Kí ló tún fa ìjà àgbà láàárín Ataoja Osogbo àti Oluwo ti ìlú Iwo?

Aworan Ataọja ati Ọba Oluwo

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aipẹ yii ni ọrọ emi lagba, emi ni mo ju ọ, waye laaarin Alaafin Oyo; Oba Abimbola Owoade ati Ooni Ile-Ife; Oba Adeyeye Ogunwusi. Ni bayii, Ataoja Osogbo ati Oluwoo ti ilu Iwo, nipinlẹ Osun ni wọn tun bẹrẹ ija agba tiwọn.

Oba ilu Osogbo ti a mọ si Ataoja, Kabiyesi Oba Jimoh Oyetunji ati Oluwoo ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Akanbi, n ba ara wọn du ẹni ti ipo kẹrin tọ si ninu awọn ọba ipinlẹ Osun.

Bo tilẹ jẹ pe wẹrẹ ni ija agba naa bẹrẹ, o ti kari ayelujara bayii, bi awọn ti Oluwoo si ṣe n sọ pe iwọ lagba, bẹẹ ni awọn alatilẹyin Ataoja naa n sọ pe Ataoja lo wa nipo kẹrin ninu awọn ọba onipo nla nipinlẹ Osun.

Awijare awọn eeyan Ataoja ni pe Osogbo ni olu ilu ipinlẹ Osun, eyi si to lọtọ lati fi titobi ọba ilu naa han, ko si duro ni ipo kẹrin.

Awọn eeyan Oluwoo ni tiwọn n sọ pe Iwo ti wa latigba iwaṣẹ, wọn ni Oduduwa funra rẹ lo fun Oluwoo lade, o yatọ si ti Ataoja ti ko pẹ to bẹrẹ si i dade.

Báwo lèyí tún ṣe bẹ̀rẹ́ gan-an?

Bo tilẹ jẹ pe ọrọ ija agba yii ti wa nilẹ tẹlẹ, ko deede jade pada bayii.

Ataoja Osogbo, Ọba Jimoh Oyetunji lo wu u jade nigba to n ṣayẹyẹ ọdun kẹẹẹdogun rẹ lori itẹ laipẹ yii.

Yunifasiti ipinlẹ Osun ni Ataoja ti sọ pe lati ilẹ wa, Ataoja lo wa nipo kẹrin ninu awọn ọba ipinlẹ Osun.

O ni lasiko ti Ataoja ana, Ọba Iyiola Matanmi III, wa lori itẹ ni wọn gbe e fun Oluwoo ti ilẹ Iwo lọna aitọ.

Kabiyesi ilu Osogbo naa sọ pe oun ko ba ọba kankan ja, bi ko ṣe pe oun n fi idi otitọ to wa nipa ipo kẹrin ọba Osun naa mulẹ bo ṣe wa ninu itan.

" Lasiko ti Ataoja ilu Osogbo to waja, Oba Iyiola Oyewale,rin irin ajo lọ si oke okun ni, ko si too pada de, wọn ti gbe ipo rẹ fun Oluwoo ti ilẹ Iwo. Bi Oluwoo ṣe di ọba to wa nipo kẹrin ninu awọn ọba ipinlẹ Osun niyẹn.

"Nigba ti mo sọrọ nipe ẹ nigba kan, awọn eeyan ṣi mi gbọ, wọn yi ọrọ mi po, tori ẹ ni mo ṣe dakẹ ti mi o wi nnkan kan mọ, ṣugbọn mo n ṣiṣẹ naa labẹnu. Mi o ba ọba kankan ja, ṣugbọn Ataoja lo ni ipo kẹrin nipinlẹ Osun"

Bẹẹ ni Ataoja Osogbo ṣalaye.

O fi kun un pe awọn baba nla oun lo ti n di ipo kẹrin naa mu.

Oluwoo fèsì

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti Oba Abdulrosheed Akanbi; Oluwoo ilẹ Iwo, n fesi si ọrọ yii lati ọwọ Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibraheem, o tako alaye Ataoja Osogbo.

Atẹjade naa ṣalaye pe Ataoja fẹẹ yi itan pada pẹlu ohun to sọ naa ni.

Ninu esi naa ni Oluwoo ti rọ Ataoja lati kọ nipa itan ododo lati ọdọ awọn agbaagba ẹni apọnle l'Osogbo.

Oluwoo sọ pe ki Ataoja ma ṣe da oju ọrọ ru nipa ori itẹ awọn Baba nla Yoruba.

"Awọn eeyan ire ilu Iwo naa ti gbọ nipa fidio kan to n lọ lori ayelujara, eyi ti wọn ni Ataoja Osogbo lo ṣe e, to fi n jiyan ipo.

"Emi bii ẹnikan wo fidio naa pẹlu ijakulẹ ọkan, ṣugbọn ko jọ mi loju.

"O ye ki n ṣalaye yii lati da aabo bo itẹ Oluwoo ati ohun to le yi itan Yoruba pada.

"Bi a ṣe mọ, Baalẹ ni Ataoja titi di 1948 to ṣẹṣẹ bẹrẹ si i dade.

"Ade Atoaja ko ti i pẹ, oun ati awọn miran ni wọn jẹ lasiko ijọba ologun gomina David Jemibewon, ti wọn sọ dofin ni 1976.

"Iye ọdun ade ileke ti Oluwo n de ko ṣee ṣi, o ti wa lati ayebaye, lati orisun ni, ògidí si ni."

Eyi ati awọn ọrọ mi-in ni Ọba Akanbi fi gbe alaye rẹ lẹsẹ, ti awọn alatilẹyin rẹ si kin in lẹyin pe bẹẹ ni.

Ọrọ naa ko ti i pari, pẹlu bi ero awọn ọba naa ko ṣe jọ ara wọn.

Àlàyé Kọmiṣanna ọrọ oye jijẹ nipinlẹ Osun

Kọmiṣanna ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Osun, Amofin Dosu Babatunde, ṣalaye fun BBC nipa ọrọ yii pe:

"Awa o mọ pe ẹnikẹni n ja si nnkan kan, emi o tiẹ mọ pe wọn n ja.

"Ko si idi kankan fun ija, ọmọ ilẹ Yoruba ni wa .

"Gẹgẹ bii ọmọ Yoruba, ko yẹ ka tun maa fẹ ẹ loju, ẹbẹ ni mo maa bẹ pe ki ẹnikẹni ma jẹ ko fẹju.

"To ba tiẹ jẹ pe wọn n ja loootọ, ko yẹ ko jẹ awa alẹnulọrọ la tun maa fẹ ẹ loju, nnkan to yẹ ka jokoo yanju laaarin ara wa ni."