Fídíò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń mu igbó, ọtí àti sìgá gbòde, ìjọba Eko bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Awọn akẹkọọ ti wọn wa lori ila nile ẹkọ wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Olumide Owaduge
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti bẹrẹ iwadii lori fidio kan to ṣafihan bi awọn akẹkọọ ile ẹkọ Excel College, to wa ni Ejigbo ti n mu ọti, mu siga ti wọn si n jo ninu ọgba ile ẹkọ naa.

Iroyin ni inu oṣu Kẹrin, ọdun 2025 yii ni iṣẹlẹ naa waye ninu yara to jẹ ti awọn ọkun nikan ni ọgba ile ẹkọ ọhun.

Amọ ọsẹ to kọja ni fidio naa tun pada bẹrẹ si n mi ori ayelujara titi, eyii to mu ki ọpọ obi ati araalu maa bu ẹnu atẹ lu fidio ọhun, ti wọn si n sọ pe ko si abojuto to yẹ ni ọpọ ile ẹkọ mọ bii ti atijọ.

Nigba to n sọrọ lori fidio ọhun, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olohundare Jimoh ti paṣẹ fun ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran, CID, to wa ni Panti lati gba iwadii naa lọwọ ẹka ileeṣẹ ọhun to wa ni Ejigbo.

Amọ agbẹnusọ ileeṣọ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Abimbola Adebisi ti sọ ninu atẹjade kan pe adari ile ẹkọ ọhun, to tun jẹ oludasilẹ rẹ, fidi rẹ mulẹ pe awọn akẹkọọ naa ti pari ẹkọ wọn nibẹ.

O ṣalaye pe ọlọpaa ke si ọkunrin adari ile ẹkọ naa lati wa wi tẹnu rẹ nipa bi ọrọ ṣe jẹ, akoko naa lo ni awọn afurasi ọhun ti kẹkọ jade.

Adebisi ni awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa n ran ọlọpaa lọwọ lori iwadii wọn, bẹẹ naa ni ọlọpaa ko fi ọrọ naa ṣere rara.

O ni gbogbo abajade iwadii awọn ni awọn yoo fi sita fun gbogbo aye lati mọ.

Lẹyin naa lo gba araalu nimọran lati maṣe dakẹ nibikibi ti wọn ba ti kofiri irufẹ iwa ibajẹ bẹẹ lọjọ iwaju.

Iwọnyii ni awọn ohun ti akẹkọọ ko gbọdọ ṣe lawọn ile ẹkọ nipinlẹ Eko

  • Akẹkọọ ko gbọdọ na akẹgbẹ rẹ
  • Akẹkọọko gbọdọ mu ohun ija oloro bii ibọn, ọbẹ, koboko ati bẹẹ lọ wa sinu ile ẹkọ.
  • Akẹkọọ ko gbọdọ mu awọn iwe tabi fidio aworan ibalopọ tabi ihoho wa sile ẹkọ
  • Akẹkọọ ko gbọdọ gbe redio kekere wa sile ẹkọ
  • Akẹkọọ ko gbọdọ dunkoko mọ akẹgbẹ rẹ paapaa ọkunrin si obinrin
  • Akẹkọọ ko gbọdọ fa igbo, mu siga tabi ọti ninu ọgba ile ẹkọ
  • Akẹkọọ ko gbọdọ ba ohun elo ile ẹkọ jẹ bii ko ya iyakuya si oju patako ikọwe atawọn ohun elo mii
  • Akẹkọo ko gbọdọ jale, eyii kan jiji dukia akẹgbẹ rẹ, dukia ile ẹkọ tabi ti awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa
  • Akẹkọọ ko gbọdọ maa pariwo lasiko ikẹkọọ tabi kọ eti ikun si aṣẹ olukọ
  • Akẹkọọ ko gbọdọ lo ẹrọ ilewọ lasiko ti ko bojumu paapaa lasiko ti ẹkọ ba n lọ lọwọ
  • Akẹkọọ ko gbọdọ ji iwe wo tabi gbeegun lasiko idanwo
  • Akẹkọọ ko gbọdọ gbalejo lasiko ti ẹkọ ba n lọ lọwọ lai kọkọ gba aṣẹ
  • Ko si aye fun akẹkọọ lati ṣe ayẹyẹ ninu ọgba ile ẹkọ lai kọkọ gba aṣẹ

Iwọnyii ni awọn ijiya to tọ si akẹkọọ to ba ṣe aṣemaṣe nipinlẹ Eko

Fun awọn ẹṣe keke bii ki akẹkọọ ma tete dele ẹkọ tabi ki o ma wọ aṣọ daadaa, ọrọ ni wọn maa ba iru wọn sọ ki wọn le yipada.

Fun akẹkọọ to ba mu ohun to lodi si ofin wa sile ẹkọ, niṣe lawọn alaṣẹ ile ẹkọ naa yoo gbẹsẹle irufẹ nnkan bẹẹ tabi ki wọn tun ni ki akẹkọọ ọhun lọ rọọkun nile.

Akẹkọọ to ba mu siga, igbo tabi ọti nile ẹkọ yoo ṣe odigboṣe si irufẹ ile ẹkọ bẹẹ ni.

Akẹkọo to ba mu aworan ihoho tabi ibalopọ wa sile ẹkọ; wọn yoo le kuro nile ẹkọ naa loju gbogbo awọn akẹgbẹ rẹ tabi ki wọn ni ko lọ rọọkun nile.

Akẹkọọ to ji iwe wo, gbeegun lasiko idanwo tabi joko fun ẹlomiran lasiko idanwo le foju wina ofin ijọba lẹyin ti wọn ba fa iwe idanwo rẹ ya tan.

Wayi o, eewọ ni ki olukọ fi ẹgba na akẹkọọ nipinlẹ Eko.

Irufẹ ijiya wo lo wa fun ile ẹkọ ti akẹkọọ rẹ ba lu awọn ofin yii?

Ile ẹkọ bẹẹ yoo N500,000 owo itanra fun ijọba.

Fun ile ẹkọ ti wọn ba n lo bii ibi ti wọn ti n ṣe amgomago idanwo 'miracle centre' ijọba yoo yọ irufẹ ile ẹkọ bẹẹ kuro lara awọn gbagede ti yoo maa gbalejo idanwo.

Ile ẹkọ to ba tapa si ofin ti ijọba gbe kalẹ le padanu iwe aṣẹ rẹ sọwọ ijọba ipinlẹ Eko, bẹẹ ni wọn le ti irufẹ ile ẹkọ bẹẹ pa.