'Ìgbà àkọ́kọ́ tí ọmọ mi Kevin lọ sílé ẹ̀kọ́, kò padà wálé o, ìròyìn ikú rẹ̀ ni wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi'
Ọmọ ọdun marundinlogun ni Kevin Moses, pẹlu inu didun lo si fi n foju sọna fun ọjọ akọkọ ti yoo lọ si ile ẹkọ giga, lẹyin to pari ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ.
Ọpọlọpọ ala rere ni Kevin ni fun ọjọ ọla rẹ, to si ti wo o pe lilọ ile ẹkọ giga Achimota yoo jẹ ara ọpakutẹlẹ fun imuṣẹ ala rere rẹ.
Amọṣa ọrọ gba ẹyin yọ fun Kevin ati iya rẹ lẹyin ti Kevin lọ si ile ẹkọ, nitori pe alọ rẹ ni iya rẹ ri ko ri abọ rẹ rara.
Dipo iroyin ayọ nipa ijafafa ọmọ rẹ nilẹkọ, iroyin iku Kevin ni wọn mu tọ iya rẹ wa.
Akẹkọọ mẹfa lo ti ku laarin oṣu mẹwaa
Laarin oṣu karun ọdun 2023 si oṣu keji ọdun 2024, akẹkọọ mẹwaa kaakiri awọn ile ẹkọ onileegbe ti wọn n pe ni boarding school lo ṣalaisi ti awọn obi ati ẹbi wọn si n sọ pe okunfa iku wọn ṣe e dena.
Ninu ipẹjọ kan lori iku akẹkọọ naa niwaju ileẹjọ giga orilẹede Ghana kan, ile ẹjọ naa fi idi rẹ mulẹ pe ile ẹkọ Achimota jẹbi fifi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ aarẹ to ṣokunfa iku Kevin Moses.
Amọṣa ileẹkọ giga Achimota ti pẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ naa.





