Obìnrin 19, ọkùnrin 12, ọmọdé 5, ọ̀dọ́ 2 ló kú nínú ìkọlù Owo - Bíṣọ́ọ́bù

Aworan

Biṣọọbu ijọ Ajuda ti Diocese ipinlẹ Ondo, Ẹniọwọ Jude Arogundade ti kede pe eniyan mejidinlogoji lo ku ninu iṣẹlẹ ikọlu to waye ni Ọjọ Isinmi, ni ile ijọsin St Francis Catholic Church, Ọwọ, ni ipinlẹ Ondo.

Ninu atẹjade ti ile ijọsin naa fi lede ni wọn ti ṣalaye bi iye awọn eniyan to ku ṣe ri.

Biṣọọbu naa ni iye awọn to wa ni ile igbokusi lọwọlọwọ jẹ mejidinlogoji , ti o si ṣeeṣe ki awọn kan ti wa gbe oku awọn eniyan wọn.

Amọ, gomina Akeredolu ti ipinlẹ Ondo kede pe eniyan mejilelogun lo ku ninu iṣẹlẹ naa lasiko to n ba awọn ara ipinlẹ Ondo sọrọ ni Ọjọ Keje, Oṣu Kẹfa, ọdun 2022.

Gomina Akeredolu si fi iye awọn eniyan to farapa to si n gba itọju lọwọ si eniyan mẹrindinlọgọta.

Arogundade ni awọn n ṣe iwadii, ti awọn si kesi awọn eniyan to gbe eniyan wọn lọ, ki wọn le ni aridaju lori iye eniyan to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Amọ awọn oku naa wa ni ile igbokusi Saint Louis Hospital, ni Ọwọ ati Ọwọ Medical Centre.

‘’Ninu awọn to ku naa ni ọmọkunrin mẹrin, ọmọbinrin kan, ọdọkunrin kan, ọdọbinrin kan, agbalagba ọkunrin mejila pẹlu agbalagba obinrin mọkandinlogun.’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Yemi Osinbajo

Bakan naa ni wọn ni ọpọlọpọ eniyan o ṣi wa ni ileewosan to fi mọ agba ati ọmọde.

Biṣọọbu naa ni awọn yoo tun ṣe isin adura fun awọn oku ni Ọjọ meje bẹrẹ lati Ọjọ Keje, Osu kẹfa tii di Ọjọ Karundinlogun, Osu kẹfa, ọdun 2022.

Wọn ni eleyii yoo tun fun wọn ni aaye lati ṣe isinku awọn eniyan awọn, ti awọn yoo si ṣe ni ọna ti yoo bu iyi kun ara awọn to ṣekọlu naa bajẹ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Akeredolu

Bakan naa ni wọn dupẹ lọwọ gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu fun akitiyan rẹ ati iduroti rẹ lasiko ikọlu naa, to fi mọ gbogbo awọn eniyan ati ileeṣẹ nlanla to duro ti wọn.

Wọn tun dupẹ lọwọ awọn to kọkọ de ibi iṣẹlẹ naa, awọn to fi ẹjẹ silẹ ni awọn ileewosan lati doola ẹmi awọn eniyan ati awọn dokita, nọọsi to gbiyanju takuntakun ni awọn ileewosan mejeeji ti wọn gbe awọn eniyan lọ.

Ikede ti ijọ St Francis fisita

Oríṣun àwòrán, Bishop Arogundade