Ìdìbò bẹ́ẹ̀ni-bẹ́ẹ̀kọ́ bẹ̀rẹ̀ ní Guinea láti mọ èrò aráàlú nípa ìwé òfin tuntun

Oríṣun àwòrán, EPA
Ijọba orilẹede Guinea ti gbe eto idibo sita fun awọn araalu lati sọ ero wọn lori ṣiṣe iwe ofin tuntun, eyi ti yoo fun aarẹ ologun, Mamady Doumbouya ni anfani lati dupo aarẹ.
Apapọ oludibo toto 6.7m ni igbagbọ wa pe wọn yoo jade dibo lati fi ero wọn han sita lori iwe ofin tuntun ọhun.
Eyi jẹ igbesẹ akọkọ to da lori dida orilẹede Guinea pada si ijọba awarawa.
Lati le tẹwọgba esi idibo yii, ida aadọta araalu gbọdọ jade dibo lori iwe ofin tuntun yii.
Gẹgẹ bii National Gendarmerie ṣe ṣalaye, o le ni ọmọ ogun 45,000 ti ijọba ti da si ilu lati ri pe igbesẹ naa lọ ni irọnu ati lati ri pe awọn araalu jade fi ero wọn sita.
Ti igbesẹ ba jẹ itẹwọgba, iwe ofin tuntun yoo rọpo iwe ofin ti ijọba ologun gbe kalẹ, eyi to fofin de awọn oṣiṣẹ ijọba lati ma jade dupo ninu eto idibo.
Bakan naa ni ọpọ sọ "Bẹẹni" si ibeere lati se afikun si iye ọdun ti aarẹ yoo ma lo lati ọdun marun un si meje fun saa meji ati idasilẹ ile igbimọ aṣofin agba, ti aarẹ yoo si ma yan ida kan ninu ida mẹta awọn amofin.
Ọgagun Mamady Doumbouya ko ti kede erongba rẹ lati jade dupo aarẹ ṣugbọn awọn alatako rẹ ni igbesẹ idibo to gbe sita yii ti fihan pe o fẹ siwaju gẹgẹ bii olori orilẹede naa.
Doumbouya ditẹgbajọba ni oṣu kẹsan an ọdun 2021, to si le Aarẹ Alpha Conde, ẹni le kuro ni ilu lọ si Istanbul, kuro nipo aarẹ. Awọn olori ẹgbẹ alatako meji, Alpha Conde ati Cellou Dalein Diallo, ni wọn ti yago fun eto idibo naa, ti wọn si rọ awọn alatilẹyin naa lati ṣe bẹẹ.
Ijọba ologun Guinea kọ lati da ijọba ni ipari ọdun 2024 gẹgẹ bii ileri ti wọn ṣe.
Lasiko eto idibo yii lori iwe ofin tuntun, ijọba ologun ti ṣe ileri pe awọn yoo ri pe eto idibo si ipo ijọba waye ṣugbọn wọn ko ti kede ọjọ ti eyi yoo waye.
Ta ni ọ̀gágun Mahamady Doumbouya?
Mọ̀ si nípa ọ̀gágun Mahamady Doumbouya tó dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Alpha Condé
Ọjọ karun un, oṣu Kẹsan an, ọdun 2021 ni awọn ọmọ ogun gbajọba lọwọ Aarẹ Alpha Condé ti orilẹ-ede Guinea lẹyin ti wọn ti kọkọ ṣina ibọn bolẹ nile rẹ.
Lẹyin naa ni ọgagun Mahamady Doumbouya kede lori ẹrọ amohunmaworan ilẹ naa kan pe awọn Ologun ti gbajọba lọwọ alagb ada.
O si sọ pe awọn ọmọ ogun yoo gbe ijọba fun ẹlomiran wọọrọwọ ti akoko ba to.
Agbegbe Forecariah, to wa ni iwọ oorun Guinea ni ọgagun naa n gbe ki iṣẹlẹ iditẹgbajọba naa to waye.
O kawe gboye nile ẹkọ "War College" ni France, o si ni iriri iṣẹ ogun jija fun ọdun marundunlogun lẹyin to ti lọ foju wina ogun ni Afganistan, Cote d'Ivoire, Djibouti ati Central African Republic.















