Tinubu àti Osinbajo ni yóò kọjú ara wọn níbi ètò ìdìbò abẹ́nú APC – Sẹnetọ Kabiru Gaya

Osinbajo ati Tinubu

Ọkan gboogi lara àwọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, Senẹto Kabiru Gaya ti ni awọn olujide mẹta ni wọn ti ju ọwọ silẹ fun igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo níbi eto ìdibo abẹle naa ti o si ku igbakeji Aarẹ àti Bola Ahmed Tinubu ti yoo koju ara wọn.

Gaya nigba ti o ba Ile ise Telifisan Channels sọrọ loni ni pe ẹgbẹ oselu APC ti pinu lati gbe asia ẹgbẹ oselu naa lọ iha Guusu orile-ede Naijiria.

Tí a ko ba gbagbe, Guusu orile-ede Naijiria ni ẹgbẹ oselu APC pinu lati yan ẹni tí yoo gbe asia ẹgbẹ naa ninu eto ìdibo Aarẹ lodun 2023.

Gaya ni awọn olujide ọhun ni yio ba awọn ọmọ ẹgbẹ sọrọ laipẹ.

Ó ní " a ni igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo àti Bola Ahmed Tinubu nítorí pé àwọn olujide kan tí juwọ lẹ fun igbakeji Aarẹ. "

"Awọn olujide ni yio bọ si gbangba láti ba awọn ọmọ ẹgbẹ sọrọ ìdí ti wọn fi juwọ lẹ."

Gaya ni ipinu lati yan ẹni tí soju ẹgbẹ oselu APC lati Guusu orile-ede Naijiria ni lati rii pe ẹmi isokan wa laarin ẹgbẹ oselu naa.

O ni oun ni igbagbo pe ìpinnu naa ni o fihan pe ẹgbẹ oselu APC ni ìfe orileede Naijiria lọ́kàn nítorí ìjọba awarawa ni ẹgbẹ naa wa fun.

Àdínkù báwọn olùdíje ààrẹ̀ nínú APC sí mẹ́ta péré

Yemi Osinbajo ati Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Osinbajo

Awọn gomina fẹgbẹ oselu APC nilẹ wa tun ti se adinku sawọn oludije fun ipo aarẹ si mẹta pere.

Awọn gomina naa lo ti kọkọ daba oludije marun pere pe ki wọn kopa ninu ibo abẹnu naa.

Orukọ awọn oludije maraarun ti wọn daba saaju naa Asiwaju Bola Ahmed Tinubu; Yemi Osinbajo; Rotimi Amaechi; Kayode Fayemi ati Dave Umahi.

Bamọ wọn ti wa se adinku si awọn orukọ naa si mẹta.

Awọn mẹtẹẹta naa ni Tinubu, Osibanjo and Amaechi.

Amọ aba naa kii se asẹ lori gbogbo awọn oludije yoku sugbọn o jẹ aba fun aarẹ Muhammadu Buhari to ti rọ wọn saaju lati se adinku awọn oludije mẹtalelogun to fẹ dije si ẹyọ kansoso ti yoo jẹ itẹwọgba.

Amọ awọn oludije fun ipo aarẹ bii Kayode Fayemi ati Yahaya Bello ti n yari pe awọn si wa ninu idije fun ipo aarẹ naa.

Àwọn gómìnà APC dín olùdíje ààrẹ ku sí 5 kí ìdìbò tó bẹ̀rẹ̀
Awọn oludije fun ipo aarẹ
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ipalẹmọ fun eto idibo abẹnu ẹgbẹ oselu APC ti yoo waye loni nilu Abuja ti doju ọgbagade.

Awọn gomina ẹgbẹ oselu APC nilẹ wa ti panupọ dabaa pe oludije marun pere ni awọn fẹ ko kopa ninu ibo abẹnu lati yan oludije ti yoo soju ẹgbẹ oselu naa ninu ibo gbogbo gboo ti yoo waye lọdun 2023.

Gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong lo fidi aba yii mulẹ fawọn akọroyin nilu Abuja.

Lalung ni awọn gomina naa gbe igbesẹ yii nitori awọn isẹlẹ to wa nilẹ, ti wọn ko si sẹ bẹẹ pẹlu ẹtanu tabi lati segbe sibi kan.

Awọn oludije maraarun ti wọn daba pe ko kopa ninu idibo abẹnu naa ni Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, Chibuike Amaechi, Yemi Osinbajo, Dave Umahi ati Kayode Fayemi.

