'Ọba wa, "Fon" kìí kú nìlùú tiwa! Èèwọ̀ ni'!

Ọba wa kìí kú, ó ma ń pòórá ni

Aworan Oba Cameroon

Fun awọn ara agbegbe Mankon ni iwọ oorun ariwa orilẹede Cameroon, ọba wọn kii ku niṣe lo ma n yipada.

Ohun lo mu ki awọn ara agbegbe Mankon fun gomina Adolphe Lele ni epe nitori o kede iḳu oba Fon Angwafor to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgọrun.

Agbẹjọro Joseph Fru Awah to jẹ ọmọ ilẹ Makon to dantọ ni ‘’Fon ni ọba gbogbo ila Mankon ti awọn ara agbegbe naa n bu ọla fun’’

Wọn rii gẹgẹ bi alakoso isin ati igbagbọ wọn, ati ẹni to wa laarin ọrun ati aye, ana ati oni , aye yii ati aye to n bọ.

Aworan

Ọdun 1959 lo gori aleefa gẹgẹ bi Fon Angwafor lll, to si jẹ ọba akọḳo ti yoo lọ si ileẹkọ lasiko ti awọn kan gbagbọ wi pe awọn ọmọ araalu lo n lọ si ileẹkọ.

O kawe yanju to si ni iwe ẹri imọ nipa iṣẹ agbẹ lọna igbalode, niti iṣ̣e agbẹ lo wọpọ julọ ni agbegbe naa.

Awọn ara Angwafor wọn ma n pe ọba wọn ni ọba Solomon to wa ninu Bibeli.

Bakan naa lo ni ọpọlọpọ iyawo to fi mọ awọn ọdọlangba, eleyii ti wọn so pe wọn pọ lorisirisi.

Amọ awọn kan bu ẹnu atẹ lu ọba naa pe oun lo wa ni idi bi wọn ṣeṣe ajọsọpọ laarin awọn ọmọ ilẹ Cameroon to n sọ Ede Faranse ati awọn to n sọ ede oyinbo.

Bakan naa lo ṣiṣẹ gẹgẹ bi igbakeji orilẹede naa labẹ aarẹ Paul Biya ni ọdun 1990.

Ipo yii lo di mu ki o to poora laipẹ yii.

Eewọ ni ki awọn eniyan sunkun Ọba to poora.

Ko ju ọsẹ mẹta lọ ti akọwe ikọ afọbajẹ ni Makon, Kwifor kede pe Fon ti poora.

Bio tilẹ ṣepe wọn ti gbe ọba naa wulẹ, ti wọn ko gbọdọ sọ pe wọn sin si agbegbe kan ti awọn eniyan ko mọ rara.

Eewọ ni lati sọ pe wọn ti sin ọba wọn, bẹẹ si ni ko gbọdọ si ẹnikẹni to gbọdọ sunkun lori ọrọ ọba naa.

Lẹyin ti wọn kede pipoora rẹ ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Oṣu Karun ni awọn agbaagba ọkunrin pejọ laiwọ bata ti awọn obinrin ko si lọ si oko lati bu ọla fun ọba naa.

Aworan

Wọn sọ okuta lu ọba tuntun

Ni ọjọ ti ọba naa gori oye ni awọn eniyan wọ aṣọ pelebe lati ara ọgẹde ati bamboo, ti oke ara wọn si wa ni ṣiṣi yatọ fun awọn obinrin to wọ bra dudu.

Ọba tuntun naa to jẹ ọmọ Fon Angwafor ni wọn sin de aafin ọba.

Lasiko to n lọ si inu aafin naa ni awọn eniyan ri to n fi ẹsẹ rin, lai wọ aṣọ si oke ara re yatọ si aṣọ funfun penpe to wọ si ibadi rẹ.

Bi o ṣe n lọ ni wọn n da iyẹpẹ si lara, pẹlu okuta keekeeke. Ti ohun naa si sa wọ inu aafin lọ.

Lẹyin naa lo pada jade pẹlu aṣọ alaranbara, ti wọn si kede rẹ gẹgẹ bi ọba tuntun to jipada wa lẹyin to poora.

Aworan
Aworan

Nitori naa ọba wọn kii ku, ti o si ma n lọ gbe aawọ ẹlomiran wọ ni.

Awọn eniyan gbadura pe ki o di asa ati iṣe ilẹ naa mu lai taanu bi baba rẹ ṣe di asa ati iṣe mu titi to fi poora.

Amọ ohun kan ti ko waye ni yinyin ibọn fun ikira ọba tuntun nitori ijọba ti fofin de lilo ibọn nitori ija to n lọ ni agbegbe naa lati ọdun 2017.

Erongba awọn eniyan nipe ọba tuntun naa yoo gbimọ lori bi alaafia yoo ṣe jọba ni orilẹede naa.