Ilé ẹjọ́ pàṣẹ fún ọdọ́ méjì tó tọ̀ sínú ìkòkò ọbẹ̀ láti san $300,000 owó ìtanràn

Aworan ounjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ọdọ meji kan to tọ si ikoko ọbẹ ni ile ounjẹ, Hotpot ni wọn ti palaṣẹ fun pe ki wọn san owo itanran 2.2m yuan ($309,000; £227,000) fun ileeṣẹ ounjẹ meji lorilẹede China.

Iṣẹlẹ yii to waye ni oṣu Keji ọdun 2025 ni agbegbe Shanghai, to jẹ ibudo ile ounjẹ hotpot chain Haidilao, lo ti fa ọpọ awuyewuye, ti ọpọ si ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa lẹyin ti awọn ọdọ naa to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun gbe fọnran iwa ti wọn hu sori ayelujara.

Ko si ẹnikẹni to le sọ boya ẹnikẹni jẹ ninu ọbẹ ọhun, ṣugbọn ileeṣẹ Haidila ti ni awọn ṣetan lati san owo fun ọpọ eeyan to jẹun ni ile ounjẹ naa lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye ati lẹyin rẹ.

Ni oṣu kẹta, Ileeṣẹ Haidilao padanu owo to ju 23m yuan lọ, lasiko ti wọn san owo fun awọn onibaara wọn lori iṣẹlẹ naa.

Ni ọsẹ to kọja, ile ẹjọ Shanghai ni pe awọn ọdọ naa jẹbi ẹsun ti wọn ka si wọn lẹsẹ, ti ile ẹjọ si ṣapejuwe ohun ti wọn ṣe gẹgẹ bii iwa adojutini, ti wọn si ni iwa ọhun da alaafia ilu laamu.

Bakan naa ni ile ẹjọ tun fẹsun kan awọn obi awọn ọdọ mejeeji, fun bi wọn ṣe kuna lati ṣe itọsọna awọn ọdọ naa ni ọna to yẹ, ki wọn san owo ni apo ara wọn.

Ileẹjọ tun fikun pe eyikeyi owo ti ileeṣẹ Haidilao ba san fun awọn onibaara rẹ, lo jẹ igbesẹ ti ileeṣẹ naa fọwọ si, ti wọn ko si le ni ki awọn ọdọ naa da a pada. .

Ileeṣẹ Haidilao ti pinnu lati san owo fun awọn onibaara to le ni ẹgbẹrun mẹrin to wa si ile ounjẹ laarin ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji, ọjọ ti wọn ti wọn tọ sinu ọbẹ ati ọjọ kẹjọ oṣu kẹta, ti wọn si san owo naa ni ilọpo mẹwaa iye owo ti awọn onibaara wọn san.

Bakan naa ni wọn tun ṣe paarọ gbogbo awọn irinsẹ ti wọn fi n dana pata.

Haidilao ni ile itaja ounjẹ to to ẹgbẹrun kan kaakiri agbaye.