Njẹ́ o mọ̀ pé Ethiopia ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ sí ọdún 2018 ni? Àwọn àwòrán láti ibi ọdún tuntun nàá rèé

Awọn ero, lara eyi ti obinrin kan to wọ aṣọ funfun, wa, to si n lu ilu ti wọn kun ni ọda, si orin ọdun tuntun ni ile ijọsin St Raguel niluu Addis Ababa, ni Ethiopia - Ọjọbọ ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan an, 2025.

Oríṣun àwòrán, Luis Tato/AFP/Getty Images

    • Author, Amensisa Ifa
    • Role, BBC Africa
    • Reporting from, Addis Ababa
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Bí a ṣe ń ṣe nílẹ̀ wa, èèwọ̀ ni, nílẹ̀ ibòmíràn.

Orílẹ̀ èdè Ethiopia ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ sí ọdún tuntun, 2018 ni.

Ethiopia ní kajọ́kaṣù tirẹ̀ èyí tó fi ọdún méje wà lẹ́yìn ti ọdún òyìnbó tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀èdè àgbáyé n lò.

Ọjọ́ Kinni, oṣù Ṣẹrẹ, ni spọ̀ orílẹ̀èdè àgbáyé má ṣe ayẹyẹ ọdún tuntun, àmọ́ ní Ethiopia, ọjọ́ kọkànlá, oṣù Kẹsàn án, ni ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun ti wọn.

Kíni ìdí tó fi jẹ́ bẹ̀ẹ́, àti pé irú ayẹyẹ wo ni wọ́n má n ṣe níbi ọdún tuntun nàá?

Obìnrin tó kó igi dání ń ra òdòdó alọ́wọ̀ èsúrú lọ́wọ́ ẹni tó ń tà á ní Addis Ababa, Ethiopia lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kẹsàn-án 2025

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa/BBC

Kìí ṣe èyí nìkan, oṣù mẹ́tàlá ló tún wà nínú kàlẹ́ndà Ethiopia, dípò méjìlá.

Ìdí ni pé, wan n ṣe òǹkà ọdún ìbí Jesu Kristi lọ́nà tó yàtọ̀. Èyí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ìjọ Aguda ṣe àtúnṣe sí òǹkà rẹ̀ ní ọdún 500AD, àmọ́ Ethiopia ṣì n lo òǹkà ìjọ ìgbàanì.

Àwọn òdòdó "adey ababa" wà lára ohun tí wọ́n fi máa ń ṣe àjọyọ̀ ọdún tuntun náà tí wọ́n sì máa ń hù ní ìlú Addis Ababa.

Ìyàtọ̀ ọdún méje tó wà láàárín kajọ́kaṣù òyìnbó àti ti Ethiopia kò ṣẹ̀yìn pé bí wọ́n ṣe ń ka ìbí Jésù yàtọ̀ ní Ethiopia. Nígbà tí ìjọ Aguda ṣe àtúnṣe sí kajọ́kaṣù wọn ní ọdún 500AD, àwọn ilé ìjọsìn ní Ethiopia kò ṣe bẹ́ẹ̀.

Àwọn ọlọ́jà tó ń ta igi àti òdòdó aláwọ̀ èsúrú wà ní ọjà ní Addis Ababa, Ethiopia

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa/BBC

Àmọ́ ayẹyẹ ọdún tuntun náà tí wọ́n ń pè ní Enkutatash kò ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ilé ìjọsìn kankan, tó sì jẹ́ pé gbogbo àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè náà ni wọ́n jọ máa ń ṣe àjọyọ̀. Gbogbo àwọn ọlọ́jà ní Addis Ababa ni wọ́n máa ń kórajọ láti ta adey ababa àti ewéko tútù.

Ọ̀pọ̀ èrò ní ọjà ní Addis Ababa. Àwọn kan mú adìẹ dání àwọn míì kó ewéko tútù dání.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa/BBC

Níṣe ni gbogbo àwọn ilé ìtajà ń rọ́ kẹ̀kẹ̀, tó fi mọ́ ọjà Addisu Gebeya, ní alẹ́ ọjọ́ ọdún ku ọ̀la pẹ̀lú bí òjò ṣe ń rọ̀, táwọn èèyàn sì ń gbáradì fún ọdún tuntun.

Ọlọ́jà kan tó wọ ìbọ̀wọ́ tó sì ń fẹyín láti ya àwòrán, ó mú adìẹ kan dání sí ọwọ́ rẹ̀ kejì.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa/BBC

Tamirat Dejene, ẹni ọdún mọ́kàndínlógún wá sí Addis Ababa láti ìlú Chanco láti wá ta adìẹ.

Ó sọ fún BBC pé, iṣẹ́ adìẹ sínsìn ni òun yàn láàyò, nítorí pé òun ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sè jùlọ láti fi se ọbẹ̀ tí wọ́n ń pè ní "doro wat".

Àwọn àgbò mẹ́ta tí wọ́n so okùn aláwọ̀ ewé àti pupa mọ́ lọ́rùn ní alẹ́ ọdún tuntun ku ọ̀la ní Addis Ababa, Ethiopia.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa/BBC

Fún àwọn tó bá tún ní owó lọ́wọ́, ẹran àgbò jẹ́ ohun tí wọ́n máa ń jẹ.

