Kíni ìwé ẹ̀rí TRCN táwọn olùkọ́ gbọdọ̀ ní kí ilé-ẹ̀kọ́ wọn tó lè ṣe ìdánwò WAEC àti NECO?

Olukọ obinrin mu ẹgbẹ lọwọ pẹlu awọn akẹkọọ ni iwaju rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ijọba apapọ tun ti kilọ wi pe idanwo aṣekagba nile ẹkọ girama, WASSCE, NABTEB, NECO ati NBIAS ko ni waye mọ lawọn ile ẹkọ tawọn olukọ wọn ko ba ni iwe ẹri ajọ TRCN (Teachers Registration Council of Nigeria) lọwọ.

Ọrọ yii jẹyọ ninu atẹjade kan ti minisita eto ẹkọ ni Naijiria, Ọmọwe Tunji Alausa, fi ṣọwọ si akọwe agba ajọ TRCN lọsẹ to kọja.

Ọmọwe Alausa sọ ninu atẹjade naa wi pe igbesẹ yii wa ni ibamu pẹlu ipinnu ijọba lati jẹ ki eto ẹkọ fẹsẹ mulẹ daadaa ni Naijiria.

Minisita fidi rẹ mulẹ pe lati ọdun 2027, ile ẹkọ tawọn olukọ rẹ ko ba ti ni iwe ẹri TRCN ko ni le ṣe idanwo aṣekagba WAEC mọ.

''Lati oṣu Kẹta ọdun 2027, gbogbo olukọ ti ko ba forukọ silẹ tabi ni iwe ẹri ajọ TRCN lọwọ ko ni kopa kankan ninu idanwo WASSE tabi NECO,'' Alausa lo sọ bẹẹ.

Minisita tun sọ fawọn ijọba ipinlẹ kaakiri Naijiria lati tẹle ilana tuntun yii lori eto ẹkọ.

Ọmọwe Alausa tun rọ awọn ijọba ipinlẹ lati bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lori ilana eto ẹkọ tuntun yii bayii fawọn olukọ nile ẹkọ ijọba ati ti aladani ki ọdun 2027 to de.

Minisita tun rọ awọn olukọ ti wọn ko kọ nipa kikọ awọn akẹkọọ lati ilẹ ṣugbọn ti wọn ti ṣiṣẹ olukọ fun ọdun kan lati lọ forukọ silẹ pẹlu ajọ NTI (National Teachers Institute).

Ṣaaju ni minisita eto ẹkọ ti sọ pe gbogbo awọn olukọ ti wọn o koju oṣunwọn lo yẹ ki ijọba da duro lẹnu iṣẹ, ki eto ẹkọ Naijiria le fẹsẹ mulẹ daadaa.

Ki ni ajọ TRCN ti ijọba ni kawọn olukọ ni iwe ẹri rẹ da lori?

Minisita eto ẹkọ, Ọmọwe Tunji Alausa, ti sọ ṣaaju pe ijọba gbe ajọ TRCN kalẹ lati jẹ ki eto ẹkọ fẹsẹ mulẹ daadaa lorilẹede Naijiria.

Alausa sọ pe ko si orilẹede to le gunke agba kọja ohun ti awọn olukọ ibẹ ba mọ.

O ni oju opo tuntun yii ki i ṣe fun imọ ẹrọ nikan, ṣugbọn fun awọn olukọ paapaa lati ba igba yi, ki wọn si dagba ninu imọ fun ọjọ ọla.

Gẹgẹ bi o ṣe wi, oju opo TRCN yii ni wọn yoo ti maa fi orukọ silẹ nirọrun, gba iwe aṣẹ ti wọn yoo si tun ti maa ṣe isọdọtun iwe aṣẹ naa kaakiri Naijiria.

"Yoo tun fun wọn ni anfaani nipa eto idanwo to ba yẹ ki wọn ṣe, yoo ṣe igbelewọn itẹsiwaju awọn tiṣa pẹlu.

"Ohun to da le lori ni ni jijẹ akọṣẹmọṣẹ tiṣa, nini imọ ẹrọ igbalode, ṣiṣe iṣiro iṣẹ wọn, ṣiṣe deede ati biba awọn akẹgbẹ wọn lagbaaye dọgba,'' Ọmọwe lo sọ bẹẹ.

