Atiku, Tinubu, Kwankwaso, Obi àti àwọn mìí tó fẹ́ gba ipò lọ́wọ́ Buhari ní 2023

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ọpọlọpọ awọn ẹgbẹ osẹlu ni Naijiria lo ti pari idibo abẹle wọn lati yan awọn ti yoo ṣoju wọn ninu idibo gbogboogbo ti yoo waye lọdun 2023.
Lara awọn ẹgbẹ to ti yan oludije si ipo aarẹ ni ẹgbẹ to wa ni iṣakoso, All Progressives Congress.
Peoples Democratic Party, Labour Party, Young Progressives Party, New Nigeria Peoples Party, ati awọn mii.
Akọsilẹ re e nipa awọn oludije ẹgbẹ kọọkan:
Ọmọọba Malik Ado-Ibrahim (YPP)

Oríṣun àwòrán, other
Ọmọọba Malik di oludije fun ipo aarẹ lati inu ẹgbẹ oṣelu Young Progressives Party, lẹyin ti wọn ṣe idibo abẹle wọn lọjọru.
Akọsilẹ nipa rẹ to wa lori ayelujara Wikipedia fihan pe ọmọ ọba Ohinoyi ti ilẹ Ebira, nipinlẹ Kogi ni.
Olowo tabua ti ọpọ si ‘bilionaire’ ni latara ileeṣẹ rẹ Bicernegy ati Formula One team Arrows A20.
Rabiu Musa Kwankwaso (NNPP)

Oríṣun àwòrán, others
Ọjọru ọsẹ yii bakan naa ni ẹgbẹ osẹlu New Nigeria Peoples Party, naa ṣe idibo abẹle wọn nilu Abuja.
Nibẹ si ni gomina ipinlẹ Kano nigba kan, Rabiu Kwankwaso ti jawe olubori gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ naa fun ipo aarẹ.
Saa meji lo ṣe gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Kano.
Lẹyin naa lo di aṣofin agba, sẹnetọ, laarin ọdun 2015 si 2019.
Ẹwẹ, Kwankwaso jẹ minisita fun eto aabo labẹ iṣakoso Olusegun Obasanjo.
Ọdun 2023 ni yoo jẹ igba kẹta to ti n du ipo aarẹ Naijiria.
Omoyele Sowore (AAC)

Oríṣun àwòrán, Others
Osu to kọja ni Omoyele Sowore gbegba oroke nibi ibo abẹle ẹgbẹ osẹlu Africa Action Congress, AAC, gẹgẹ bi oludije fun ipo aarẹ.
Igbakeji re e ti Sowore n dije fun ipo naa. Ọdun 2019 ni igba akọkọ.
Sowore ni oludasilẹ ileeọ̀ẹ iroyin Sahara Reporters.
O ti fi igba kan wa ni ẹwọn, nitori iwọde Revolution Now, to sẹ agbatẹru rẹ jakejado Naijiria lọdun diẹ sẹyin.
Peter Obi (LP)

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinlẹ Anambra nigba kan ni Peter Obi.
Oun si ni oludije fun ipo aarẹ lati inu ẹgbẹ osẹlu Labour Party.
Ẹgbẹ osẹlu PDP ni Obi wa tẹlẹ, nibẹ lo si ti kọkọ fẹ ẹ dije.
Amọ o fi ẹgbẹ naa silẹ ni oṣu to kọja nitori awọn idi kan.
Igba kinni re e ti yoo dije fun ipo aarẹ. Amọ o dije gẹgẹ bi igbakeji aarẹ fun Atiku Abubakar lọdun 2019.
Amọ wọn ko wọle.
Ọmọọba Adewole Adebayo (SDP)

Oríṣun àwòrán, other
Ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP, yan Ọmọọba Adebayo gẹgẹ bi oludije wọn, nibi idibo abẹle ti wọn ṣe lọjọru nilu Abuja.
Agbẹjọro ni. Oun si ni oludasilẹ ileeṣẹ amohunmaworan KAFTAN Television.
Kola Abiola (PRP)

Oríṣun àwòrán, Other
Oun ni ọmọkunrin to dagba ju laarin awọn ọmọ oloogbe Moshood Abiola.
Oun si ni oludije fun ipo aarẹ lati inu ẹgbẹ osẹlu Peoples Redemption Party.
Oniṣowo ni Kola.
Igba akọkọ kọ re e ti yoo dije.
Asiwaju Bola Ahmed Tinubu (APC)

Oríṣun àwòrán, other
Gomina ipinlẹ Eko nigba kan, Bola Tinubu lo bori nibi idibo abẹle ẹgbẹ osẹlu All Progressives Congress lọjọru, gẹgẹ bi oludije wọn fun ipo aarẹ.
Saa meji lo ṣe gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko.
Bakan naa lo sẹ sẹnetọ ni saa iṣejọba to ṣaaju ti Sani Abacha.
Atiku Abubakar (PDP)
Igbakeji aarẹ nigba kan, Atiku Abubakar lo bori nibi idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu alatako gboogi, Peoples Democratic Party.
Ọdun 2023 ni yoo jẹ igba kẹfa to ti n dije fun ipo aarẹ.
Ọdun 1993 ni igba akọkọ, botilẹ jẹ pe ẹgbẹ osẹlu rẹ ko fun ni tikẹẹti nigba naa.















