Ẹ máà dá Obansajo lóhùn, Ó gbìyànjú sáà kẹta àmọ́ ó lulẹ̀ ni - Usman Bugaje

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọwe Usman Bugaje, aṣofin nigba kan ri ti tako ọrọ Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Olusegun Obasanjo to sọ pe oun ko gbiyanju lati du sa kẹta lasiko ijọba oun.
Ṣaaju ni Obasanjo ti kọkọ sọ pe irọ ni iroyin naa nibi eto kan ti Aarẹ tẹlẹ, Goodluck Jonathan ṣagbatẹru rẹ.
Obasanjo sọ nibi ipade naa pe oun ko nifẹ si ati ṣe saa kẹta, bi bẹẹ kọ, oun yoo jawe olubori ti oun ba gbiyanju rẹ.
O ni "Mi o kii ṣe omugọ, ti mo ba fẹ ṣe saa kẹta, mo mọ bi mo ṣe maa ṣe ti maa si bori.
"Ko si ọmọ Naijiria kankan boya o ti ku ni o tabi o ṣi wa laaye ti yoo sọ pe mo wa ba oun pe mo fẹ ṣe saa kẹta.
"Irọ ni Obasanjo pa, ohun gbogbo lo ṣe lati fikun saa rẹ"
Amọ nigba to n sọrọ lori ẹrọ amuhunmaworan Channels, Bugaje ni Obasanjo gbiyanju lati ṣe afikun saa rẹ lori oye amọ ko ṣe aṣeyọri.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, pupọ ninu awọn akẹgbẹ oun nile igbimọ aṣofin lọdun naa lọhun lo mọ gbogbo ọgbọn ti Baba Iyabo da lati ma fi ipo silẹ lasiko to yẹ.
O sọ pe "Mo le fidi rẹ mulẹ fun yin pe Obansanjo gbiyanju lati ṣe saa kẹta.
"O gbiyanju, bẹẹ lo sa gbogbo ipa rẹ lati ri saa kẹta ṣe amọ o lulẹ ninu igbiynaju rẹ.
"Toripe ko pe ẹnikẹni lori aago pe oun fẹ saa kẹta kii ṣe ẹri to dantọ lati fidi rẹ mulẹ pe ko gbiyanju rẹ.
"Ọgbọn ẹwẹ lo lo ṣugbọn gbogbo wa nile igbimọ aṣofin ni a mọ daadaa pe o ṣiṣẹ lọsan ati ni oru, koda, pupọ ninu wa ni awọn ẹmẹwa rẹ dunkoko mọ."
Bugaje ṣalaye pe lara awọn ti wọn dunkoko mọ lọdun naa lọhun ni Sẹnetọ to ṣoju ẹkun Ariwa nigba naa, Victor Lar.
O ni ọrọ naa le to bẹẹ ti Lar fi na papa bora fun ọpọ ọjọ.
O ṣalaye pe awọn to dunkoko mọ awọn atawọn to n fi owo le awọn kiri nigba naa ṣi wa laye lonii, bẹẹ ni awọn to gba owo nigba naa ko tii ku, nitori naa ẹlẹri oun ko si ni ọrun alakeji.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọdun 2006 ni awuyewuye waye lori atunṣe si ofin ọdun 1999 ki awọn aṣofin to pana rẹ.
To ba jẹ pe awọn aṣofin fi ọwọ si atunto naa lọdun naa lọhun ni, awọn Aarẹ ni Naijiria yoo lanfani lati maa lo saa mẹta lori alefa bayii.
Ṣé lóòótọ́ ni Obasanjo fẹ́ dupò ààrẹ Naijiria fún sáà kẹ́ta? Ààrẹ tẹ́lẹ̀ sàlàyé

Oríṣun àwòrán, Goodluck Jonathan/Facebook
Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Oloye Olusegun Obasanjo ti ṣalaye pe irọ to jina si ootọ lọrọ t'awọn eeyan kan ti n gbe kiri tipẹ wi pe oun gbiyanju lati dupo aarẹ fun saa kẹta.
Obasanjo fidi ọrọ yii mulẹ nibi ijiroro lori eto ìjọba awarawa ti Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri mii, Goodluck Jonathan, ṣagbatẹru rẹ niluu Accra, ti i ṣe olu ilu orilẹede Ghana.
Obasanjo ni ko si ẹni to ni ẹri to le fidi rẹ mulẹ pe loootọ loun gbiyanju lati dupo aarẹ Naijiria fun saa kẹta lẹyìn toun lo saa meji tan.
"Kìí ṣe pe ori mi o pe. Mo mọ nnkan ti mo le ṣe ti mo ba fẹ dupo aarẹ fun saa kẹta.
Ko si ọmọ Naijiria kan yala eyi to ti ku tabi wa laaye to le sọ pe mo pe oun wi pe mo fẹ dupo aarẹ fun saa kẹta," Obasanjo lo sọ bẹẹ.
Aarẹ ana naa fikun ọrọ rẹ pe biba awọn ti Naijiria jẹ lowo sọrọ lati fagile gbese ti Naijiria jẹ le ju ki oun gbiyanju lati dupo aarẹ fun kẹta lọ.
Obasanjo ni "gbogbo igba ni mo maa n sọ ọ pe ti mo ba fẹ dupo aarẹ fun igba kẹta ni toootọ ni, n ko ba ṣe bẹẹ, torí o rọrun fun mi lati lọ fun saa kẹta ju riri idarijin gba fun gbese ti Naijiria jẹ lọ."
Ẹyin olori ti ẹ kii fẹ fipo silẹ, ẹ jawọ nbẹ - Obasanjo
Aarẹ Naijiria tẹlẹ wa kìlọ fawọn olori orilẹede ti wọn kii fẹ fipo silẹ lati jawọ lapọn ti ko yọ.
Obasanjo ni lasiko ti eeyan ba si wa ni abarapa ni eeyan maa lokun lati le ṣiṣẹ daadaa.
"Ti ara ba ti di kujẹ kujẹ, eeyan o ni le ṣe ọpọ nnkan daadaa mọ.
Amọ, mo mọ pe awọn kan maa n ro wi pe t'awọn ko ba si níbẹ, ko si ẹlòmíràn to le ṣe e.
Wọn tiẹ tun máa n sọ pe awọn o tii ri ẹlomiran, mo ni igbagbọ pe ẹṣẹ ni eyi jẹ si Ọlọrun.
Idi ni pe Ọlọrun le gba ẹmi rẹ nigba kugba ti ẹlomiran yóò si bọ si ipo rẹ.
Ẹni to ba si bọ sí ipo rẹ naa le ṣe daadaa ju ọ lọ, o si tun le ma ṣe daadaa to ọ," Obasanjo ṣalaye.















