Pásítọ̀, ẹ pèsè ẹ̀rọ CCTV sílé ìjọsìn yín torí ìkọlù agbébọn - Oriade l‘Ogun

Oba Eselu ti ilu Iselu ni ipinlẹ Ogun ti fi iwe ranṣẹ si olori ẹgbẹ ọmọ lẹyin Kristi Naijiria,Rev Supo Ayokunle,lori ikọlu sawọn ọmọ lẹyin Kristi ni ile ijọsin St. Francis Catholic Church Owo nipinlẹ Ondo.
Oba Akintunde Akinyemi ninu iwe naa da laba pe ki aarẹ ẹgbẹ yi kesi awọn ile ijọsin lati ṣamulo ẹrọ kamẹra CCTV lati le fi mọ awọn to ba n wọle tabi jade ninu ile ijọsin wọn ni gbogbo igba.
- Àwọn gómìnà APC dín olùdíje ààrẹ ku sí 5 kí ìdìbò tó bẹ̀rẹ̀
- Seyi Makinde tara-pòrò lórí ìkọlù Owo, ó ké sáwọn tọ́rọ̀ ààbò kàn láti yé fọ́wọ́ lẹ́rán lórí ìkọlù agbébọn
- Òní lòní ń jẹ́, bí ìpalẹ̀mọ́ fún ìbò abẹ́nú APC láti yan olùdíje Ààrẹ ṣe ń lọ rèé
- Tinubu, ewu ń bẹ níwájú, ṣọ́ra ko má jìn sí ọ̀fìn tí Abiola, Awolowo jìn sí - Fayose
Gẹgẹ bi oriade yi ti ṣe sọ, fidio lati inu ẹrọ CCTV yi yoo jẹ ranwọ fawọn olori ijọ lati le tete kesi awọn agbofinro ti wọn ba nilo iranwọ wọn.
Oba y ni CAN tun gbọdọ pa laṣẹ lasẹ fawọn ile ijọsin lati ra awọn irinṣẹ aabo ki wọn si lo irufẹ irinṣẹ naa lati fofin si ipakupa awọn ọmọ ijọ ni ile ijọsin wọn.

Kabiyesi to ba kan jẹ lori iṣẹlẹ ikọlu si ile ijọsin naa sọ pe iṣẹlẹ naa buru ''ti gbogbo eeyan si gbọdọ dide ni itako ikọlu si awọn ile ijọsin lati ọwọ awọn agbebọn ti wọn ko mọ''
Eselu tẹnumọ pe ki CAN ma sinmi lati bẹnu atẹ lu pipa ẹnikankan, yala musulumi tabi Kristẹni ni paapa labẹ awawi pe wọn sọrọ odi si ẹsin.
O ni iru iwa yi jẹ́ iwa ẹranko ti wọn ko si gbọdọ ba lọwọ awọn eeyan lawujọ ode oni.
O tun parọwa si gbogbo ọmọ Naijiria lati ''mu opin ba iwa ẹhanna yi lorileede Naijiria''
''Ọlọla julọ, o da lootọ pe ki a gbadura,iwe mimọ sọbẹ ṣugbọn a ko tun gbọdọ sun asunpiye gẹgẹ bi iwe mimọ ṣe sọ fun wa''












