“Èmi lókàn, Eléyìí’, ‘Concensus’, Ọ̀dàlẹ̀” àtàwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tó gbòde lásìkò ìdìbò abẹ́nú APC l’Abuja

Idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress to waye mu ki ọpọ eeyan ni Naijiria ṣe aisun mọju ki wọn baa le mọ ibi ti esi idibo naa yoo ja si.
Dugbẹ dugbẹ naa to n mi ti wa jabọ bayii a si ti mọ ibi to ṣẹ si.
Amọ lasiko idibo yii ati asiko to ṣaaju rẹ, niṣe lawọn ọrọ kan jẹyọ pupọ loju opo ayelujara ati lẹnu awọn to n fi ọkan ba idije lati yan oludije ipo aarẹ ẹgbẹ APC ti yoo gbe asia ẹgbẹ dani lọdun 2023.
A gbiyanju lati ṣe akojọpọ awọn ọrọ yi latẹnu awọn tọrọ kan tabi iṣesi wọn ti awọn araalu si ti wa mu awọn ọrọ yi bẹnu bayii.
Die ree ninu wọn:
Consensus

Oríṣun àwòrán, Senatordrabdullahiadamu
Ni nkan bi ọdun meloo kan sẹyin aṣa tawọn oloṣelu maa n da lori pinpin ipo si ẹkun tabi agbegbe mii ni Zoning.
Amọ nibi idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC ni paapa fun ipo ẹni ti yoo dupo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ ni ifikunlukun,ajumọ fọwọ si to tunmọ si consensus lede oloyinbo.
Ki wọn to ṣe idibo abẹnu APC, gbolohun consensus ko tiẹ kọkọ yọju ṣugbọn bi ọjọ ṣe n sunmọ bọ lawọn ọmọ ẹgbẹ kookan ati awọn alatilẹyin n mọrọ yi bẹnu.
O debi pe awọn Gomina lati ariwa orileede Naijiria ni lati dasi ọrọ naa nipa pe wọn lawọn fẹ ki oludije ipo aarẹ wa lati iha Guusu Naijiria.
Ni ti tiẹ alaga ẹgbẹ APC Abdullahi Adamu kede pe aarẹ ile aṣofin orileede Naijiria Ahmad Lawan ni aarẹ buwọlu gẹgẹ bi oludije ajumọyan fẹgbẹ.
Abalọ ababọ awọn Gomina tapa si ọrọ yi ti aarẹ naa si sọ pe oun ko ni aayo kankan ninu awọn oludije.
Idije pada waye ti gbogbo oludije si lọsagbo ki o to di pe awọn kan bẹrẹ si ni juwọ silẹ fun awọn oludije ẹgbẹ wọn lọjọ idibo.
Ni ṣoki, consensus ko ṣiṣẹ nibi yiyan oludije ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ APC ninu idibo to pari
"Emi lo kan"

Ninu gbogbo awọn ọrọ taa ṣalabapade lasiko idibo abẹnu ẹgbẹ oṣleu APC nibi ti wọn ti yan oludije ti yoo dupo aarẹ labẹ ẹgbẹ, eleyi to gbode julọ ni ''emi lo kan''
Gbolohun yi jade lẹnu agbaọjẹ ẹgbẹ oṣelu APC Bola Ahmed Tinubu nigba to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ sọrọ nipinlẹ Ogun.
Awọn kan ni ibinu ni Tinubu fi sọ ọrọ yi amọ awọn agbodegba rẹ ni Tinubu fi ọrọ yi ṣe alaye pataki to fi lero pe o yẹ kawọn eeyan dibo fun to si sọ pe oun ti n farada ọpọ nkan fun ẹgbẹ tori naa lasiko yi'' ẹ gbe kini yi wa emi lo kan.''
Awọn eeyan mu ọrọ yi bẹnu koda awọn kan ṣe fidio orin ati awada yẹyẹ lorisi lati fi tun da ẹrin pa ẹkẹ araalu lori gbolohun yi.
Bi nkan ṣe n lọ bayi, o ṣeeṣe ki awọn ikọ ipolongo Asiwaju sọ di orin akunlẹkọ ti wọn yoo fi polngo pe lootọ awọn ro pe Tinubu lo kan lati de ipo aarẹ Naijiria.
"Eleyii"

