Ọlọ́pàá ṣàlàyé lórí ìbẹ̀rù pé agbébọn fẹ́ ṣe ìkọlù sí àdúgbò kan l'Eko

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ti jiyàn ìròyìn kan tó ń lọ lórí ayélujára WhatsApp wí pé àwọn kan ti ń gbèrò láti ṣe ìkọlù sí ẹ́sítèètì Muhammadu Buhari tó wà ní agbègbè Badagry, ìpínlẹ̀ Eko.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Benjamin Hundeyin nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta ní ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹfà, ọdún 2022 ní ìròyìn òfégè ni ìròyìn náà.
Hundeyin ní àwọn kan ló ń lo ìròyìn náà láti fi dá inú fu aya fu sílẹ̀ sọ́kàn àwọn ènìyàn.
Ó ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti gbọ́ sí ìròyìn tó ń lọ lórí WhatsApp wí pé àwón Fulani kan ti wà ní ẹ́sítèètì Muhammadu Buhari, Agemowo, Badagry láti ṣe ìkọlù ńlá sí agbègbè náà.
Ó fi dá àwọn ènìyàn lójú wí pé kò sí òótọ́ kan ṣoṣo nínú ìròyìn náà àti pé ètò ààbò tó gbópọn wà fún àwọn ènìyàn agbègbè náà.
Ó fi kun pé àgọ́ ọlọ́pàá kan wà ní ìtòsí ẹ́sítèètì náà, tí wọ́n sì ti gbáradì láti kojú ẹnikẹ́ ni tó bá gbèrò láti da omi àláfíà àdúgbò náà rú.
Bákan náà ló ní àwọn ọlọ́pàá ti lọ ṣe àbẹ̀wò sí gbogbo àyíká agbègbè láti fìdí èyí tó ń jẹ́ múlẹ̀ lórí ìròyìn tí àwọn ènìyàn ń gbé lórí ayélujára.
Hundeyin sọ síwájú pé Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko Abiodun Alabi ti ń bá àwọn àjọ ẹ̀ṣọ́ ààbò mìíràn jíròrò lórí bí ètò ààbò yóò ṣe kẹ́sẹ járí ní ìpínlẹ̀ Eko àti agbègbè rẹ̀.
Afurasi ẹni ọdún 18 pa ọmọọdún kan àti ìya rẹ̀ sínú odò tórí kò gbà kó fipá báa lòpọ̀

Ileeṣẹ Ọlọpaa Adamawa ti fi ṣinkun ofin mu ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogun kan ti wọn fi ẹsun kan pe o pa arabinrin ẹni ọdun mẹrindinlogoji ati ọmọ rẹ, ọmọ ọdun kan ni agbegbe ijọba ibilẹ Lamurde, ipinlẹ Adamawa.
Ati afurasi naa Volamu Kalbes, ati arabinrin ọhun Talatu Usman jọ n gbe ni ilu Sabon Layi ni ijọba ibilẹ Lamurde.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa, SP Suleiman Yahaya Nguroje fọwọ si, wọn fẹsun kan pe afurasi naa ṣe ikọlu si arabinrin ọhun leti odo nibi ti oun ati ọmọ rẹ ti lọ wẹ.
O ni obinrin ọhun vi agbara kọ lati jẹ ki oun fipa baa lopọ amọ agbara rẹ ko ka oun toun si kapa rẹ to wa tẹ ẹ ri sinu omi ninu eyi to ti mu omi yo to si ku.
Ko tan sibẹ o, afi bi afiṣe, agbẹnusọ ọlọpaa tun sọ ninu atẹjade naa pe wọn fẹsun kan pe afurasi ọhun tun gbe ọmọ ọdun kan arabinrin naa to ti n sọkun o si lọ ri oun naa bọ inu odo titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.
Nitori idi eyi ni awọn ọlọpaa agbegbe naa lọ fofin mu afurasi ọhun lẹyin ti wọn gbọ iroyin iṣẹlẹ ọhun lẹnu ọkọ rẹ, Alhaji Usman Abdul to n ṣọfọ iku aya ati ọmọ rẹ lọwọ.
Komisọna Ọlọpaa ipinlẹ Adamaw, CP S.K. Akande ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ ati pe ki igbakeji Kọmisọna to wa nidi akoso awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ gba akoso iwadii iṣẹlẹ naa.
Awọn igba mii ti iru iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ
Iṣẹlẹ yii fẹ da bii iṣẹlẹ iku arainrin Bamiṣe Ayanwola ni ipinlẹ Eko ti wọn fẹsun kan pe awakọ BRT kan fipa baa lopọ to si pa a sinu ọkọ lasiko ti obinrin naa n wọ ọkọ pada lọ ile lati ibi iṣẹ.
Igbẹjọ afurasi naa, Andrew Nice ṣi n lọ lọwọ gẹgẹ bi awọn ẹbi Bamise ṣe n pe fun idajọ ododo.
Bakan naa ni ipinlẹ Kano afurasi marun lo ti wa lọgba ẹwọn bayii lori ẹsun lilọwọ ninu ẹsun iku ọmọ ọdun marun kan, Hanifa.
Ariwo idajọ fun Hanifa gba ori ayelujara kan nigba naa pẹlu aworan rẹ to tan ka ati lẹyin ti awọn ọlọpaa ri oku Hanifa ni Kano. Iroyin ni awọn afurasi naa ji ọmọ ọdun marun ọhun gbe lasiko to n pada lọ ile lati ile Keu.
Lafikun ninu oṣu kini ọdun 2022, awọn ọkunrin ọdọ langba mẹrin kan pa ọrẹbinrin ọkan lara wọn lori ẹsun pe wọn fẹ fi ṣe oogun owo ni ipinlẹ Ogun.
Ọlọpaa ipinlẹ Ogun ni awọn ọkunrin naa jẹwọ pe ori obinrin naa lo wa ninu koko ibilẹ ti wọn jo ti wọn si ṣapejuwe bi wọn ṣe rii pa. Ọrọ wọn ti wa niwaju ile ẹjọ bayii ti awọn afurasi naa si wa ni ọgba ẹwọn.















