pe awọn yoo ba awọn ileeṣẹ to n ṣe irẹsi kaakiri Naijiria sọrọ lati sọ asọyepọ nipa pipese ẹgbẹrun lọna ọgọta tirela (60,000tons) irẹsi lati ta kaakiri orileede yii.
Igbesẹ ẹlẹẹkẹta ni lati bẹrẹ sii ko ounjẹ wọle si Naijiria lati ilẹ okeere, eyi ti yoo mu idẹrun ba igbayegbadun araalu.
Njẹ ẹ wa mọ ohun ti awọn igbesẹ wọnyi tunmọ si? Ipa wo ni wọn yoo ko? Ati pe bawo ni yoo ṣe mu ayipada rere ba igbe aye inira ti awọn eeyan n la kọja?
Bayii ni abajade ti a mu wa yii yoo ṣe ri
Onimọ nipa eto ọrọ aje ati ipese ounjẹ nni, Ọmọwe Muhammed Suleiman Kani, ẹni to tun jẹ olukọ ni ile-ẹkọ Federal Government College of Education to wa nipinlẹ Kano sọ pe igbesẹ gidi ni ijọba apapọ gbe, nitori pe yoo mu idẹrun ba ilakaka araalu.
O ni lawọn igba ti orileede ba n koju irufẹ awọn iṣoro bayii, ohun to kan ni lati wa ọna abayọ ti yoo mu irọrun ba araalu.
Ṣugbọn o ni awọn ounjẹ ti ijọba apapọ n sọ wọnyi “kii ṣe eyi ti wọn yoo ko silẹ fun ọmọ Naijiria lọfẹẹ.”
O ni ohun ti ijọba yoo ṣe ni pe, wọn maa dinwo awọn ounjẹ naa, bi apẹẹrẹ ti ounjẹ kan ba jẹ ẹgbẹrun mẹwaa, ijọba yoo ta a ni ẹgbẹrun meje tabi ẹgbẹrun mẹjọ.
Keni sọ pe “Ijọba ti gbe iranwọ dide lori awọn ounjẹ lorileede Naijiria.”
O ni igbesẹ yoo ran awọn eeyan ti wọn rii pe owo oṣu oṣiṣẹ ko yi pada pẹlu bi eto ọrọ aje ṣe ri lọwọ, ati pe awọn oniṣowo naa n koju aita ọja wọn nitori pe agbara kaka lawọn eeyan fi n ri owo lati wọ inu ọja.
“Fun ẹni to ba ra ounjẹ lati ilẹ okeere, yala nipa owo naira si dọla, tabi owo naira si CFA, tabi ohunkohun ti ẹ ba fi ṣe paṣirpaarọ owo naira, bi ẹ ba ra ounjẹ naa, ẹ ko le ta a ni owo kekere.” Ọmọwe Kani.
Ọmọwe Muhammad Suleiman Kani jẹ ko di mimọ pe bi ijọba apapọ ba fẹẹ mu idẹrun ba araalu, afi ki wọn fofin de awọn ounjẹ ilẹ okeere ti wọn le ri ni Naijiria.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni bi ijọba ba gbe iru igbesẹ bayii, o yẹ ki wọn tun ṣiṣẹ lori ina mọnamọna, ki ohun gbogbo le lọ bo ti tọ.
Bakan naa lo tun rọ Aarẹ lati gbe igbesẹ nipa ṣiṣe ohun to yẹ, eyi ti yoo mu Naijiria kuro ninu wahala to wa bayii.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe ki ijọba mu awọn ileri rẹ to ṣe nigba ti wọn yọ owo iranwọ ori epo ṣẹ, nipa fifi owo kun owo oṣu, igbayegbadun awọn agbegbe ati atunkọ ile ifọpo Fatakwal.
Bi ijọba ṣe le mu ki agbekalẹ naa yọri
Gẹgẹ bi onimọ nipa ipese ounjẹ naa tun ṣe sọ, o ni igbesẹ lati ko ounjẹ wọle lati orileede miran jẹ eyi to dara, ṣugbọn ṣa, o ṣe pataki fun ijọba lati tọpinpin bi eto ọhun yoo ṣe lọ lati ṣe araalu ni anfaani.
O ni “Awọn ileeṣẹ eleto aabo ni lati foju silẹ nitori iwa awọn ọmọ Naijiria, ẹ le gbe ounjẹ naa wọle tan, ki ẹ wa rii pe awọn eeyan ti bẹrẹ sii ṣe paṣipaarọ baagi ounjẹ naa, wọn ti bẹrẹ sii gbe lọ saarin ọja lati ta a.”
Bakan naa lo tun sọ pe ijọba ko gbọdọ ṣe aṣiṣe lati pin awọn ounjẹ naa nipaṣe awọn gomina, nitori pe ko si aṣeyọri ninu eyi to ṣẹlẹ ṣeyin.
Ọmọwe Kani sọ pe lati le ṣe aṣeyọri, ijọba apapọ ni lati yọwọ awọn gomina tabi awọn aṣofin ati awọn aṣoju-ṣofin kuro nibẹ.
O ni ki ijọba apapọ ṣabojuto eto ọhun funra rẹ, ki wọn si yan awọn olootọ araalu lati ṣabojuto ẹ daadaa ti wọn le ṣe e pẹlu otitọ.
Bi eto naa ṣe le ṣakoba fun awọn okoowo
Ọmọwe Muhammad Kani ṣalaye pe eto ijọba apapọ yii yoo ni ipa fun awọn ọlọja ati awọn olokoowo, bẹẹ lo tun sọ pe ni awọn orileede bii United State, ijọba maa n ra ounjẹ, wọn yoo si ja owo rẹ wa silẹ ni gbogbo igba ti ko ba si awọn nnkan ire oko mọ.
O ni eto yii ko pin si ibi yii nikan, o sọ pe iru igbesẹ yii naa ni orileede Saudi Arabia n gbe.
“Ni Saudi Arabia, awọn igba kan wa to jẹ pe awọn ire oko yii pọ ju, niṣe ni wọn ranṣẹ pe awọn agbẹ lati ma ṣe da oko mọ. Wọn beere pe eelo ni awọn ere wọn, wọn si san an fun gbogbo wọn.
“Nitori pe to ba pọ lapọju, adanu ni yoo jẹ fun wọn. Wọn kan maa da oko lasan ni, lai ri ere kankan nibẹ.”
O ni bi ijọba gbe iru igbesẹ yii, ifigagbaga yoo wa lati le jẹ ki awọn agbẹ alabọde ja owo ire oko wọn wa silẹ.
Awọn iṣoro to ṣee ṣe ko waye nipa eto yii
Akọṣẹmọṣẹ naa sọ pe aisi ile ikọ ọja si (warehouse) le ṣe akoba nla fun ounjẹ kiko wọle, nitori pe ko si ibi ti wọn le tọju wọn si, to si maa fa ki ọpọ ounjẹ bajẹ.
Ni bayii, o sọ pe ijọba ko ni ounjẹ nilẹ, wọn maa ko ounjẹ wọle, ati pe ibeere naa ni pe owo wo ni wọn yoo fi ra awọn ounjẹ wọnyi.
O sọ pe o di dandan fun ijọba lati ya owo lati fi ra awọn ounjẹ.