Igbesẹ awọn gomina yii ni Lalung sọ pe o fidi ipinnu wọn mulẹ lati gbe ipo aarẹ wa sẹkun guusu Naijiria.

Awọn eekan ninu ẹgbẹ APC

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe bi orukọ awọn gomina naa se to tẹle ara wọn nilana onka ABD ni awọn se to o.

O tun fikun pe aarẹ Buhari ti sọ fun awọn gomina naa lati se adinku iye oludije ti yoo kopa ninu ibo abẹnu naa.

Gomina ipinlẹ Plateau naa ni awọn ti fi orukọ awọn oludije naa sọwọ si igbimọ alasẹ ẹgbẹ naa.

O wa gba awọn oludije maraarun ti awọn gomina fi ontẹ lu naa lati fikunlukun laarin ara wọn, ki wọn si fi ohun sọkan lori ẹni ti wọn yoo fa kalẹ laarin ara wọn.

Ète Alága APC láti fa olùdíje kan ṣoṣo kalẹ̀ dàrú, wàhálà bá ẹgbẹ́
Amin idamọ ẹgbẹ APC

Oríṣun àwòrán, APC

Lọwọ lọwọ bayii, idarudapọ ati rukerudo ti wọ inu ẹgbẹ oselu APC to n se akoso ijọba apapọ ni orilẹede yii.

Wahala naa ko si sẹyin bi alaga apapọ fun ẹgbẹ oselu naa, Abdullahi Adamu se kuna lati fa oludije kan soso fun ipo aarẹ kalẹ.

Ni irọlẹ ọjọ Aje ana ni ariwo gbalẹ kan ni Naijiria pe Adamu ti kede pe ẹgbẹ ti pinnu lati fa Ahmed Lawan silẹ.

Lawan ni aarẹ ile asofin agba ati oludije fun ipo aarẹ kalẹ, gẹgẹ bii ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ naa fun ipo aarẹ lasiko ibo gbogbo gbooo.

Amọ ni kete lẹyin ariwo naa, ni ileesẹ aarẹ ati awọn gomina mejila to wa lati ẹkun ariwa Naijiria kede sita pe awọn takete si ete lati fa oludije kan soso kalẹ sipo aarẹ.

Buhari n se ipade pọ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Saaju ni Alaga ẹgbẹ oselu APC naa ti kọkọ pe ipade igbimọ amusẹya ẹgbẹ tii se ẹlẹni mẹẹdọgbọn si ibujoko ẹgbẹ naa to wa nilu Abuja.

Nibẹ si lo ti yan leti igbimọ naa pe Lawan ni oludije ti awọn fi ontẹ lu bii ẹni ti yoo du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC amọ igbesẹ naa ni ko dun mọ awọn ọmọ igbimọ naa ninu.

Adamu si taku pe oun ti gba asẹ lati ọdọ aarẹ Muhammadu Buhari lati kede Lawan bii oludije funn ipo aarẹ fẹgbẹ APC.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ti sọ, ni kete lẹyin ipade naa, si lo wọ inu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ, to si kuro nibi ipade naa.

Awọn oludije fun ipo aarẹ nilẹ Yoruba

Awuyewuye bẹrẹ lori ikede Lawan bii oludije aarẹ kansoso fẹgbẹ APC:

Lẹyin rogbodiyan yii, ni awọn oludije fun ipo aarẹ ninu APC, awọn ọmọ igbimọ amusẹya ẹgbẹ, awọn gomina ẹgbẹ APC lati ẹkun Ariwa atawọn ọmọ ẹgbẹ gbogbo ti fọnmu lori ete Adamu naa.

Koda, meje lara awọn ọmọ igbimọ amusẹya fẹgbẹ APC eyi ti akọwe ẹgbẹ wọn, Suleman Argungun ko sodi, sọ fawọn akọroyin pe Lawan kii se oludije ti awọn faramọ.

Bakan naa ni awọn gomina mejila fẹgbẹ APC lati ẹkun ariwa naa pari ipade wọn pẹlu aarẹ Buhari, ti wọn si lo ti fi da awọn loju pe oun ko ni oludije kankan ti oun faramọ julọ.

Awọn gomina naa si yari kanlẹ pe awọn si duro lori ipinnu awọn pe ẹkun guusu Naijiria ni awọn n fẹ ki oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oselu APC ti jade.