Wo kókó mẹ́wàá tó yẹ ko mọ̀ nípa Bola Tinubu, olùdíje ààrẹ fẹ́gbẹ APC

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ẹgbẹ oselu APC ti kede pe Oloye Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lo gbegba oroke ninu ibo abẹnu to se fun awọn oludije to fẹ du ipo aarẹ orilede yii.
Tinubu lo ni ibo.......................... ninu eto idibo naa, to si fi idi awọn oludije yoku janlẹ ninu ibo ọhun.
Ta ni Bola Tinubu, oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oselu APC?
Asiwaju Bola Ahmed Tinubu jẹ ọmọwe, to si nimọ nipa eto iṣiro, ọrọ aje.
Oun naa si tun ni adari ẹgbẹ oṣelu APC lati igba ti wọn ti da silẹ ni ọdun 2013.
Bola Tinubu to n dije dupo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu APC ti fi igba kan jẹ gomina ipinlẹ Eko lati ọdun 1999 si 2007.
Ọkan lara awọn orukọ ti awọn eniyan ma n pe ni Jagaban ati pe oun ni Baba isalẹ eto oṣelu ni ipinlẹ Eko ati Guusu Ariwa Naijiria.
Wo ohun to yẹ ko mọ nipa Ahmed Bola Tinubu?
- Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Oṣu Kẹta, ọdun 1952 ni wọn bi Tinubu ni ipinlẹ Osun, tii se ọdun aadọrin ọdun sẹyin
- Ẹlẹsin Musulumi ni Tinubu, to si jẹ ọkọ Arabinrin Olurẹmi Tinubu to jẹ sẹnatọ ni aarin gbungun ipinlẹ Eko
- Ibatan rẹ, Adewale Tinubu ni Ọga agba ileeṣẹ Oando
- Iya rẹ, Abibatu Mogaji jẹ oniṣowo to gbajumọ nigba naa, ki o to di iyalọja ipinlẹ Eko
- Iya Tinubu naa papoda ni Osu Kẹfa, ọdun 2014 lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun
- Bakan naa ni ọmọ Tinubu, Jide ku nilu London ni ọdun 2017
- Tinubu ni Aṣiwaju ti ipinlẹ Eko ati Jagaban ti ilu Borgu ni ipinlẹ Niger.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ẹkọ iwe kika
Ileẹko alakọbẹrẹ St. John's Primary School, Aroloya, ni ipinlẹ Eko ati ileẹkọ Children's Home School ni Ibadan ni Tinubu lọ.
Lẹyin naa lo lọ si orilẹede Amẹrika ni ọdun 1975, nibi to ti lọ kawe ni ileẹkọ Richard J. Daley College ni Chicago, Illinois, ko to ṣẹṣẹ wa lọ si ileẹkọ giga Chicago State University.
Nibẹ lo ti kẹkọ jade ni ọdun 1979 nipa imọ Accounting.
Iru iṣẹ wo lo kọkọ ṣe yatọ si oṣelu?
Ileeṣẹ ilẹ Amẹrika bii Arthur Andersen, Deloitte, Haskins &sells to fi mọ GTE Services Corporation ni Tinubu ti kọkọ ṣiṣẹ ni oke okun.
Lẹyin to padawa si Naijiria ni ọdun 1983 lo darapọ mọ ileeṣẹ Mobil Oil, to si di ọga patapata ni ileeṣẹ naa.
Bawo ni Tinubu ṣe bẹrẹ oṣelu?
Ọdun 1992 ni Tinubu bẹrẹ iṣẹ oṣelu lẹyin to darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party.
Awọn akẹẹgbẹ rẹ nigba to bẹrẹ oselu ni Shehu Musa Yar'Adua, Umaru Yar'Adua, Atiku Abubakar, ati Baba Gana Kingibe.
Awọn yoku ni Rabiu Kwankwaso, Abdullahi Aliyu Sumaila, Magaji Abdullahi, Dapo Sarumi atiYomi Edu.
Labẹ ẹgbẹ oṣelu naa lo ti lọ si ile igbimọ aṣofin agba lati ṣoju ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Eko.
Lẹyin ti wọn wọgile idibo aarẹ ti 12 June 1993 ni Tinubu oludasilẹ ẹgbẹ oṣelu National Democratic Coalition to n pe fun ijọba alagbada ati pe ki gbogbo agbaye gba pe Moshood Abiola lo bori ninu idibo sipo aarẹ ni Ọjọ Kejila, Oṣu Kẹfa.
Tinubu sa asala fun ẹmi rẹ ni ọdun 1994 nigba ti Ọgagun Sani Abacha fi ipa gbajọba.
Amọ Tinubu pada si Naijiria ni ọdun 1998 lẹyin iku Abacha, eleyii to bẹrẹ ijọba tiwantiwa Fourth Republic.
Bawo lo ṣe di gomina ipinlẹ Eko?