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat
Ninu ọrọ tawọn eeyan tun n ran lẹnu leleyi to niṣe pẹlu Tinuba bakan naa ni bo ti ṣe dari ọrọ si Gomina ipinlẹ Ogun Dapo Abiodun nibi ipolongo to si pe Gomina ni ''eleyii.''
Laarin awọn Yoruba, a mọ pe ẹni to ba juni lọ le pe ẹni to kere si ni eleyii amọ bẹẹ naa la mọ pe pipe eeyan leleyii a maa mu abuku lọwọ.
Eleyii to jẹ ninu erongba abuku tabi ẹgbọn si aburo lawọn eeyan n jiyan le lori nipa bi Tinubu ṣe pe Gomina ipinlẹ taraalu dibo fun ni ''eleyii''
Kete to sọ ọrọ yi awọn eeyan loju opo ayelujara ba sọ di nkan ti wọn si n gba bi igba ọti.
Koda ọrọ ti o jade lati ọdọ Gomina to sọ pe oun kii ṣe ọbaluaye ati pe ipo Gomina kii se oye idile oun ko jẹ ko kuro lọkan awọn eeyan.
Eleyii jẹ gbolohun to ja rain tawọn eeyan si mu bẹnu lawọn ọjọ bu meloo kan ki idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC to waye.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
"Oore ati Ọdalẹ"
Awọn gbolohun mejeeji yi n ba ara wọn rin pupọ ti wọn a si ma jẹyọ ninu apejuwe tawọn alatilẹyin Bola Tinubu ati ti igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo fi n tahun si arawọn.
Lọdọ awọn to jẹ alatilẹyin fun Osinbajo wọn a maa ni Osinbajo mọ oore ti Tinubu ṣe fun eleyi to mu ko de ipo igbakeji aarẹ ṣugbọn ko tunmọ si pe ko gbọdo wa gbero lati de ibi giga ju ibi to wa lọ.
Ni itako awọn ti Asiwaju Tinubu a maa naka aleebu si igbakeji aarẹ pe o dalẹ ọga rẹ ni pẹlu bo ṣe fẹ dije dupo aarẹ Naijiria.
Ati orn eebu ati owe miran lawọn ikọ mejeeji yi a maa fi ranṣẹ si ara wọn paapa loju opo ayelujara.
Ọrọ naa doju rẹ debi pe awọn agbaagba ilẹ Yoruba ninu ẹgbẹ oṣelu APC pe ipade ifikunlukun lori ẹni ti wọn yoo yan gẹgẹ bi aṣoju ẹgbẹ fun ipo aarẹ.
Wọn par ipade naa pẹlu pe ko si ẹni to juwọ silẹ fun ara wọn amọ awọn agbaagba ni kawọn alatilẹyin oloṣelu kọọkan yago fun itabuku ara ẹni ki wọn si fi iwa ọmọluabi ṣe ipolongo ṣaaju idibo abẹnu to pada waye.
Igbakeji aarẹ ati Ice Cream

Gbolohun yi bẹẹ ṣe ri ninu aworan taa fi sita yi wa lati ẹnu Gomina tẹlẹ ri nipinlẹ Borno to si jẹ ọkan lara awọn to n ṣe ipolongo fun Bola Ahmed Tinubu fun ipo aarẹ.
O fi ọrọ yi lede ninu ifọrọwanilẹnuwo kan lori ẹrọ amohunmaworan Channels nibi to ti sọ pe lootọ ni igbakeji aarẹ jẹ eeyan daada ṣugbọn kii ṣe iru eeyan tawọn ọmọ Naijiria nilo lasiko yi.
Ọrọ yi naa mu ki oju opo ayelujara sọna tawọn kan si bẹrẹ si ni bẹnu atẹ lu pe o tabuku igbakeji aarẹ.
Boya lati fi polowo ọja nitori bi ọrọ ri ṣe gbode, eeyn kan wa sibi ipade apero ẹgbẹ ni Eagles Square ti wọn ti dibo abẹnu APC to si gbe ami kalẹ to ni kawọn eeyan wa mu Ice Cream ti Osinbajo ti n fun awọn ọmọ Naijiria mu lati ọjọ to ti pẹ.
Kashim Shettima pad tọrọ aforijin lọdọ Igbakeji aarẹ lori ọrọ to sọ yi.

Oríṣun àwòrán, Mohammed Jammal












