Afrika lè di orílẹ̀ tó mọ́ jùlọ láàárín méjì bí gbogbo wab á tọ́jú àyíká wa – Streezboiz

Àkọlé fídíò, Afrika lè di orílẹ̀ tó mọ́ jùlọ láàárín méjì bí gbogbo wab á tọ́jú àyíká wa – Bustop boiz
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lọdun meji sẹyin arakunrin kan pinnu lati yoo bẹrẹ igbesẹ lati ṣetọju ayika ki gbogb rẹ le mọ tonitoni.

Heneba Kwadwo Sarfo ati ọrẹbinrin rẹ to ti di iyawo rẹ bayii lati bẹrẹ si ni jade kaakiri lati maa ko ẹgbin ati idọti danu.

"Awọn eeyan bu wa daadaa nigba ti a bẹrẹ lọdun 2023. Igba miran bi a ba n tọju ayika kan, awọn eeyan kan a maa sọ fun wa pe ka lọ sinmi nitoripe ib a tun ṣi pada dọti."

Ni orilẹede Ghana ni arakunrin yii ti n ṣe iṣẹ gbalumọ yii.

Ni bayii, o ni iye awọn to ti wa dara pọ mọ awọn ti pọ to bẹẹ ti awọn ti le ni ogoje bayii.

Akẹkọgboye imọ ijinlẹ fasiti ni arakunrin naa, ṣugbọn o gbe e ti sẹgbẹ kan ni lati tọju ayika nitori, gẹgẹ bi ọrọ rẹ, "ayika wa ko fẹ mọ boya dokita, olukọnini ọ tabi ohunkohun yoowu ti o le jẹ, bi aisan iba b agba ẹ muwaa dubulẹ aisan."