BBC tú àṣírí oníṣòwò tó ń kó àwọn obìnrin ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó, fún wọn ní ìgbọ̀nsẹ̀ jẹ ní Dubai

Àkọlé fídíò, BBC Eye
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9
Aworan yii ṣafihan Charles Mwegiswa, eyin rẹ meji han nita, o n wo ọọkan, o wọṣo dudu to ni ila funfun tẹẹrẹtẹ
Àkọlé àwòrán, Charles Mwesigwa, oniṣowo to n ko awọn obinrin ṣowo nabi Ni Dubai.

Ìkìlọ̀: Ohun to le ba ọ lọkan jẹ wa ninu àyọkà yìí

Ka maa fi ẹtan ko awọn eeyan lọ silẹ okeere pe ki wọn wa lọ ṣiṣẹ to ba ofin mu, ki wọn de ọhun tan ko di owo nabi ko ṣẹṣẹ bẹrẹ.

Ṣugbọn pẹlu gbogbo igbiyanju ajọ to n gbogun ti iwa yii, iwa naa ṣi n tẹsiwaju ni.

Ọkan lara rẹ ti BBC ṣẹṣẹ tu idi rẹ sita yii tun mu iyalẹnu dani pupọ, nitori awọn obinrin tọrọ naa kan ko ṣiṣẹ nabi lasan, wọn tun n foju wina nnkan ẹgbin bii ki wọn ṣe igbọnsẹ si wọn lara, wọn si le ni ki wọn maa ko igbọnsẹ naa jẹ pẹlu.

Koda, meji ninu awọn ọmọbinrin to ti orilẹede Uganda lọ ṣiṣẹ nabi lọdọ ni Dubai ni wọn fi ẹmi wọn di iṣẹ ti wọn gba.

Bẹẹ, abanitaja nilee itaja igbalode ni wọn sọ fun wọn pe wọn n lọ ṣe ti wọn fi gba Dubai lọ.

Ẹni to wa nidii okoowo nabi yii ni a mọ si Charles Mwesigwa, awakọ ni niluu London tẹlẹ, ko too pada di olokowo iṣẹ aṣẹwo ṣiṣe ni Dubai.

Báwo ni àṣírí ṣe tú sí BBC lọ́wọ́?

Lẹyin awọn iroyin to n lọ labẹnu, pe Charles Mwesigwa n fi awọn obinrin ṣe owo nabi, o si n gba owo gọbọ lorii wọn, BBC lo ọtẹlẹmuyẹ akọroyin abẹnu kan lati wọle si i lara.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Charles Mwesigwa, ṣalaye fun akọroyin naa pe ilu London loun ti n ṣiṣẹ awakọ tẹlẹ, ṣugbọn nipa ti awọn obinrin yii, oun maa n diidi patẹ ariya fun awọn eeyan nla ti wọn jẹ ọkunrin ni.

O ni awọn olowo to n fowo ṣe faaji loun maa n tori wọn da owanbẹ silẹ, oun yoo si ba wọn wa awọn obinrin to ṣetan lati ba wọn ṣere, owo toun maa n gba fun eyi si bẹrẹ lati ẹgbẹrun kan dọla $1,000 (£740).

O ni bi awọn ọlọmọbinrin naa ba wọ agbo ariya naa tan, ko sohun ti wọn ko le ṣe lati tẹ awọn baba alaanu naa lọrun.

Charles ni boun tilẹ jẹ tete olowo gọbọi, oun yoo tun maa ṣiṣẹ olobinrinde yii lọ ni, oun ko le fiṣẹ naa silẹ.

Iru ode owanbẹ ti Charles ṣalaye ẹ pe oun n da silẹ yii ni wọn n pe ni Dubaiportypotty.

Ibalopọ to yatọ gedegbe si ti ọmọluabi ni a gbọ pe o maa n waye nibẹ, eeyan to le ni 450 million lo ti wo o loju opo Tiktok.

Lara iru rẹ naa si ni pe awọn ọkunrin yoo ṣe igbọnsẹ, wọn si le ni ki obinrin to ba ko si wọn lọwọ maa ko o jẹ.

Bo ṣe n ko o jẹ naa ni wọn yoo maa ya aworan rẹ, wọn yoo maa ka a silẹ, wọn yoo si maa fi ṣe yẹyẹ.

Yatọ si Charles to n ṣagbatẹru eyi, awọn obinrin kan naa wa ti wọn jẹ iya isalẹ, awọn ni wọn n ṣe agbodegba fun awakọ tẹlẹ naa, wọn jọ n ṣiṣẹ pọ ni.

