Wo ojú díẹ̀ lára àwọn tó kú nínú ìkọlù ṣọ́ọ̀ṣì Owo àti ìròyìn nípa wọn

Awọn to ku ninu ikọlu Owo

Ọjọ buruku esu gbomi mu ati ọjọ manigbagbe ni ọjọ Aiku, ọjọ Karun osu kẹfa ọdun 2022 jẹ nilu Owo, ipinlẹ Ondo, ilẹ Yoruba, Naijiria ati lawujọ agbaye lapapọ.

Idi ni pe ọjọ yii gan ni awọnn agbebọn kan ya bo ijọ aguda St Francis nilu Owo, ti wn si seku pa eeyan to to ogoji nigba ti ọpọlọpọ miran fara pa.

Awọn osisẹ agbofinro ati awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn salaye pe ado iku ni awọn agbebọn naa yin, ki wọn to wọ inu sọọsi naa, ti wọn si n yinbọn mọ awọn olujọsin.

Isẹlẹ yii lo da omi tutu si ọkan ọpọ eeyan, idi si ree ti BBC fi se akojọpọ iroyin nipa diẹ lara awọn eeyan to fori sọta isẹlẹ naa.

Ẹ wo ojú díẹ̀ lára àwọn tó kú nínú ìkọlù ṣọ́ọ̀ṣọ̀ Owo àti ìròyìn nípa wọn:

Caroline Agboola

Oríṣun àwòrán, Caroline Agboola

Caroline Agboola:

Lara awọn obinrin to ku ninu ikọlu naa ni mama Caroline Agboola ti ọpọ eeyan mọ si Mama Alakara.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, ọmọ ọmọ mama naa ni awọn dijọ lọ sile ijọsin lọjọ naa ni.

Amọ o ni oun lọ sa pamọ si ile iyagbẹ awọn alufa to wa lẹba ppẹ nigba tawọn agbebọn de.

Nigba ti ikọlu naa si pari, ti oun jade, ni oun ri oku mama agba oun nilẹ, to ti dagbere faye.

Veginus Nwani

Oríṣun àwòrán, Veginus Nwani

Veginus Nwani:

Veginus Nwani ati ọmọ rẹ obinrin kekere, Chidiogo ni wọn dijọ ku sinu ikọlu naa.

Bi o tilẹ jẹ pe akọbi baba naa to jẹ ọkunrin wa nile ijọsin naa lasiko ti isẹlẹ yii n waye amọ ohunkohun ko se e rara.

Ni kete ti ikọlu naa waye, awọn eeyan ti isẹlẹ ọhun soju wọn sọ fun BBC pe se ni akọbi Veginus gbe aburo rẹ digbadigba re ile iwosan fun itọju.

Sugbọn wọn ni o se ni laanu pe ẹpa ko boro mọ, ọmọdebinrin naa ti tẹri gbasọ.

Chidiogo Nwani

Oríṣun àwòrán, Chidiogo Nwani

Chidiogo Nwani:

Chidiogo, tii se ọmọdebinrin ni oun ati baba rẹ, Veginus Nwani dijọ lọ jọsin lọjọ ikọlu agbebọn naa.

Awọn mejeeji si lo jẹ Ọlọrun nipa lasiko isẹlẹ naa.

Umunna

Oríṣun àwòrán, Umunna

Umunna:

Bakan naa, Umunna ati ọmọdekunrin rẹ ni ọta ibọn ba lasiko ikọlu agbebọn naa.

Lẹyin ikọlu naa si ni wọn ri oku Umunna to da ara rẹ bo ọmọ rẹ mọlẹ, tawọn mejeeji si wa ninu agbara ẹjẹ.

Awọn ti isẹlẹ naa soju wn ni ọkunrin naa n tiraka lati daabo bo ọmọ rẹ lọwọ ọta ibọn lo se bo o mọlẹ.

Amọ awọn mejeeji ni wọn dijọ dagbere faye.

Awọn eroja to n lo ina ọba si ni Umunna n ta nilu Owo nibi to ti jade laye.

Ozurumba Bridget

Oríṣun àwòrán, Ozurumba Bridget

Ozurumba Bridget:

Mama Brifget Ozurumba naa ba isẹlẹ ikọlu agbebọn naa rin.

Oun ati ọmọ rẹ ọkunrin si ni wn dijọ lọ sile ijọsin lọjọ naa nigba ti isẹlẹ naa waye.

Bi o tilẹ jẹ pe mama yii ati ọmọ rẹ naa ni ọta ibọn dijọ ba, amọ ọkunrin naa si wa nile iwosan nibi to ti n gba itọju lọwọ.

Mr and Mrs Onuoha

Oríṣun àwòrán, Mr and Mrs Onuoha

Mama ati baba Onuoha:

Tọkọ tiyawo ni mama ati baba Onuoha, tawọn mejeeji si jade laye lasiko ikọlu naa.

Ọgbẹ ọta ibọn ti wọn gba sara lo se iku pa wọn lasiko ikọlu naa.

Bakan naa ni awọn tọkọtaya yii lọsile ijọsin naa pẹlu ọmọ wọn amọ ko si ohunkohun to se ọmọ naa.

Asọgba ni baba Onuoha ko to jade laye nigba ti iyawo rẹ n ta ọja pẹ pẹ pẹ.