Ọmọ Nàìjíríà tó ń gbé ní US yìnbọn pa ìyàwó rẹ̀, ìyá ìyàwó ó tún pa ara rẹ̀

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Amerika ti fi idi rẹ mulẹ pe ọmọ Naijiria kan ni ilu Texas yinbọn fun iyawo rẹ ati iya iyawo rẹ, to si ji ọmọ gbe lọ, ki o to pa ara rẹ.
Arakunrin Obinna Dwayne Igbokwe ni ileeṣẹ ọlọpaa Montgomery kede pe o pa ara rẹ ni Ọjọbọ lasiko ti awọn ọlọpaa n le fun iwa ọdaran to hu ni Ọjọru.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ ni yii…
Ohun to ṣẹlẹ ni pe Obinna Dwayne Igbokwe ati iyawo rẹ, Tangela Igbokwe n ja lori ẹni ti yoo ṣakoso ọmọ oṣu mẹta to jẹ ọmọ wọn.
Ọga ọlọpaa ni agbegbe naa ni lasiko aigbọraẹniye lori ọrọ ọmọ naa lo yinbọn fun iyawo rẹ ati iya iyawo rẹ.
Nibayii, iyawo wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun, amọ iya iyawo ti ba iṣẹlẹ naa lọ. Iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe 30120 Block, Aldine Westfield Road, Spring Texas.
Saaju ni Ọga Ọlọpaa ti fi atẹjiṣẹ lede pe wọn n wa afurasi to gbe ọmọ salọ, to si pa iyawo ati iya iyawo rẹ.
‘’Igbokwe ko fẹ ki a fi panpẹ mu u lo ṣe pa ara rẹ.’’
Ileeṣẹ ọlọpaa Montgomery ni agọ ọlọpaa agbegbe Corsicana lo kọkọ pe pe ọmọ jojolo naa wa ni ikawọ wọn.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa Corsicana ṣe sọ fun wọn, arakunrin kan fi ọmọ rẹ silẹ ninu ọkọ rẹ, to si sọ fun wọn pe oun n bọ, amọ ko pada wa mọ.
Lẹyin igba diẹ ti wọn ko ri arakunrin naa ni ile itura to wa, ni wọn ke si ileeṣẹ ọlọpaa ọkọ ayọkẹlẹ ti ọkunrin wọ inu rẹ, to si sa lọ.
Nibẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa ti kan si awọn ọlọpaa ni agbegbe naa lati sọ fun wọn pe Obinna wa ni agbegbe naa.
Wọn ni lẹyin ti wọn le fun igba diẹ, ni ọkọ naa duro ni ibi ti wọn wa ọkọ gunlẹ si , ti wọn si gbọ ti iro ibọn ẹyọkan dun ninu ọkọ naa.
Bi awọn ẹṣọ agbofinro ṣe bẹrẹ si ni tiraka lati doola ẹmi rẹ ni wọn pe ileewosan amọ ọta ibọn naa ti ṣọṣẹ si lara, ti Igbokwe si ku nitori ibọn to yin fun ara rẹ.
Nibayii, ọmọ jojolo naa wa ni alaafia , ti wọn si ti gbe pada fun mọlẹbi rẹ.
‘’Ọkan wa wa pẹlu awọn ẹbi ti eleyii ṣakoba fun ti a si n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ti iṣẹlẹ naa ba lati fun wọn ni iranwọ to tọ.’’