Ta a ló fìdí èyí múlẹ̀?

Troy to n ba Charles Mwesigwa ṣiṣe tẹlẹ ree, o de fila dudu, o fi ami kan siwaju ori rẹ. Troy fi yẹti seti osi rẹ, o ni irungbọn to pọ.
Àkọlé àwòrán, Troy

Iwadii abẹnu BBC lori aṣiri yii gbe wa de ọdọ awọn ọdọmọbinrin orilẹede Uganda, wọn fi ye wa pe ohun tawọn n koju buru ju bẹẹ lọ.

Awọn ọdọbinrin naa ṣalaye pe ki i ṣe pe awọn fẹ di aṣẹwo labẹ Mwesigwa. Wọn ni ile itaja ati otẹẹli ni wọn sọ fawọn pe awọn yoo ti ṣiṣẹ, nigba tawọn debẹ tan lo di aapọn.

Ọmọbinrin kan, Mia, ti a fi orukọ rẹ gan-an bo o laṣiiri, ṣo fun BBC pe ẹnikan wa lara awọn onibaara Mwesigwa, to jẹ ohun to maa n beere fun ni pe oun fẹẹ ṣe igbọnsẹ si ara awọn obinrin ti wọn ba gbe fun un.

BBC beere eyi lọwọ Mwesigwa, ṣugbọn o ni ko sohun to jọ bẹẹ.

O ni oun kan maa n ba awọn ọmọbinrin naa wa ile ti wọn yoo maa gbe ni Dubai ni, ati pe wọn maa n tẹle oun lọ si ode ariya nitori awọn eeyan nla toun maa n wa si pati oun.

Bakan naa ni ọkunrin kan, Troy, to n ṣiṣẹ bii aṣoju fun Charles nigba kan, ṣalaye pe ọga ou maa n sanwo fun awọn aṣobode nilee faaji kiri, ki wọn le jẹ ki awọn obinrin rẹ wọle, ki wọn si ni ibalopọ.

"Mo ti gbọ nipa oriṣiriṣi ibalopọ ti mi o ri ri laye mi nibẹ. Awọn ọmọbinrin yẹn ko ribi kankan sa lọ. Bi wọn ṣe n ba awọn agbabọọlu sun ni wọn n ṣe fun awọn olorin ati awọn aarẹ orilẹede."

Troy lo sọ bẹẹ.

Obìnrin méjì pàdé ikú òjijì, wọ́n ní wọ́n jábọ́ lórí ilé ńlá ni

Monic Karungi ninu aworan to ya loke ile ti wọn lo ti jabọ, nigba to ku ọjọ mẹrin ti yoo jade laye lo ya aworan yii. Ọmọbinrin pupa ni, o de wiigi dudu.

Oríṣun àwòrán, Instagram

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Monic Karungi

Ninu iwadii lati ri i pe ọmọbinrin meji lo pade iku ojiji nipasẹ iṣẹ aṣẹwo ti wọn n ṣe lọdọ Mwesigwa.

Ori aja ile nla to ga gogoro ni a gbọ pe awọn ọmọbinrin naa ti jabọ ti wọn si ku. Monic Karungi ati Kayla Birungi lati Uganda ni awọn obinrin to pade iku ojiji naa.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ni wọn pa ara wọn ni, awọn ẹbi ati ọrẹ wọn sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ, ati pe o yẹ ki ọlọpaa tọpinpin iku naa gidi.

Ni ti Monic Karungi, nigba to de lati Iwọ-Oorun Uganda si Dubia, awọn obinrin to pọ gan-an lo ba nibẹ ti wọn ni wọn yoo jọ maa gbe pọ, wọn yoo jọ maa ṣiṣẹ fun Charles Mwesigwa.

Ọkan lara awọn ti Monic ba gbele,( a maa pe orukọ ẹ ni Keira fun aabo),ṣo fun BBC pe oun ati Monic jọ gbe ni 2022 ni.

"Bii ọja ni ile Mwesigwa, o to aadọta ọmọbirin to wa nibẹ. Inu Monic ko dun, nitori ki i ṣe ohun to ro lo ba nigba to de."

Keira lo ṣalaye bẹẹ fun wa.Ile itaja ni Monicro pe oun yoo ti ṣiṣẹ, gẹgẹ bi ẹgbọn rẹ, Rita, naa ṣe tun ṣalaye fun wa.

Ẹnikan to tun fidi aṣiri yii mulẹ fun wa siwaju ni Mia, oun naa si mọ Monic daadaa, o ni:

"Nigba ti mo sọ fun Ọgbẹni Mwesigwa pe mo fẹẹ pada sile, o bẹre si i ba mi ja.

