Kí ló fa gbas-gbos láàárín Sowore, DSS àti Tinubu tí wọ́n fi ń wọ́ ara wọn lọ ilé-ẹjọ́?

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria, DSS, ti pe ajafẹtọọmọniyan to tun jẹ akọroyin, Omoyẹle Sowore ati ileeṣẹ ikansiraẹni lori ayelujara, X lẹjọ lori ẹsun marun un ọtọọtọ.
DSS pe ẹjọ naa niwaju ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja lẹyin ti Sowore kọ lati yọ ọrọ ti wọn ni o sọ lodi si Aarẹ Bola Tinubu loju opo ọhun kuro.
M.B. Abubakar, lati ọọfisi ileeṣẹ to n ri si eto idajọ Naijiria lo pe ẹjọ naa lorukọ ajọ DSS ati ijọba apapọ.
Ẹsun akọkọ sọ pe Sowore lo oju opo X rẹ lati lati pe Aarẹ Tinubu ni ọdaran lasiko to lọ si Brazil to si sọ pe ko si iwa ajẹbanu ni Naijiria mọ.
Iwe ẹjọ naa ni "O mọ pe ohun ti o sọ kii ṣe ododo amọ o mọọmọ kọ ọrọ naa lati da rogbodiyan silẹ ni orilẹede, paapaa laarin awọn ti ero wọn yatọ nipa iru ẹni ti Aarẹ n ṣe.
"Fun idi eyii, o ti ṣẹ ti ofin labẹ abala 24 (1) (b) ofin idunkokomọni lori ayelujara ti wọn ṣe atunṣe rẹ lọdun 2024."
Ẹsun keji ti wọn fi kan Sowore ni pe o kọ ọrọ abuku si Aarẹ loju opo Facebook lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025 yii.
Ẹsun kẹta ni pe Sowore pe Aarẹ Tinubu ni "ọdaran" ati pe o fẹsun irọ pipa kan Aarẹ pe o ṣeke lasiko to ni ko si iwa ajẹbanu mọ ni Naijiria lorilẹede Brazil.

Oríṣun àwòrán, DSS
Bi gbas-gbos ṣe bẹrẹ laarin Sowore ati DSS
Ọrọ naa bẹrẹ nigba ti Aarẹ Bola Tinibu lọ si orileẹde Brazil fun ipade kan pẹlu Aarẹ orilẹede naa.
Nibi ipade ọhun ni Aarẹ Tinubu ti sọ pe ko si iwa ajẹbanu ni Naijiria mọ bii ti atijọ, ati pe ijọba ilẹ naa le wa si Naijiria lati ṣowo.
Amọ lẹyin ọrọ Tinubu naa ni Sowore sọ loju opo X ati Facebook rẹ pe irọ ni Tinubu n pa pe ko si iwa ajẹbanu ni Naijiria mọ.
Sowore sọ lọjọ naa pe awọn adari ni Naijiria ṣi n wu iwa ajẹbanu, koda awọn eeyan ṣi n ko owo ilu si apo ara wọn labẹ ijọba Tinubu, nitori naa irọ pọnbele ni ọrọ ti Aarẹ sọ ni Brazil.
Ko pẹ si asiko yii ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS kọ iwe si ileeṣẹ X pe ki wọn yọ ọrọ ti Sowore kọ kuro loju oppo wọn labẹ asia pe o tabuku Aarẹ Naijiria.
X naa tun kọ iwe si Sowore nipa ẹbẹ DSS amọ Sowore fun X lesi pe oun ko ni yọ ọrọ naa nitori ootọ ni oun sọ, ẹtọ oun labẹ ofin si ni lati sọ ootọ ọrọ bo tilẹ jẹ o le ma dun mọ ijọba orilẹede oun ninu.
Laarin ọdọ diẹ asiko yii ni agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga kọ iwe si Sowore pe ko yọ ọrọ naa kuro loju opo rẹ, gẹgẹ bi Sowore ṣe sọ, amọ akọroyin naa ni oun ko ni ṣe oun ti wọn n fẹ.
Ẹwẹ, ṣaaju ni DSS ti kọkọ kọwe si Sowore pe ko yọ ọrọ naa amọ Sowore ni oun ko ni ṣe bẹẹ niori ẹtọ oun ni labẹ ofin lati kọ ohunkohun to ba wa lọkan oun gẹgẹ bii ọmọ Naijiria.
Sowore pe ẹjọ tirẹ tako DSS

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Wayi o, Sowore ti pe ẹjọ tirẹ tako ajọ DSS lẹyin wakati diẹ ti wọn gbe ọrọ rẹ lọ ile ẹjọ.
Agbẹjọro Sowore, Tope Temokun, bẹ ile ẹjọ pe ko ma gba DSS laaye lati kan an nipa fun awọn ileeṣẹ X and Meta pe ki wọn yọ ọrọ ti Sowore sọ kuro loju opo wọn, paapaa eyii to ti pe Aarẹ Tinubu ni ọdaran.
Temokun ni Sowore pe ẹjọ lati tako ẹjọ ti DSS lori bi wọn ṣe fẹ fi agadagodo di ẹnu oun lori ayelujara.
Agbẹjọrọ naa sọ pe araalu lẹtọ labẹ ofin ni Naijiria lati sọ ọrọ to ba wu wọn lori ayelujara labẹ abala 39 ofin orilẹede Naijiria ti wọn kọ lọdun 1999.
O ni ofin naa fun araalu lẹtọ lati sọ ohun to ba wu u labẹ ijọba awarawa.
O ni "Ko si ileeṣẹ eto abo kankan, bo ṣe wu ki wọn lagbara to, to lẹtọọ lati yọ ọrọ naa kuro lori ayelujara.
Lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, ile ẹjọ ko tii gbe ẹjọ mejeji siwaju adajọ kankan.















