Ẹ̀rù n bá wà kí Russia má kọlù wa tí a bá gbà láti kó oúnjẹ òníhóró gba ibùdókọ̀ omi Black Sea - Ukraine

Ibi ti wọn ko ounjẹ onihoro Wheat si ni Ukraine

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aarẹ ẹgbẹ́ awọn agbẹ oúnjẹ onihoro ni Ukraine, Nikolay Gorbachov, ti kọ àbá ti awọn kan dá pe ki wọn o lo Gusu Ukraine ati ilẹ Yúróòpù, gẹgẹ bi ọna miran lati ko oúnjẹ jade dipo Black Sea. Orile-ede Ukraine ma n ko bii miliọnu mẹfa si meje toonu oúnjẹ onihoro ati èso to n sun òróró, lọ silẹ okeere loṣooṣu, lati ibudokọ omi Black Sea. Ṣùgbọ́n eyi ko ṣeeṣe mọ lati igba ti ogun Russia ti bẹ̀rẹ̀. Ọgbẹni Gorbachov sọ fun BBC pe ilẹ Yoroopu ko ni awọn eroja ati irinṣẹ lati mojuto iye oúnjẹ onihoro ti Ukraine n ta silẹ okeere. O ni ṣugbọn " lati ibode Gusu Ukraine, a le ko bii miliọnu kan aabọ jáde". Lori ipade ijororo kan to waye niluu Ankara, laarin minisita fun ilẹ okeere ni Russia, Sergie Lavrov ati akẹẹgbẹ rẹ lati Turkey, Mevlut Cavusoglu, Gorbachov sọ pe Ukraine gbọdọ kopa ninu gbogbo ijoro ọna abayọ ti yoo ba waye.

Ẹwẹ, ijọba Ukraine ti sọ pe ileri òfo ni ọrọ ti minisita ọrọ ilẹ̀ okeere ni Russia sọ pe, ti Ukraine ba fi aaye gba kiko àwọn oúnjẹ onihoro gba ibudokọ omi Black Sea, awọn ko nii lo anfaani naa lati kọlu wọn. Sergie Lavrov ṣe ileri naa lẹyin ijiroro rẹ pẹlu akẹẹgbẹ rẹ lati Turkey, to n gbiyanju lati mu ki wọn o ṣi aaye silẹ ni budokọ omi. Lavrov sọ pe orile-ede oun kọ lo n di kiko Wheat jade ni Ukraine. O ni Ukraine fúnra rẹ lo nilo lati ṣe atunse oju omi naa. Sugbọn Ukraine ni ẹru n ba oun ki Russia ma lọ lo anfaani naa lati kọluu. Agbẹnusọ ileeṣẹ ilẹ̀ okeere ni Ukraine, Oleg Nikolenko sọ pe àwọn nilo irinṣẹ ijagun lati daabo bo eti òkun naa, ati awọn ọmọ ogun ori omi ti yoo maa lọ kaakiri àwọn ibi ti ẹrù n gba jade. O ni àwọn ko le jẹ ki Russia lo anfaani pe awọn fẹẹ ko oúnjẹ onihoro lọ silẹ okeere, lati kọlu àwọn.