Osun 2022: Ẹnikẹ́ni tó bá fa rògbòdìyàn lásìkò ìbò yóò ríjà Ògún, Sango - Àwọn oníṣẹ̀ṣe

AWORAN IDANIMỌ AWỌN ONISESE

Bi eto idibo ipinlẹ Osun se sunmọ, awọn onisẹẹṣe ni ipinlẹ Osun ti kilọ fun awọn onijagidijagan to ba fẹ fa rogbodiyan tabi ni erongba lati da eto idibo ru lati ma gbinyanju rẹ rara nitori pẹ wọn o ri ija orisa Sango ati Ogun.

Dokita Oluseyi Atanda, Alaga fun ẹgbẹ onisẹẹse, ninu iforowero pẹlu BBC NEWS YORUBA sọ pe ọrọ naa kii ṣe ti awọn ara ilu nikan sugbọn pẹlu awọn oloṣelu ti o ba ni erongba lati da alafia ilu ru naa.

Atanda ni ọpọlọpọ ifa ni awọn ti da, ti ifa si ni ki awọn se ikilo fun ẹnikeni ko da ẹto idibo ru to ba di oṣu keje ọdun 2022.

O rọ awọn olori ẹlẹsin yoku lati beere adura fun alafia ni ipinlẹ Osun nitori pe awọn oloselu ati ololufe wọn gbodọ rii pe wọn yago fun rogbodiyan.

O ni; “Awọn oloṣelu kan ni erongba lati so eto idibo di jagidijagan ṣugbọn awọn oriṣa alalẹ o ni gba fun wọn.

“ Ati bẹ awọn oriṣa Sango ati Ogun ki ba ṣe idajọ fun ẹnikeni to ba fe fa rogbodiyan

“Mo rọ awọn ẹlẹsin. lati ma dake adura fun ibagbepo alafia ni ipinlẹ Oṣun