'Ọmọ mi fura pé bàbá òun fẹ́ lọ fi òun ṣe òògùn owó ni'

Babalawo ati Evans

Iya ọmọdébìnrin ẹni ọdun mọkanla kan ni ó ti fi ẹsun kan baba ọmọ rẹ pe o n mú ọmọ naa lọ si ile onisegun làti fi ṣe ogún owo.

Iroyin ni nibi irinajo ni ọmọ naa ti fura pe baba òun fẹ fi ohun ṣe ogun owó ni.

Ninu ọrọ iya ọmọdébìnrin Elizabeth nigba ti o n ba Ile ise Tẹlifisan Ghana sọ̀rọ̀, o ni ṣe ni ọmọ naa fura lẹyin ti baba rẹ beere pe ojo woo ni wọn bí ọmọ naa sì aiye.

Ó tẹsiwaju pe ifura naa peleke nigba ti baba ọmọ náa ni ohun fe mú ọmọ lọ sí odo àwọn ransoranso láti wọn fun aso tuntun.

Ki ni iya rẹ ṣe?

Elizabeth ni oun kilọ fun ọmọ oun lati ibẹrẹ ojú ni alakan fi n sọ ori ti o ba ti n tẹle baba rẹ jade lọ si ọdọ ranṣọranṣọ.

"Mo ní ko gbọdọ mu omi ti baba rẹ ba gbe fun un ati pe ko gbọdọ sún loju ọna."

Mo ni ti wọn ba ni ko bọ aṣọ rẹ, kò má dáhùn kí ó sì pariwo le gbogbo wọn lórí ".

Ọmọdébìnrin ẹni ọdún mọkanla naa ninu akọsilẹ rẹ, ni nigba ti awọn n lọ lori irinajo, Baba òun ra apo sakasaka loju ona.

O ní oun o ro lọ pe ìle babaláwo ni awọn lọ nítorí gbogbo ọkàn òun ni pe àwọn lọ sí ọ do ransoranso.

O ni kete tí awọn de ibi kan ni Baba òun ni kí dẹrẹba ọkọ naa bọ lẹ, tí oun àti baba rẹ sì tẹsiwaju ninu irinajo naa.

Bawo ni wọn ṣe rin in ati pe ki lo ṣẹlẹ?

Ọmọdébìnrin naa ni nigbati awọn de bi ilé kan, baba oun pa ina moto, tí o si ni kí àwọn wọ inu ile babaláwo lọ.

"Gbogbo irinajo naa ni ko ye mi sugbọn nigba ti owo òfin mu baba mi ni wọn jẹwo pe wọn fẹ fi mi se ogun owo ni."

Ile ejo giga Accra ti wa fi Baba ọmọdébìnrin naa ẹni ọdun metadinlaadota si ahamo awọn olopaa lẹyin ti baba naa yoju si Ile ejo.

Ile ejo ni kò sí wa lahamo àwọn olopaa títí di asiko ti àwọn agbofinro yí o pari iwadi wọn lori isele naa.

Àṣírí tú! Babaláwo fi Ọlọ́pàá gbé Evans Oppong, afurasí tó gbé ọmọ rẹ̀ ọmọ ọdún mọ́kànlá wá ṣe oògùn owó

Ọwọ ṣinkun òfin ti tẹ arakunrin kan ti Babalawo adifa kan sọ pe o gbé ọmọ rẹ obinrin to jẹ ọmọ ọdun mọ́kànlá wa si ọdọ oun fun etutu ọla.

Evans Oppong jẹ ẹni ọdun mejilelogoji ọmọ orílẹ̀èdè Ghana to lọ sí ọdọ Babalawo pẹlu ọmọbinrin rẹ to ni ki wọn ba òun pa fun oogun owo.

Fidio iṣẹlẹ yìí to lu jade eyi to waye ni agbegbe Ámásà an ni Ghana n ya awọn araalu lẹ́nu gidi gan.

Bí Ọlọpaa ṣe rí afurasi náà mu ree -

Evans Oppong
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu fidio to tan kaakiri, afurasi naa ro aṣọ funfun mọ idi lai wọ ẹ̀wù kankan si aya.

Ó safihan rẹ to jokoo si ile Babalawo nigba ti awọn Ọlọpaa wọle de lẹyin rẹ ti ọkan lára wọn si sọ fun un pe to ba gbiyanju ati sá lọ, oun yoo yín ín níbọn.

Babalawo naa to n ka fídíò nkan to n ṣẹlẹ̀ lásìkò náà lọ ṣàlàyé fún àwọn Ọlọpaa pe oun pe wọn torí pe arákùnrin naa rọ òun láti pa ọmọ rẹ fun oogun owo.

Awọn Ọlọpaa ko ṣẹkẹsẹkẹ irin si Evans Oppong lọwọ ti ko si lee sọ̀rọ̀ kankan.

Babalawo naa, Nana Adu-Boafa ṣàlàyé pe baba ọmọbinrin naa sọ fun oun pe oun ṣẹ̀ṣẹ̀ de lati òkè òkun ni tori o ni aye ko dara fun oun.

Afurasi yìí ni oun ni ọmọ méjìlá ti oun si fẹ fi meji ninu wọn ṣe oògùn owó. Lafikun, Babalawo naa sọ pe arakunrin ọhun ṣèlérí láti fun oun ni ẹgbẹrun mewaa owó Ghana(Ghc10,000) atàwọn nkan nii tí wọn ba parí isẹ.

"Ohun to ba ni ninu jẹ ni pe o kan lọ mu ọmọ naa lasiko to wa nile ẹ̀kọ́ rẹ to sọ fun wọn pe awọn fẹ lọ ra aṣọ tuntun fún un.

Dipo ohun tó sọ, ile Babalawo lo mu wa to si ni ki wọn pa ọmọbìnrin naa fun oogun owo fun oun.

"Babalawo ni mi amọ Sójà náà tún ni mi. Mi o si ki n ṣe ibajẹ. Mo fẹ́ jẹ ki gbogbo ayé mọ pe awon Babalawo kii ṣe oniṣẹ ibi bí wọn ṣe maa n foju rẹ wo wá". Nana-Ado Boafa sọ nínú fídíò naa to ṣe.

Ọlọpaa ti mu ọkùnrin naa fún iwadii bayi ni Ọjọbọ ọjọ Kejì oṣù Kẹfà.

Gẹgẹ bi ohun tí Ọlọpaa sọ, wonyi òfin mu okunrin náà lẹyin ti olùfọkànsìn Babalawo yẹn ta wọn lolobo nípa erongba oníṣòwò náà.

Afurasi ọhun ti wa latimole Ọlọpaa báyìí láti seranwo nínú ìwádìí wọn.

Ẹwẹ, Ọlọpaa ni ọmọbinrin ọdún mọ́kànlá náà wa lalafia ni akoso awọn Ọlọpaa.

Ọlọpaa ni awọn ń ṣiṣẹ́ láti mu ki ọmọbìnrin naa darapọ mọ iya rẹ ati mọ̀lẹ́bí lalafia.