Àwọn nọ́ọ̀sì àti agbẹ̀bí ní Naijiria yarí mọ́ àwọn aláṣẹ lọ́wọ́, wọ́n tú síta fún ìwọ́de

Awọn nọọsi to n ṣe iwọde

Ọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun 2024, ni agbarijọ ẹgbẹ awọn nọọsi ati agbẹbi kaakiri orileede Naijiria, National Association of Nigeria Nurses and Midwives bẹrẹ iwọde ifẹhonuhan lori ofin ati ilana tuntun ti awọn adari ẹgbẹ ọhun gbe kalẹ sita fun wọn laipẹ.

Ọjọ keje, oṣu keji, ọdun 2024, ni ẹgbẹ NMCN gbe atẹjade sita, nibi ti wọn ti n sọ nipa awọn ofin ati ilana tuntun fun ẹni to ba fẹ ẹ gba iwe ẹri iṣẹ nọọsi ati agbẹbi.

Ilana ati ofin naa sọ pe nọọsi tabi agbẹbi to ba fẹ ẹ gba iṣẹ nilẹ okeere, gbọdọ ti ṣe iṣẹ ọdun meji ni Naijiria lẹyin eto ẹkọ rẹ, ko si tun ni iwe ẹri moyege nipa iṣẹ naa.

Wọn ni awọn nọọsi yoo tun san awọn owo kan sinu apo ẹgbẹ wọn ko to di pe wọn gba iwe ẹri moyege yii.

Eyi ni awọn adari ẹgbẹ naa sọ pe awọn ṣe lati wa ni ibamu pẹlu eto ilana agbaye.

Awọn oluwọde
Aworan awọn nọọsi nibi ti wọn ti n fẹhonuhan niluu Abuja
Àkọlé àwòrán, Aworan awọn nọọsi nibi ti wọn ti n fẹhonuhan niluu Abuja

Lati ọjọ ti ilana ajọ NMCN ti gbe awọn ilana tuntun naa jade, ni awọn nọọsi kan, paapaa lori ayelujara ti n fi ẹhonu han.

Kia ni wọn si da ọjọ lati ṣe iwọde alaafia, lati fihan awọn adari wọn pe ilana ọhun ko ba wọn lara mu.

Ṣaaju, ninu ọdun 2023, ni ajọ na ti kọkọ ti itakun ayelujara wọn, nibi ti awọn nọọsi ati awọn agbẹbi ti maa n fi orukọ silẹ fun iwe ẹri ati ontẹ

A gbọ pe eyi ni wọn ṣe lati dena bi awọn oṣiṣẹ eleto ilera lorileede Naijiria bii dokita, nọọsi, agbẹbi ati awọn miran ṣe n japa kuro niluu lati lọ bẹrẹ igbesi aye tuntun ni orilẹ-ede miran.

Iwọde waye niluu Abuja ati ipinlẹ Eko

Awọn oluwọde

Nibi iwọde naa to waye niluu Abuja, lara awọn nọọsi to ba BBC sọrọ ṣalaye pe bi ẹni pe wọn fẹ ẹ fi ẹtọ wọn dun wọn ni.

"O dabi i pe wọn fẹ mu wa sinu igbekun ni awọn ofin ati ilana tuntun ọhun wa fun, a ko si le fara mọ ọ .

Awọn nọọsi ati awọn agbẹbi naa sọ pe awọn ko le wa ni oju kan ṣoṣo, awọn nilo lati lọ gba imọ kun imọ kaakiri.

Lara awọn oriṣiriṣi ti wọn ko sara patako ifẹhonuhan ti wọn gbe dani ni ni ‘Ẹ ma ṣe re iyẹ wa, ẹ jẹ fo tayọ’,

“Ẹ jẹ ki awọn nọọọsi ri imu mi’, ‘Aabọ ẹmi nọọsi ṣe pataki’, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn nọọsi ati agbẹbi niluu Ekoo naa ko gbẹyin ninu iwọde ifẹhonuhan ọhun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbegbe Yaba ni awọn nọsi ati agbẹbi ti gbera, ti wọn si lọ kaakiri igboro lati rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ Naijiria lati da si ọrọ naa ko too pẹ ju.

Lara awọn ohun ti awọn naa n beere fun ko yatọ si eyi ti awọn akẹẹgbẹ wọn to ṣe iwọde niluu Abuja.

Ọkan lara wọn to ba BBC sọrọ nibi ifẹhonuhan ọhun, Ọgbẹni Amusan Kazeem sọ pe, awọn ṣakiyesi pe ijọba apapọ Naijiria ko fẹ ki awọn eeyan lọ siluu oyinbo mọ.

“Ẹyin ti ẹ ko fẹ ka kuro lorileede yii, ṣebi ṣe lo yẹ yẹ ki wọn fun wa ni awọn ohun ti a fẹ, wọn ko ṣe e.

“Nnkan ti a n beere lọwọ ijọba Naijiria bayii ni pe a ko fẹ lẹta ti wọn kọ ranṣẹ si wa, nitori pe a ko le maa duro de oṣu mẹfa, tabi pe ka kọkọ lo ọdun meji ko to di pe a tẹsiwaju lọ sibi to wu wa.

Bakan naa lo ni awọn tako pe ko jẹ ọga agba ileewosan kan lo maa fun wa ni iwe ontẹ pe ki a maa lọ. Ki ọga agba miran to si le fontẹ lu ẹnikan, niṣe ni wọn maa kọkọ ba iru ẹni bẹẹ laṣepọ.

Awọn akọṣẹmọṣẹ naa sọ pe ti ijọba ba ti ṣe awọn nnkan wọnyi, wọn maa rii pe ko ni ṣeni to maa sọ pe oun fẹ japa.

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

Ohun mẹjọ gboogi ti wọn n beere fun

  • Ki wọn wọgile ilana tuntun ti wọn gbe sita
  • Lati gbe iwe ẹri NMCN ko gbọdọ kọja wakati mejilelogoji
  • Eto ilana gbigba iwe ẹri gbọdọ jẹ ọfẹ, o si gbọdọ wa ni ibamu pẹlu ti agbaye bii UK, USA, CANADA ati bẹẹbẹẹlọ.
  • Alekun lori owo oṣu awọn nọọsi
  • Idagbasoke igbayegbadun awọn nọọsi
  • Alekun lori owo ajẹmọ fun ijamba lẹnu iṣẹ
  • Idagbasoke nipa bi wọn ṣe n ṣiṣẹ
  • Idagbasoke awọn anfaani fun awọn akọṣẹmọṣẹ