Wo àwọn tí ẹnu ń kùn pé yóò jẹ́ igbákejì Tinubu fún ìbò ààrẹ 2023?

Awọn ti ẹnu n kun fun ipo aarẹ

Nibayi ti ẹgbẹ oselu APC ti dibo yan Bola Ahmed Tinubu lati gbe asia ẹgbẹ naa feto ibo aarẹ lọdun 2023, ohun to kan bayii ni lati mọ ẹni ti yoo ba dije papọ bii igbakeji rẹ.

Osu Keji ọdun 2023 ni eto idibo aarẹ yoo waye gẹgẹ bi akọsilẹ ti ajọ eleto idibo, INEC gbe sita.

O si di dandan bayii pe ki ẹgbẹ oselu APC fi orukọ oludije fun ipo igbakeji aarẹ sọwọ pẹlu orukọ Tinubu, ki gbedeke ti INEC gbe kalẹ to pari.

Bawo ni ẹgbẹ oselu kan se n yan igbakeji aarẹ?

Ọpọlọpọ nnkan ni ẹgbẹ oselu kan maa n se agbeyẹwo rẹ, ko to pinnu lori ẹni ti yoo yan gẹgẹ bi igbakeji aarẹ ti yoo soju ẹgbẹ naa.

Ipinnu lati yan igbakeji aarẹ kii si se ohun ti ẹnikansoso le da se nitori awọn ti ọrọ ẹgbẹ oselu naa gberu yoo jiroro laarin ara wọn na, ki wọn to se ipinnnu naa.

Sani Salihu, tii se onwoye nipa ọrọ oselu fun BBC salaye pe isoro nla ni yoo koju ẹgbẹ oselu APC ati Tinubu funra rẹ nidi erongba lati yan igbakeji rẹ.

“Yoo nira pupọ fun ẹgbẹ oselu APC lati fẹnu ko lori ẹni ti yoo se igbakeji aarẹ, isoro naa si le pọ fun wọn ju ti ẹgbẹ PDP lọ.

Idi ni pe ẹgbẹ PDP lee yan igbakeji aarẹ ni ẹkun meji to ku, eyiun ẹkun ila oorun guusu ati iwọ oorun guusu.

Idi ni pe Atiku Abubakar to jẹ oludije PDP fun ipo aarẹ ti wa lati ẹkun ariwa.

Amọ fun APC, ẹkun mẹta lo wa nlẹ fun APC lati yan oludije fun ipo igbakeji aarẹ, eyiun ẹkun aarin gbugbun, ila oorun ati iwọ oorun ariwa Naijiria.”

Agbeyẹwo yiyan awọn oludije to jẹ ẹlẹsin kannaa fun ipo aarẹ ati igbakeji rẹ:

Salihu tun salaye awọn igbesẹ miran ti awọn ẹgbẹ oselu maa n yiiri wo, ki wọn to kede ẹni kan bii oludije fun ipo igbakeji aarẹ.

“Ohun miran ti wọn yoo tun gbeyẹwo ni tito oludije fun ipo aarẹ ati igbakeji rẹ ti wọn jẹ ẹlẹsin kan soso papọ lati dije.

Fun APC ati PDP, wọn yoo fẹ yago fun jijẹ ki oludije fun ipo aarẹ ati igbakeji rẹ dijọ jẹ musulumi eyi ti yoo mu ki awn eeyan kan mase tọ si ipo naa.

Bakan naa ni wọn yoo tun se agbeyẹwo awọn ilana kan bii ẹkun ti oludije fun igbakeji aarẹ naa yoo ti wa, agbegbe to ti wa ati ipa to n ko si aseyọri ẹgbẹ oselu naa.

Wọn yoo tun wo boya onitọun nifẹ lati gba ipo naa atawọn ilana miran ko to di pe wọn kede ipinnu wọn lori ẹni ti wọn fẹ yan sipo naa.”

Awọn ti ẹnu n kun fun ipo aarẹ

Awọn eeyan to seese ki wọn daba wọn lati se igbakeji aarẹ fun Tinubu:

Simon Lalong:

Lalong ni gomina ipinlẹ Plateaun to n se saa keji lọwọ, to si tun jẹ alaga ẹgbẹ awọn gomina lati ẹkun ariwa.

Ẹkun aarin gbungbun ariwa Naijria lo si ti wa, to si ti n lo ọdun keje lọ lori aleefa.

Ẹni ọdun marundinlọgọta ni gomina naa tii se agbẹjọro, to si ti gba tikẹẹti lati dije sipo ile asofin agba nipinlẹ rẹ.

Idi ti awọn eeyan si se n pariwo orukọ rẹ fun ipo igbakeji Tinubu ni pe eekan nla ni ninu ẹgbẹ oselu APC.

Yatọ si eyi, ọmọlẹyin Kristi ni Lalong eyi to mu ko yẹ bii igbakeji aarẹ niwọn igba ti Tinubu jẹ musulumi.

Solomon Lalong

Oríṣun àwòrán, PSG

George Akume:

Gomina ana ni George Akume nipinlẹ Benue to wa ni aarin gbungbun ariwa Naijiria, to si tun jẹ eekanlu miran ti awọn eeyan n jẹ orukọ rẹ lẹnu fun ipo igbakeji aarẹ.

Lẹyin to ti lo ọdun mẹjọ bii gomina ipinlẹ Benue, lo tun yege ibo sile asofin agba ldun 2011.

Lọwọ lọwọ bayii, oun ni minisita fun akanse isẹ ati ọrọ ẹka kan si ekeji, koda o du ipo alaga ẹgbẹ APC, ko to ja mọ Adamu Abdullahi lọwọ.

Gẹgẹ bi Lalong, oun naa jẹ eekan nla lati ẹkun arin gbungbun ariwa, ti yoo si seranwọ fun ẹgbẹ oselu APC lati ri ọpọ ibo mu.

George Akume

Oríṣun àwòrán, George Akume

Nasir El-Rufai:

Oun ni gomina fun ipinlẹ Kaduna to ti se saa meji lori aleefa.

Oun naa lagbara ninu ẹgbẹ oselu APC amọ musulumi ni.

Eyi si le mu ko nira lati yan sipo oludije fun igbakeji aarẹ Tinubu.

Nasir El Rufai

Oríṣun àwòrán, KDSG

Babagana Zulum:

Gomina ipinlẹ Borno lẹkun ariwa ni Babagana Zulum, o si tun fẹ dije fun keji bii gomina.

Amọ awọn onwoye kan n daba pe pẹlu agbara ti Zulum ni lagbo oselu APC, o seese ko mu ayipada rere ba esi ibo aarẹ to ba di oludije fun igbakeji aarẹ.

Zulum tii se amofin lo gba ipo lyin gomina Kassim Shettima ldun 2019, to si jẹ gbajumọ oloselu yika Naijiria.

Ẹkun ila oorun ariwa Naijiria lo ti wa gẹgẹ bii Atiku Abubakar, tawọn onwoye si gbagbọ pe to ba ti oludije fun ipo igbakeji aarẹ ninu APC, yoo din agbara ti Atiku ni lẹkun naa ku lasiko ibo ọdun to n bọ.

Amọ sugbọn kan to wa nidi ọrọ Zulum, to fi le mu ko nira lati gba ipo igbekeji aarẹ ninu APC ni pe musulumi ni gg bii Tinubu.

Babagana Zulum

Oríṣun àwòrán, Babagana Zulum