Wo nǹkan méje tó le ṣe tó bá fẹ́ lóyún

Kò sí àníàní wí pé gbogbo ènìyàn ló máa ń wù láti finú ṣe oyún, kí wọ́n fẹ̀yìn gbé ọmọ pọ̀n ní kété tí wọ́n bá ti ṣe ìgbéyàwó tán.
Ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ a máa pòruru tí Ọlọ́run kò bá tètè gbọ́ àdúrà wọn lórí ọmọ bíbí lẹ́yìn ìgbéyàwó.
Wíwá ní àláfíà tó pé jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì tí ènìyàn pàápàá obìnrin nílò láti ṣe àmúṣẹ nígbà tí ènìyàn bá ń wojú ọmọ Ọlọ́run fún ọlẹ̀ ayọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ètò ìlera Dókìtà Sajeeda Ibrahim ti ilé ìwòsàn olùkọ́ni Abuja àti Dókítà Tanko Zakari tí ilé ìwòsàn Aminu Kano ṣe sọ, ó ṣe pàtàkì kí obìnrin mọ ipò ìlera tó wà kí oyún tó dúró lára.
Àwọn dókìtà méjéjèjì yìí nígbà tí wọ́n ń bá BBC sọ̀rọ̀ ka ìgbésẹ̀ méje tí ènìyàn le tẹ̀lé láti mú kí ọlẹ̀ ọmọ tété so nínú obìrin.
Àwọn nǹkan méje tó le ṣe tó bá fẹ́ lóyún
Ṣe àyẹ̀wò láti mọ̀ bóyá ara rẹ̀ wà ní ìlera pípé:
Gẹ́gẹ́ bí àwọn Dókìtà Ibrahim àti Zakari ṣe ṣàlàyé kí obìnrin tó máa gbìyànjú láti lóyún, ó ṣe pàtàkì kí ònítọ̀hún kọ́kọ́ tọ àwọn dókítà lọ láti lè mọ ipò ìlera rẹ̀.
Kí ènìyàn bèèrè nípa àwọn ògùn tó máa ń mú kí ènìyàn ní àláfíà lásìkò òyùn, kí ènìyàn máa lo irú àwọn ògùn bíi folic acid tó máa ń dá ààbò bò oyún.
Bákan náà tí àwọn kùdìẹ̀kudiẹ kan bá wà ní àgọ́ ara, ó ṣe pàtàkì kí ènìyàn tọ́jú irú ìpèníjà bẹ́ẹ̀ kó tó lóyún kí oyún náà má ba à ṣe ìdíwọ́ fún-un.
Mímọ àsìkò nǹkan oṣù obìnrin:
Níní ìmọ̀ nípa àkókò tí nǹkan oṣù obìnrin máa ń wá, ìgbà tí yóò àti ọjọ́ tó máa ń wà láàárín oṣù kan sí òmíràn ṣe pàtàkì gẹ́gẹ́ bí Dókìtà Sajeeda ṣe sọ.
Ní àsìkò tí ara obìnrin bá pèsè ẹyin inú ara máa ń jẹ́ àsìkò tó tọ̀nà jú fún obìnrin láti súnmọ́ ọkùnrin tí oyún yóò sì dúró.
Dókítà Sajeeda ní lásìkò yìí gan ló yẹ kí obìnrin máa ní ìbálòpọ̀ jùlọ.
Bákan náà ni àsìkò yìí jẹ́ àsìkò tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyípadà máa ń débá ara tí obìnrin sì nílò láti súnmọ́ àwọn onímọ̀ ìlera láti mọ àwọn nǹkan tó le ṣe tí ọlẹ̀ ayọ̀ yóò fi sọ nínú rẹ̀.
Mímọ̀ ìgbà àti irú ìbálòpọ̀ tò yẹ:
Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ṣe sọ, bí ènìyàn bá ṣe pẹ́ tó tàbí tètè ṣe kíá sí kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú oyún níní.
Bákan náà ni wọ́n ní kò sí ìwádìí tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó ní ipò kan tí ọkọ àti aya gbọdọ̀ wà lásìkò ìbálòpọ̀ kí oyún tó lè dúró sí obìnrin lára.
Ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ ni pé kí àtọ̀ ọkùnrin dàpọ̀ mọ́ ti obìnrin.
Wọ́n ní yàtọ́ sí níní ìbálòpọ̀ lórí ìdúró àti ìjókòó, kò sí ọ̀nà tí tọkọtaya kò fi lè ní ìbálòpọ̀ tí oyún yóò sì dúró sára obìnrin.
Kí obìnrin yé sáré dìde lẹ́yìn ìbálòpọ̀:
Ó máa ń dára kí obìnrin ṣì wà ní ìdùbúlẹ̀ fún bíi ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀dógún lẹ́yìn ìbálòpọ̀.
Wọ́n ní èyí kò nílò kí obìnrin gbé ẹsẹ̀ sókè tàbí gbé ìdí sókè rárá gẹ́gẹ́ bí àawọn kan ti máa ń gbé kiri.
Kí àsìkò máa wà fún ìgbà tí ìbálòpọ̀ yáà máa wáyé:
Àwọn onímọ̀ ní kí ènìyàn máa ní ìbálòpọ̀ ní gbogbo ìgbà kò ní kí ènìyàn lóyún àmọ́ àwọn àsìkò kan wà tó jẹ́ wí pé ó le mú kí oyún tètè dúró.
Wọ́n ní àtọ̀ ọkùnrin le dúró lára obìnrin fún ọjọ́ márùn-ún, tó sì dára kí obìnrin tó bá ń wá oyún máa ní ìbálòpọ̀ lásìkò tí àwọn olóyìnbó ń pè ní “oluvation”
Bákan náà ni wọ́n ní kò da kí ọkùnrin máa wọ ṣòkòtò tàbí aṣọ tó bá fún nítorí ó máa ń ṣe àkóbá fún àtọ̀ ni.
Wọ́n ní ó dára kí obìnrin máa wẹ nínú omi gbígbóná.
Dín wàhálà ṣíṣe kú:
Lásìkò tí obìnrin bá ń wá oyún níní, ó nílò l;ati dín wàhálà ṣíṣe àti jìnà sí ìrònú.
Ìwádìí fi hàn pé obìnrin tí kò bá ṣe wàhálà púpọ̀ ní àǹfàní láti tètè lóyún ju ẹni tó ń ṣe wàhálà lọ.
Eré ìdárayá:
Eré ìdárayá dára fún ìlera tó péye tó sì máa ń dín ará sísan kù.
Dókítà Sajeeda ní bí ṣíṣe eré ìdárayá ṣe dára fún ara tó, ó ní àwọn eré ìdárayá kán wà tí kò yẹ fún ẹni tó ń wá oyún.
Bákan náà Dókítà Tanko ni ó dára kí obìnrin tó bá ń wá oyún bá àwọn dókítà sọ̀rọ̀ láti mọ irú eré ìdárayá tó yẹ̀ẹ́.















