Ilé sinimá ṣàfihàn fíìmù nípa ọmọ Ànọ́bì, The Lady of Heaven; wàhálà bẹ̀rẹ̀ ní UK

Ile sinima Cineworld ti fagile gbogbo ayẹwo fiimu kan to jẹ nipa ọmọbinrin Anọbi lẹyin ti o da iwọde silẹ niwaju awọn sile sinima kọọkan.
Awọn ile fiimu naa ni “a ṣe eyi lati da abo bo awọn oṣiṣẹ ati onibaara wa”.
O le ni eeyan ẹgbẹrun lọna ọgọfa to ti tọwọ bọ iwe ipẹjọ ni UK pe ki awọn ile sinima UK yọ fiimu “The Lady of Heaven”.
Igbimọ awọn Mọṣalaṣi Bolton sọ pe fiimu naa sọrọ odi si Anọbi to si ni ṣe pẹlu igbagbọ kan pato.
Fiimu naa ti da iwọde silẹ bayii ni Bolton, Birmingham ati ni Sheffield.
Ki lo de ti fiimu naa da wahala silẹ?
Fiimu naa ti wọn gbe jade ni Sinima kan ni ilu London ni ọjọ Kẹta oṣu Kẹfa ni wọn ni o sọ itan nipa Arabinrin Fatima, ọmọ Anọbi.
Awọn ẹgbẹ Musulumi kan fi ẹsun kan pe fiimu naa n ṣafihan Anọbi ni ọna to tabuku ba ẹsin Islam.
O le ni eeyan ẹgbẹrun lọna ọgọfa to tọwọ bọ iwe pe ki wọn yọ fiimu naa kuro eyi to da lori bi ẹlẹsin Musulumi Shiite oni fiimu kan ati Alfa Yasser Al-Habib ṣe ṣafihan awọn eekan ẹsin laye igba Sunni ninu Islam eyi to si fihan pe o n ṣafiwe iṣesi wọn pẹlu ti awọn ẹgbẹ Islamic State ni iraq.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ẹwẹ, awọn adari iwọde naa ti nigba ti awọn n fẹ ki wọn gbegi le fiimu naa, iwọde alafia ni awọn n ṣe amọ awọn ile sinima ni tiwọn lero pe iwa yii nni wọn fi n dẹru bolẹ eyi to si to lati jẹ ki awọn ma ṣafihan fiimu naa. Amọ loju opo ayelujara ti awọn to ṣe fiimu naa, wọn ṣalaye pe “ko sohun to jọ dida ṣafihan ẹni mimọ kankan dipo eyi, a lo awọn oṣere ara ọtọ a si lo ọṣọ bii ina ati ọṣọ mii fi gbe e jade”. Amọ nibayii, tori ohun to bẹrẹ, agbẹnusọ Cineworld ti fi ọrọ sita pe awọn ti so ṣiṣafihan fiimu naa fun ayẹwo rọ na.















