Àwọn Ajínigbé gbé gbogbo èèrò ọkọ̀ bọ́ọ̀sì kan nípìnlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, sahara reporters
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti jẹ ko di mimọ pe awọn ti ko awọn ọlọpaa kogberegbe to n ṣewadi awọn ajinigbe, iyẹn Special Anti Kidnapping Squad sita lati ṣawari awọn arinrin-ajo ti awọn ajinigbe jigbe laipẹ yii niluu Akunu -Akoko, ipinlẹ naa.
Ọga ọlọpaa, Abayọmi Ọladipọ lo sọrọ naa ninu atẹjade ti agbenusọ wọn, Funmilayọ Ọdunlami-Omisanya fi sita lopin ọsẹ to kọja.
Ninu atẹjade ọhun lo ti sọ pe awọn ti ko awọn ọlọpaa kogbere oluwadii sita pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ologun ati awọn ọlọdẹ lati ṣawari ibi ti awọn ajinigbe naa wa.
Ọladipọ sọ pe awọn yoo ri awọn ti wọn jigbe naa gba jade layọ ati alaafiaa, bẹẹ lọwọ yoo tẹ gbogbo awọn ajinigbe to wa lọwọ ninu ijinigbe ọhun.
Irọlẹ ọjọ Ẹti to kọja ni awọn ajinigbe da awọn arinrin-ajo lọna ninu ọkọ bọọsi elero mejidinlogun ti wọn wa, ti wọn si ji wọn gbe wọnu igbo lọ.
Ṣugbọn wọn fi ọmọdebinrin kan silẹ, ti ko si tii sẹni to mọ ibi ti wọn ko wọn lọ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
Bakan naa ni iroyin sọ pe awọn ajinigbe naa pa awakọ bọọsi ọhun to gbera lati ipinlẹ Eko, to si n lọ si ilu Abuja.
Ọkọ naa ni wọn lo jẹ ti ileeṣẹ irinna aladani kan.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ko pẹ si asiko ijinigbe ọhun ti awọn oṣiṣẹ ọlogun, ọlọpaa ati awọn ọlọdẹ fi debẹ.
"Loju ẹsẹ ti a gbọ pe nipa iṣẹlẹ naa, la sare wọnu igbo lati mọ ibi ti wọn gba, ṣugbọn ti wọn sọ pe ko sẹni to ri ibi ti wọn gba."
Ọga ọlọpaa naa wa sọ pe iṣẹ iwadii awọn ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lati rii pe awọn gba gbogbo arinrin-ajo ọhun jade layọ ati alaafia.
Bẹẹ lo ni kii ṣe pe ki wọn gba awọn eeyan naa jade nikan, bi ko ṣe pe ki awọn tun mu awọn ajinigbe yii pẹlu.
Bakan naa lo parọwa si araalu wi pe ki wọn ma ṣe gbọjẹgẹ lori iṣẹlẹ naa, nitori pe awọn ti n ṣe iwadii.