Àwọn ọlọ́jà àtàwọn oníbàárà yí àwọn adìẹ tó wà nínú àgò ká nínú ọjà kan ní Addis Ababa, Ethiopia.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa/BBC

Àwọn ẹbí máa ń pe ọ̀rẹ́ jọ láti darapọ̀ mọ́ wọn láti wá báwọn jẹun ní àyájọ́ Enkutatash, yálà oúnjẹ ọ̀sán tàbí ti alẹ́, ó sì lè jẹ́ méjéèjì nígbà mìíràn.

Àwọn míì máa ń pa akọ màálù nígbà míì.

Súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ ní alẹ́ ọdún ku ọ̀la ní Addis Ababa. Àwọn iná àtàwọn àwòrán tó ń ṣe àpẹẹrẹ ọdún tuntun jẹ́ rírí.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa/BBC

Ní ọdún ku ọ̀la ni àwọn èèyàn máa ń sáré láti ra nǹkan sílé, tí wọ́n sì máa mórílé agbo eré àríyá lẹ́yìn náà.

Àwọn eléré ń kọrin láti gbàlejò ọdún tuntun ní ibìkan ní Addis Ababa. Àwọn iná tó ń ṣe àfihàn ọdún tuntun, ọdún 2018 ń hàn lẹ́yìn wọn.

Oríṣun àwòrán, Amensisa Ifa/BBC

Àwọn ọmọdébìnrin mẹ́wàá tí wọ́n wọ aṣọ tọ ní òdòdó àwọ̀ èsúrú lára, wọ́n ń kọrin, wọ́n ń lùlù fún àwọn èèyàn tó ń kọjá ní Addis Ababa ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹsàn-án.

Oríṣun àwòrán, Luis Tato/AFP/Getty Images

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ ọdún tuntun, wọ́n ń kọrin ìbílẹ̀ kan tí wọ́n ń pè ní "Abebayehosh" káàkiri gbogbo ìlú. Àwọn ọmọdébìnrin ló máa ń kọrin yìí fáwọn aráàlú tó bá ń kọjá, tí wọ́n sì máa ń lọ láti ojúlé sí ojúlé nígbà míì.

Àwọn olọ́jà méjì tí wọ́n ń ta agbòòrùn ń ṣọ oníbàárà ní ẹsẹ̀ títì Twní Addis Ababa, Ethiopia.

Oríṣun àwòrán, Luis Tato/AFP/Getty Images

Orin yìí ní ìsopọ̀ mọ́ àṣà Ethiopia tó sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa ọdún tuntun.

Àlùfáà ìjọ kan ń fi tùràrí àdúrà ṣe àdúrà fún àwọn olùjọ́sìn tí wọ́n wọ aṣọ funfun àti ìbora tí wọ́n tẹ̀ síwájú rẹ̀ ní ilé ìjọsìn Entoto St Raguel Church ní Addis Ababa, Ethiopia

Oríṣun àwòrán, Luis Tato/AFP/Getty Images

Àlùfáà ìjọ darapọ̀ mọ́ àwọn ìjọ ní ilé ìjọsìn Entoto St Raguel Church ní Addis Ababa, Ethiopia láti gba àdúrà fún ọdún tuntun.

Àwọn obìnrin ilé ìjọsìn márùn-ún kọ ẹ̀yìn sí ẹ̀rọ ayàwòrán tí wọ́n sì ń kọrin ìjọsìn ní ilé ìjọsin Entoto St Raguel Church ní Addis Ababa, Ethiopia lọ́jọ́ ọdún tuntun.

Oríṣun àwòrán, Luis Tato/AFP/Getty Images

Àwọn èèyàn Ethiopia kò ní ìdààmú kankan tí wọ́n bá fẹ́ lo kajọ́kaṣù ti wọn tàbí ti òyìnbó.

Tí wọ́n bá ń sọ èdè wọn, kajọ́kaṣù wọn ni wọ́n máa ń lò tí wọ́n sì máa ń só pé ọdún 2018 ni àwọn wà ṣùgbọ́n tí wọ́n máa ń bọ́ sí ọdún 2025 tí wọ́n bá ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Àwọn díákónì àti àlùfàá ìjọ kan yí ọkùnrin kan tó ń lùlù láti fi ṣyẹyẹ ọdún tuntun ká ní ilé ìjọsin at Entoto St Raguel Church in Addis Ababa, Ethiopia

Oríṣun àwòrán, Luis Tato/AFP/Getty Images

Ohun kan tó tún ya kajọ́kaṣù Ethiopia sọ́tọ̀ ni pé oṣù mẹ́tàlá ló ní. Oṣù méjìlá ní ọgbọ̀n ọjọ́ nígbà tí oṣù kẹtàlá ní ọjọ́ nárùn-ún péré.

Àsìkò ọdún tuntun náà tún máa ń túmọ́ sí ìparí àsìkò òjò.