Kí ni àwọn ohun tó lẹ́tọ̀ọ́ tó yẹ kí o mọ̀ nípa ẹ̀jẹ̀ ẹni tó o fẹ́ yàn ní olólùfẹ́?
Ọ̀rọ̀ ìfẹ́ bí àdánwò ni.
Tí ọfà bá èèyàn, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí bìkítà láti mọ irúfẹ́ àkóbá tí àìṣe àwọn nǹkan tó lẹ́tọ̀ọ́ nípa ẹni tí wọ́n fẹ́ gbé lọ́kọ tàbí láya.
Ọ̀pọ̀ ni kìí bìkítà láti ṣe àwọn àyẹ̀wò tó lẹ́tọ̀ọ́ tó fi mọ́ àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ láti mọ́ bóya àwọn le fẹ́ra nítorí ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ.
Àmọ́ ó pọn dandan láti àwọn nǹkankan nípa ẹni tí èèyàn bá fẹ́ yàn ní olólùfẹ́ kí ọjọ́ iwájú má ba à di ohun tí wọ́n yóò máa kọwọ́ àbámọ̀ sẹ́nu.
Èyí lọ mú BBC News Yorùbá kàn sí dókítà láti mọ àwọn ewu tó wà nínú ṣíṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ èyí tí àwọn olóyìnbó ń pè ní Genotype fún olólùfẹ́ méjì tó fẹ́ fẹ́ ara wọn.
Dókítà Ayodele Awojobi tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìlera ẹbí sọ fún BBC pé onírúurú ẹ̀jẹ̀ ló wà tí èèyàn sì gbọdọ̀ mọ èyí tó yẹ fún òun tí òun bá fẹ́ yan ọkọ tàbí aya.
Lára àwọn ẹ̀jẹ̀ tí dókítà Awojobi sọ pé ó wà ní AA, AS, AC, SS àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ó sọ pé irúfẹ́ ẹ̀jẹ̀ tí èèyàn bá ni yóò sọ èèyàn tí yóò fẹ́.