Bola Tinubu to jẹ aayo ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy (AD) ni idibo gbogboogbo ti ọdun 1999, labẹ iṣakoso awọn adari bii Abraham Adesanya ati Ayo Adebanjo lo gbegba oroke gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko.
Awọn ti wọn jọ figagbaga ninu idibo abẹle nigba naa ni Funsho Williams ati Wahab Dosunmu.
Ọdun mẹjọ lo lo ni ipo gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko lati ọdun 1999 titi de ọdun 2007, ti Babatunde Fashola ti ẹgbẹ oṣelu Action Congress, ti awọn eniyan gbagbọ wi pe Tinubu jẹ baba isalẹ fun si gbajọba.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Bola Tinubu ati ọrọ Baba isalẹ
Ero ọpọlọpọ eniyan nipe Tinubu ni baba isale ni ipinlẹ Eko nitori awọn iroyin pe oun lo di ọrọ aje ipinlẹ Eko mu.
Bakan naa ni iroyin gbe ni ọdun 2009 pe oun ati Fashola to jẹ gomina ipinlẹ Eko nigba naa kii ṣe ọrẹ mọ, amọ ti Fashola si pada wọle fun igba keji.
Amọ ni ọdun 2015 ni igbagbọ wa pe Tinubu lo fi Akinwunmi Anbode sibẹ gẹgẹ bi gomina, eleyii ti Fashola tako nigba naa.
Lẹyin naa lo tun fa ọwọ gomina to wa nibẹ lọwọlọwọ Babajide Sanwo-Olu si oke, lẹyin to kẹyin si Akinwunmi Ambode to dije dupo fun saa keji gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko amọ to padanu.
Ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan Bola Tinubu?
Lẹyin idibo ọdun 2007 ni ijọba apapọ gbe Tinubu lọ si iwaju Ajọ to n risi iwa jẹgudujẹra lori ẹsun pe oni apo iṣuna mẹrindinlogun si oke okun.
Amọ ni ọdun 2009 ni Ajọ EFCC kede pe Tinubu, James Ibori ati Obong Victor Attah ko jẹbi ẹsun iwa jẹdugujẹra.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa Ilẹ Gẹẹsi, Metropolitan Police ni ọdun 2009 ni ipinlẹ Eko wa lara awọn to ra ileeṣẹ ibanisọrọ Econet nigba naa,amọ to ti da Airtel bayii,ti wọn si fẹ lọ gbẹjọ rẹ ni ilẹ okeere.
Amọ ijọba apapọ kọ lati fun wọn ni ohun ti wọn nilo ki iwadii le tẹsiwaju.
Ni ọpọ igba ni awọn eniyan ti bu ẹnu atẹ lu bi Tinubu ṣe ma n lo Bullion Van lati gbe owo wọ inu ile rẹ to wa ni Bourdillion Road, ni Ikoyi.
Amọ esi ti Tinubu ma n fun wọn nipe ibikibi to ba wu oun ni oun le fi owo pamọ sii.
Ipa Tinubu ninu eto oṣelu Naijiria
Ni ọdun 2006, Tinubu gbiyanju lati jẹki Atiku Abubakar wa si ẹgbẹ oṣelu Action Congress lati wa dije du ipo aarẹ tako ọga rẹ, Olusegun Obasanjo nigba naa lọhun. Amọ Atiku fidi rẹmi ti ẹgbẹ oṣelu PDP si gbegba oroke.
Lẹyin idibo ọdun 2009 naa ni Tinubu bẹrẹ ijiroro lori ati gbe egbe alatako to lagbara dide tako ẹgbẹ oṣelu APC, eleyii ti abajade rẹ jẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ni ọdun 2013.
Ni ọdun 2014 ni Tinubu ṣe atilẹyin fun Muhammadu Buhari to ti dije du ipo aarẹ ni ọdun 2003, 2007, ati 2011 ko to bori ninu idije naa.
Tinubu kọkọ fẹ du ipo igbakeji aarẹ amọ o fi silẹ fun Yemi osinbajo to jẹ eniyan tirẹ ati kọmisọna fun eto idajọ, nipinle ̣Eko .
Lati ọdun 2015 titi di asiko yii ti ẹgbẹ oṣelu APC ti n ṣejọba ni Asiwaju ti n kopa ribiribi lati ripe ẹgbẹ naa tẹsiwaju.
Amọ ni ọdun 2020 ni ẹgbẹ yọ Adam Oshiomole kuro gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oṣelu naa, eleyii ti ọpọ ero wo pe lọna ati gbegi dina Tinubu pe oun fẹ dije du ipo aarẹ ni.
Amọ ni Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Kini, ọdun 2022 ni Tinubu fi lede pe oun fẹ dije du ipo aarẹ Naijiria, ti o si fitọ aarẹ Muhammadu Buhari leti.












