Èèyàn meji dèrò ẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn pé wọ́n fẹ́ẹ́ fi ẹyẹ àjẹ́ pa ààrẹ

Oríṣun àwòrán, Others
Ile ẹjọ kan lorilẹede Zambia ti ju ọkunrin meji kan si ẹwọn ọdun meji, fun pe wọn jẹbi ẹsun igbiyanju lati fi agbara ajẹ ti wọn ni pa aarẹ orilẹeede naa, Hakainde Hichilema.
Awọn ọkunrin meji to gbadajọ ẹwọn naa ni Leonard Phiri, ọmọ orilẹede Zambia, ati Jasten Mabulesse Candunde toun jẹ ọmọ orilẹede Mozambique.
Oṣu Kejila ọdun to kọja ni wọn bẹrẹ igbẹjọ lori ẹsun ki eeyan ni ẹyẹ ajẹ ti wọn fi kan wọn, wọn si tun ba ọpọlọpọ oogun abẹnugọngọ lọwọ wọn ati ẹranko ọ̀gà kan to ṣi wa laaaye.
" Iwoye mi lori ọrọ yii ni pe awọn mejeeji yii ki i ṣe ọta aarẹ nikan, bi ko ṣe pe pe ọta gbogbo ọmọ Zambia ni wọn jẹ."
Adajọ Fine Mayambu to gbe idajọ naa kalẹ lo sọ bẹẹ.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ti wa lẹnu ẹjọ yii fun igba pipẹ, eyi ni igba akọkọ ti awọn eeyan jẹjọ nipa pe wọn fẹẹ fi agbara ajẹ pa aarẹ.
Kí ló ṣẹlẹ̀ ní kóòtù?

Oríṣun àwòrán, EPA.EFE/ REX/Shutterstock
Ninu ọrọ agbefọba lori ẹsun jijẹ ẹlẹyẹ yii, o ni ọmọ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ kan to n sa kiri lo ran Phiri ati Candunde to fẹẹ pa aarẹ lati gba ẹmi rẹ.
Bi awọn ti wọn gba idajọ ẹwọn naa si ti ṣalaye to, pe Babalawo lawọn, awọn n fi ohun ti wọn ba lowọ awọn ṣe iwosan ni, sibẹ, ile ẹjọ da wọn lẹbi labẹ ofin to de ẹyẹ ajẹ ni Zambia.
"Awọn mejeeji gba pe awọn ni oogun lọwọ, eyi to n jẹ Phiri yẹn tiẹ tun sọ pe boun ba fi iru ọga yẹn ṣe oogun tori eeyan, ẹni naa yoo ku laaarin ọjọ marun-un."
Adajọ Mayambu lo fi kun ọrọ rẹ bẹẹ.
Lọya ti awọn olujẹjọ gba, Agrippa Malando, tilẹ bẹbẹ pe ki kootu ṣiju aanu wo wọn nigba ti won ko tapa sofin ri, ṣugbọn Adajọ kọ ẹbẹ rẹ.
.
Adajọ Mayambu sọ pe ọpọ eeyan lo mọ pe ajẹ wa ni Zambia ati awọn ile Africa mi-in, bi ijọba ko tilẹ mọ ohun to n jẹ bẹẹ, ti sayẹnsi ko si fidi rẹ mulẹ.
Ọdun 1914 ni wọn ti ṣe ofin ajẹ ni Zambia
Gẹgẹ bi agbẹjọro kan, Dickson Jere, ṣe ṣalaye fun BBC, o ni ọdun1914 ni wọn ṣe ofin to de ki eeyan jẹ ajẹ ni Zambia, iyẹn lasiko ijọba amunisin.
O ni wọn ki i sabaa mu awọn eeyan lori ofin naa, tabi pe wọn lajẹẹ.
Amofin Dickson sọ pe iranlọwọ kan ti ofin naa ṣe ni pe o da aabo bo awọn iya agba ti wọn maa n foju ajẹ wo, ti wọn si maa n sọ wọn loko pa.
Bakan naa ni wọn gbe ofin yii kalẹ lati da aabo bo awujọ lọwọ awọn to maa n fi agbara naa halẹ mọ ẹlomiran ti ko ni.
Yatọ si ẹwọn ọdun meji ti wọn ju wọn si fun nini ẹyẹ ajẹ, awọn ọkunrin meji naa tun gba idajọ ẹwọn oṣu mẹfa fun nini oogun lọwọ.
Ṣugbọn bi ẹwọn naa yoo ṣe waye si asiko kan naa, ọdun meji ni yoo jẹ, wọn yoo ka a si pe wọn ti bẹrẹ rẹ lati ọdun 2024.
Aarẹ Hichilema ti wọn tori rẹ dero ẹwọn ti figba kan sọ ọ ri pe oun ko nigbagbọ ninu pe agbara ajẹ, ṣugbọn ko ti i wi nnkan kan lori ẹwọn ti awọn eeyan naa n lọ ti a fi pari iroyin yii.














