Ìwà kí obìnrin kan bá obìnrin míràn gbé òyún-bímọ̀ di okoòwò ńlá, òfin wo ló tì í lẹ́yìn?

Àkọlé fídíò, Ìwà kí obìnrin kan bá obìnrin míràn gbé òyún-bímọ̀ di okoòwò ńlá, òfin wo ló tì í lẹ́yìn?
Ìwà kí obìnrin kan bá obìnrin míràn gbé òyún-bímọ̀ di okoòwò ńlá, òfin wo ló tì í lẹ́yìn?

Ọmọ niyun, ọmọnidẹ, ọmọ nidẹ, ọmọ ni asẹyinde to ba di ọjọ alẹ.

Bi ọmọ se dara to yii, awọn obinrin kan wa nidi bibẹ Ọlọrun pe ko fun awọn ọmọ tori bo se nira to fun wọn lati ri ọmọ bi.

Lootọ ni Yoruba sọ pe Olowo ko le ri ọmọ ra lọja sugbọn lasiko yii, pẹlu imọ igbalode, olowo ti n ri ọmọ ra nile iwosan pẹlu iranlọwọ ẹlomiran.

Eyi si n waye lati ipasẹ sisan owo fun awọn obinrin kan lati ba awọn obinrin gbe oyun, awọn ti ile ọmọ wọn ko le gbe oyun, tori ailera kan tabi omiran

Asa sisan owo fun obinrin kan lati ba obinrin miran gbe oyun naa si ni wọn n pe ni Surrogacy.

Obinrin oloyun

Awọn obinrin ti ilera wọn pe, ko fẹ gbe oyun funra wọn mọ, ọpọ obinrin n fi isẹ biba ẹlomiran gbe oyun ṣe okoowo

Asa biba ẹlomiran yii si lo ti n wọpọ lode oni, ti ọpọ obinrin ti wọn n pe ni agan, si di ọlọmọ laye.

Gbogbo eeyan si lo mọ pe ara isẹ obinrin to se koko ni oyun nini ati ọmọ bibi.

Lasiko ti obinrin ba loyun, ọpọ irora ati inira lo maa n la kọja, ti inira lasiko ibimọ naa si lagbara.

Lasiko yii, lọna lati yago fun irora ati inra to rọ mọ oyun nini ati ọmọ bibi, awọn obinrin kan, ti ilera wọn gan pe lati loyun, ki wọn si bi ọmọ, lo tun n pada sanwo fun awọn obinrin miran lati gbe oyun fun wọn, ki wọn si bimọ naa fun wọn.

Boya eyi lo si faa ti awọn obinrin kan se n fi isẹ biba ẹlomiran gbe oyun yii se isẹ se.

Ṣe ofin wa to de iwa biba ẹlomiran gbe oyun tàbí fi ṣe okoòwò?

N jẹ se ofin kankan wa nilẹ Naijiria to rọ iwa biba ẹlomiran gbe oyun?

Se ofin ilẹ wa tiẹ fi aaye gba a lati maa fi iwa biba ẹlomiran gbe oyun se okoowo lati pawo wọle fun ara ẹni loore koore?

BBC Yoruba wa tọ amofin kan lọ, lati mọ ohun ti ofin sọ nipa asa yii, ti a si gbọ pe ni Naijiria lonii, ko tii si ofin to rọ mọ asa biba ẹlomiran gbe oyun.