Ọlọ́kadà pa ènìyàn kan l’Eko, àwọn ọ̀dọ́ jó ọ̀pọ̀ ọ̀kadà níná

Oríṣun àwòrán, Yakubu Usman/Twitter
Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ ní ilé ìgbé ẹ́sítèètì Jakande ní agbègbè Oke Afa, Isheri, ìpínlẹ̀ Eko lẹ́yìn ọlọ́kadà gbá ọkùrin kan, tí onítọ̀hún sì jẹ́ Ọlọ́run nípè.
Ọlọ́kadà náà tí wọ́n kò tíì mọ orúkọ rẹ̀ títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, ló gba ọ̀nà tí kìí ṣe tirẹ̀, tó sì lọ yà pa ọkùnrin ọ̀hún níbi tó dúró sí ní ẹ̀bá títì ní ìkóríta First Junction.
Àwọn ti ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọn ní kò pẹ́ tí ọlọ́kadà yìí kọlu ẹni náà, ló gbé ẹ̀mí mì.
Èyí ló bí àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò náà nínú tí wọ́n sì gbèrò láti gbẹ̀san ikú ọkùnrin náà lára ọlọ́kadà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní lù ú.
Níbi tí wọ́n ti ń lù ú lọ́wọ́ ní àwọn ọlọ́pàá kan gbà á kalẹ̀ lọ́wọ́ wọn ṣùgbọ́n àwọn ọ̀dọ́ náà gba ọ̀kadà rẹ̀ kalẹ̀ àti gbogbo ọ̀kadà tó bá kọjá ní àsìkò náà láti fi ẹ̀hónú wọn hàn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó wáyé náà.
Nígbà tí àwọn ọlọ́pàá gbé ọlọ́kadà tí àwọn ọ̀dọ́ náà ti lù ní àlùbami lọ sí ilé ìwòsàn ní àwọn ọ̀dọ́ ọ́hún bẹ̀rẹ̀ sí ní jo gbogbo àwọn ọ̀kadà tí wọ́n ti gba kalẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́kadà tí àwọn ènìyàn yìí ń gbà ló fi ọ̀kadà wọn kalẹ̀ nítorí ìbẹ̀rùbojo pé kí wọ́n má ba à lu àwọn pa tàbí jó àwọn náà níná.
Lára àwọn ará àdúgbò náà tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní inú ìbẹ̀rùbojo ni àwọn wà báyìí nítorí àwọn kò ohun tí àwọn tó ni ọ̀kadà, èyí ọ̀pọ̀ wọn jẹ́ ará òkè ọya le ṣe fún àwọn.
Wọ́n ní lóòótọ́ ni pé àwọn ọlọ́kadà náà ti máa ń gba òpópónà márosẹ̀ náà kọjá tipẹ́tipẹ́, wọn kìí tẹ̀lé òfin ètò ìrìnnà bó ti yẹ.
Wọ́n fi kun pe ọ̀nà tí kìí ṣe ti wọ́n ni wọ́n máa ń gbà ní gbogbo ìgbà, tí wọ́n sì máa ń díná mọ́ àwọn tó ni ọ̀nà gan.
Bákan náà ni wọ́n fi kun pé kò ní ọgbọ̀n ọ̀kadà tí àwọn ọ̀dọ́ náà gbà lọ́wọ́ àwọn Aboki tó ń gun ọ̀kadà tí wọ́n sì jó gbogbo rẹ̀ níná ráúráú.
Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn onílé ní ilé ìgbá náà, Fatai Oloko ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àti igbákejì aága ìjọba ìbílẹ̀ Ejigbo ti ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti ri dájú pé àwọn ọlọ́kadà náà kò ṣe ìkọlù sí àwọn ènìyàn agbègbè náà padà.
Ọlọpaa koro oju si iwa ipanle tawọn ọdọ hu sawọn ọlọkada:
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko, Benjamin Hundeyin bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò náà ṣe gbẹ̀san ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọwọ́ ara wọn.
Hundeyin ní ohun gbogbo ti padà bọ̀ sípò ní agbègbè ọ̀hún tí àwọn sì ń ṣiṣẹ́ láti ri dájú pé irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò wáyé mọ́.
Bákan náà ló sọ wí pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò fi àyè gba kí ènìyàn máa gbẹ̀san lọ́wọ́ ara wọn àti pé ẹnikẹ́ni tí àwọn bá mu fún ìwà bẹ́ẹ̀ yóò fojú wíná òfin.
Olè ló yìnbọn pa èèyàn márùn-ún ní Ondo kìí ṣe àwọn tó fẹ́ gbẹ́san ìkọlù Owo - Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, others
Ko din ni eeyan mẹfa ti awọn agbebọn pa nilu Ondo, nipinlẹ Ondo lọjọru.
Iṣẹlẹ naa waye lẹyin ọjọ mẹta ti awọn agbebọn pa ogoji eeyan nibi ikọlu ile ijọsin kan nilu Owo, lọjọ Aiku.
Iroyin to jade sori ayelujara sọ pe awọn eeyan kan lo kọlu agbegbe ibi ti awọn ẹya Hausa n gbe, nilu Ondo loru Ọjọru.
Ṣugbọn agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, Funmilayo Odunlami sọ ninu atẹjade kan pe awọn adigunjale lo pa awọn eeyan naa.
Odunlami ni ayederu ni iroyin to sọ pe awọn eeyan kan kọlu awọn Hausa, lati gbẹsan ikọlu to waye ni Owo.
“Ni oru ọjọru, awọn adigunjale kan gbiyanju lati ja ọkọ akẹru J5 kan to ko alubọsa ati anọmọ, lati ilu Zaria, nipinlẹ Kaduna, to si n lọ si Ore.
“Amọ o duro ni Ondo lati sinmi. Nibi to duro si ni awọn adigunjale ti kọlu wọn ni nkan bi aago kan kọja iṣẹju mẹwaa loru, ti wọn si yinbọn pa awakọ.”
Arabinrin Odunlami ṣalaye pe wọn yinbọn mọ ọmọ-iṣẹ awakọ naa, amọ o raaye salọ pẹlu ọgbẹ ọta ibọn.
Bakan naa lo sọ pe aṣita ibọn tun ba ọlọkada kan, eero to gbe sẹyin, ati ẹnikan to n kọja lọ.
Ọjọ Aiku, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ni awọn agbebọn ti ẹnikan ko mọ yabo ile ijọsin St. Francis Catholic Church, nilu Owo, ti wọn si yinbọn mọ awọn olujọsin.
Awọn alaṣẹ sọ pe ogoji eeyan lo ti ku bayii nipasẹ isẹlẹ naa, ti ọpọ si n gba itọju nileewosan.
Gomina Rotimi Akeredolu sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyi to jani laya, ti oun ko si nireti iru rẹ rara.
“Iṣẹlẹ yii ba mi lojiji. Ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, ao lo gbogbo nkan to wa ni ikapa wa, lati mu awọn to ṣe ikọlu yii.
Ikọlu yii mu iporuru ọkan ba ọpọ ọmọ Naijriia nile ati nilẹ okeere.
Ti ọpọ si b pariwo pe ki ijọba tete wa nkan sẹ si iṣoro eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.