"O sọ fun mi pe mo ti n jẹ oun ni gbese £2,000 ($2,711). Laaarin ọsẹ meji pere, owo naa ti le si i ni ilọpo meji to ni mo jẹ.

"Owo tikẹẹti, owo fisa, owo ibi ti o n sun, iyẹn tumọ si pe o gbọdọ ṣiṣẹ daadaa. O gbọdọ ṣiṣẹ karakara, ko maa bẹ awọn ọkunrin lati ba ọ sun."

Mia lo sọ iriri rẹ bẹẹ.

O ni Europe ni pupọ awọn to n ba awọn lo pọ ti wa, wọn si fẹran ki wọn maa beere ohun ti ko tọ lọwọ obinrin.

"Ọkan wa ninu wọn, o maa n ṣegbọnsẹ si obirin lara ni, a ni ki wọn ko o jẹ. "

Iru awọn ohun ti ko ba ọkan rẹ, ti ko si dun mọ awọn ọmọbinrin to di oloogbe naa han si wọn, ṣugbọn nigba ti wọn di oloogbe lojiji, ori ilẹ ni wọn ni wọn ti jabọ.

Mia sọ fun wa pe Monic ko fẹẹ ṣiṣẹ nabi ti wọn gbe le e lọwọ, ọpọ igba si ni oun ati Chales maa n ja lori eyi.

O ni Monic kuro ninu ile naa nigba to ri iṣẹ miran to daa lati maa ṣe, yatọ si ibalopọ ọpọ ọkunrin ni gbogbo igba.

Ko pẹ sigba naa ni wọn ni Monic jabọ lati ori ila alaja pupọ kan ni Al Barsha, ṣaaju iku rẹ lo si fi fọto kan sita lati ori oke ile naa, eyi to ya lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin ọdun 2022.

Ọjọ kẹrin lẹyin fọto naa ni iku de. Oṣu mẹrin pere ni Monic lo ni Dubai ko too dagbere faye.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa sọ pe awọn ṣe iwadii iku naa, wọn ni awọn ba oogun oloro ati ọti lile ni yara ti Monic wa, ko si sẹni kankan lọdọ rẹ nigba to jabọ, apa ọwọ rẹ nikan lo han lara irin ile to duro si. (Balcony).

Ko si ẹri to tọka ohun to pa Monic, wọn kan wulẹ gba iwe iku rẹ ni Dubai, wọn si fi oku rẹ ranṣẹ si Uganda ni.

Wọn ko tilẹ ri oku Kayla Birungi fi ranṣẹ silẹ ni tirẹ, wọn sin in si itẹku awọn ajoji ti ko lẹni kan ni Dubai ni. Al Qusais ni wọn n pe ibẹ.

Ohun ti wọn sọ nipa iku tirẹ naa si ni pe o jabọ lati ori ile alaja rẹpẹtẹ ni 2021.

Gbogbo nnkan wọnyi ni BBC beere alaye nipa rẹ lọwọ ọlọpaa, ṣugbọn wọn ko fesi.

'A sanwó fún ọ láti fipá bá ọ lò pọ̀, tọ̀ sí ọ lójú, lù ọ́'

Ọmọbinrin kan to tun fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun BBC ni a pe ni Lexi, o ṣalaye nipa Porta Potty, ode buruku ti wọn ti n ṣe obinrin niṣekuṣe.

O ni:

" Onibaara kan sọ fun mi pe, a san 15,000 Arab Emirates Dirham fun ẹ ($4,084, £3,013) lati jumọ ba ọ lo pọ, ka tọ si ọ loju, ka lu ọ, ka si fi 5,000 ($1,361, £1,004) kun owo naa fun ọ bi o ba le ko igbọnsẹ jẹ, ti a si ya aworan rẹ silẹ bi o ṣe n jẹ ẹ."

Lexi ni boun ba loun ko gba, o jọ pe o maa n jẹ ki ori wọn tanna silẹ ni.

O ni wọn fẹran lati maa ri i pe eeyan n sunkun, o n sa kiri, o si maa n wu wọn ki ẹni naa jẹ eeyan dudu.

Nigba to n fesi si eyi, Charles Mwesigwa sọ pe, faaji loun n ṣe ni toun, oun ti lo to ọdun mẹẹẹdọgbọn ni Dubai.

"Emi ni mo ni Dubai, ko si bi ẹ ṣe le fi ẹjọ mi sun, emi ni ẹmbasi, ẹmbasi, ẹmbasi ni mi"

Bi o ba ni afikun kankan lori iṣẹ iwadii yii, jọwọ kan si [email protected]