"Ẹsẹ̀ mí kẹ̀, ó dojú kọ ara wọn bíi pẹ́rẹ́gi, ìṣẹ́ abẹ kẹta ló mú kó nà padà"

Àkọlé fídíò, Adebola Dada: Ó dùn mí tí wọn bá pè mí ní ẹlẹ́sẹ̀ pẹ́rẹ́gi

Adebola Oluwole Dada jẹ obinrin kan ti ẹsẹ rẹ kẹ lati kekere, eyi ti wn n pe ni Bow leg.

Ẹsẹ naa kẹ to bẹẹ gẹẹ debi pe wọn doju kọ ara wọn ni, to si maa n dun to ba n rin lọ.

Nigba to ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn ipenija ati idẹyẹsi to koju nitori pe ẹsẹ rẹ kẹ sinu, Adebola salaye pe ẹlẹsẹ pẹrẹgi ni wn pe oun ni kekere.

O fikun pe bi o tilẹ jẹ pe oun sisẹ abẹ lati na ẹsẹ naa nigba ti oun wa ni ọmọ ọdun mẹfa ati nigba ti oun sinru ilu NYSC tan, sibẹ ẹsẹ naa tun pada kẹ.

Adebola ni o maa n dun oun nigba ti oun ba n rin lọ, ti ọpọ eeyan si n tẹju mọ oun.

Amọ o salaye pe isoro naa di ohun itan lẹyin ti oun se igbeyawo, ti oun si bi gbogbo ọmọ ọmọ inu oun tan.

O ni asiko yii ni oun pada lọ se isẹ abẹ ẹlẹẹkẹta, ki ẹsẹ mejeeji naa to na pada, ti inu oun si dun pupọ.

Adebola, tii se osisẹ agbohunsafẹfẹ salaye pe lasiko ti oun n la isoro ẹsẹ oun mejeeji to kẹ naa kọja, oun ko jẹ ki irẹwẹsi de ba ọkan oun lati de ibi ti oun pinnu lati de nile aye.

O wa n gba gbogbo awọn eeyan to n koju irufẹ isoro yii nimọran lati mase jẹ ki ipenija naa mu akude ba ọkan wọn , amọ ki wn pinnu lati de ibi giga ti wn fẹ.