''Ijọba ṣe agbekalẹ ajọ TRCN lati da aabo bo awọn ọmọ wa''

Bakan naa ni Minisita eto ẹkọ ṣalaye nipa eto ẹkọ to pọn dandan kan ti wọn fẹẹ bẹrẹ fun awọn olukọ.

Alausa sọ pe idanilẹkọọ naa jẹ dandan fun awọn tiṣa, nitori bi wọn yoo ṣe maa huwa lai kọja ohun ti ofin wi lo wa fun un.

O fi kun un pe tiṣa kankan ti ko ba gba idanilẹkọọ naa ko ni i ri iṣẹ olukọ gba nileewe ijọba ati ti aladaani mọ .

Ayẹwo finni-finni nipa ohun ti oluko naa n gbe bọ lati ibi to ti n ṣiṣẹ tẹlẹ yoo tun waye pẹlu, gẹgẹ bo ṣe sọ.

O fi kun un pe awọn ileewe aladaani naa gbọdọ maa yẹ akọsilẹ olukọ wọ, ṣe o wa ni ibamu pẹlu ofin tuntun TRCN.

"Eyi ki i ṣe ifiyajẹni, idaabobo ni. O n waye lati da aabo bo awọn ọmọ wa, ki ẹkọ to yẹ ki wọn gba nileewe ma si ṣe fo wọn ru"

Bẹẹ ni Alausa ṣalaye.

"Gbogbo obi lo lanfaani lati wadii bo ya olukọ to n kọ ọmọ wọn forukọ silẹ pẹlu ajọ TRCN"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ tirẹ, Alabojuto Teachers Registration Council of Nigeria (TRCN), Ọmọwe Ronke Soyombo, sọ pe oju opo tuntun yii yoo ran akọsilẹ iye olukọ lọwọ.

Soyombo ni yoo tun fopin si iṣoro ọdun gbọọrọ ti awọn olukọ maa n koju ki wọn too ri iwe ẹri wọn gba.

"Pẹlu oju opo yii, awọn tiṣa kaakiri Naijiria le fi orukọ silẹ nitọrun, wọn le yẹ esi idanwo wọn wo ki wọn tun tẹ ẹ jade sinu iwe lai tiẹ daamu rara,'' Ọmọwe Soyombo lo ṣalaye bẹẹ.

O ni TRCN ti n ṣiṣẹ lorii bi esi idanwo ti i ṣe Professional Qualifying Examination (PQE), yoo ṣe maa jade laaaarin ọsẹ kan pere, ti awọn tiṣa yoo si tete maa ri iwe ẹri wọn gba lẹsẹkẹsẹ.

"Gbogbo obi lo ni anfaani lati wadi bayii, boya tiṣa to fi orukọ silẹ lọdọ TRCN lo n kọ ọmọ wọn tabi bẹẹ kọ.

Nigba ti yoo ba fi di oṣu Kẹwaa, ajọ naa yoo ṣi oju opo Artificial Intelligence (AI) rẹ, bi Soyombo ṣe wi, eyi ti yoo ran iṣẹ awọn tiṣa lọwọ, ti awọn akẹkọọ naa yoo si gbadun ẹkọ bo ṣe sọ.

Olugbani-nimọran agba lati British High Commission, Ian Attfield, naa fi kun un pe ilana tuntun yii yoo ran akọsilẹ awọn tiṣa lọwọ, iwuri yoo ṣi wa fun wọn lati ṣe iṣẹ wọn.

"Tiṣa pọ loriṣiiriṣii— tiṣa agbegbe, awọn tiṣa to n kọmọ nilee ijọsin lati ọwọ ara wọn, ati awọn tiṣa ileewe olowo pọọku ti ọpọ wọn ko kunju oṣunwọn, eto tuntun yii tumọ si pe awọn naa gbọdọ darapọ, ki wọn si ri iwuri,'' Attfield lo sọ bẹẹ.

O fi da wọn loju pe ijọba UK, nipasẹ ọfiisi rẹ ti i ṣe Foreign, Commonwealth and Development Office, yoo maa tẹsiwaju ninu iranlọwọ to n ṣe fun atunto eto ẹkọ Naijria.