Ta ló ni $7m tí wọn kò mọ ẹni tó ní nínú ilé owó Providus Bank?

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti paṣẹ pe ki ijọba apapọ gbẹsẹle owo ti iye rẹ jẹ miliọnu meje dọla to wa ninu kolo ile ifowopamọ Providus, ti wọn ko mọ ẹni to ni i.
Ṣaaju ni ajọ EFCC ti kọkọ pe ẹjọ naa niwaju adajọ Emeka Nwite pe owo ọhun jẹ eyii ti ẹni kan ri ninu iwa ajẹbanu.
Agbẹjọro EFCC, Rotimi Oyedepo (SAN) ni ajọ naa ti ṣe akojọpọ gbogbo awọn iwe to yẹ nipa owo ọhun.
EFCC kede aṣẹ ile ẹjọ naa to sọ pe ki ẹnikẹni to ba ni eredi ti ijọba ko fi gbọdọ gbẹsẹle owo naa wa wi tẹnu wọn.
Wọn ni lati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025 yii, ko tii si ẹnikẹni to jade sita lati tako awọn.
Ẹwẹ, agbẹjọro kan, Gbenga Akande, yọju sile ẹjọ pe, oun fẹẹ ṣoju awọn eeyan kan to ni owo naa amọ o kọ lati darukọ wọn, bẹẹ ni ko fi ẹri kankan lelẹ niwaju adajọ nipa owo ọhun.
Lọjọ ti wọn sun ẹjọ naa si, Akande ko si nile ẹjọ ṣugbọn agbẹjọro mii, Darlington Ozurumba lo yọju bo tilẹ jẹ pe ko tako ebẹ EFCC.
Lẹyin naa ni Oyedepeo ni niwọn igba ti ẹnikẹni ko ti tako igbẹjọ awọn, ajọ naa n fẹ ki ijọba gbẹṣele owo ọhun yanyan.
Lẹyin to yẹ gbogbo ẹri to wa niwaju rẹ wo, adajọ Nwite fi ontẹ lu ẹbẹ EFCC.
Bi ọrọ owo naa ṣe jẹ
Ninu alaye EFCC, wọn ni iwadii awọn fi han pe laaarin ọjọ karundinlọgbọn si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ ni owo naa fi wa ni akata ẹka banki ọhun to wa ni Victoria Island, niluu Eko, ti wọn ko si san an si aka-n-ti ẹnikẹni.
Iwadii EFCC siwaju si fi han pe wọn ko gbe owo naa lorukọ ẹnikẹni amọ wọn gbe sinu kolo banki ọhun lai fi alaye tabi iwe kankan silẹ nipa ẹni to ni i.
Nigba ti EFCC fi ọrọ wa awọn oṣiṣe banki naa lenu wo, wọn sọ pe adari ileeṣẹ ti orukọ rẹ n jẹ Oceangate Engineering Oil and Gas Limited lo ni ki wọn gbe owo naa lọ sibẹ.
Nigba ti EFCC kan si alaṣẹ ileeṣẹ ọhun, o ni oun ko mọ nipa owo naa, amọ o sọ pe oun ya miliọnu meje dọla lọwọ banki naa.
Banki ọhun ko si fi to ijọba leti pe owo kan wọ akata oun ti oun ko mọ ẹni to ni i.















