Bí Wike àti Fubara ṣe tí parí ìjà, wo nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa 'Bàbá ìsàlẹ̀'

Aworan Bola Tinubu, Nyesome Eike ati Fubara

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Aarẹ Bola Tinubu ati Gomina ipinlẹ Rivers, Siminalayi Fubara pade ni ile jjọba orilẹede Naijiria lana niluu Abuja, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe alaafin ti jọba nipinlẹ naa.

Fubara, ẹni to pada si ipo Gomina ni ọsẹ to kọja lẹyin ti aarẹ Tinubu kede ilu o faraọ nipinlẹ Rivers fun oṣu mẹfa.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade rẹ pẹlu Aarẹ Tinubu, Fubara ni oun gbe igbesẹ lati wa si ọdọ Aarẹ nitori oun fẹ dupẹ lọwọ rẹ ati lati jẹ ko mọ pe oun ti pada si ipo Gomina ipinlẹ Rivers.

"Ẹ mọ pe ikede ilu o faraọ ti pari ni ọjọ Kẹtadinlogun Oṣu Kẹsan an, ti mo si pada si ẹnu iṣẹ ni Ọjọ Kọkandinlogun.

"O tọna pe ki n wa sọ fun Aarẹ pe mo ti pada si ẹnu iṣẹ mi gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Rivers."

Nigba ti wọn n bi nipa ajọsepọ pẹlu gomina ana nipinlẹ Rivers, Nysesome Wike, Fubara ni oun ti oun mọ to da oun loju ni pe alaafia ti jọba laarin awọn mejeeji, ti wọn si n ṣiṣẹ papọ lati mu ilọsiwaju ba ipinlẹ naa.

Oriṣiiriṣii iṣẹlẹ lo waye laaarin oṣu mẹfa naa, ninu rẹ ni Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe Ibas ti yan awọn eeyan ti yoo bojuto ijọba ibilẹ mẹtalelogun to wa ni Rivers lati ba a ṣiṣẹ.

Ninu rẹ ni Fubara ati Wike ti ni awon ti pari ija, iyẹn loṣu Kẹfa ọdun yii, ti wọn ṣepade pẹlu Aarẹ Tinubu l'Abuja.

Bii baba ati ọmọ ni Nyesom Wike ati Siminalayi Fubara ri tẹlẹ, ko too di pe ọrọ oṣelu da wahala silẹ laaarin wọn.

Lara awọn ohun to fa rogbodiyan naa ree:

Igbẹsẹ awọn aṣofin lati yọ gomina Fubara nipo, eyi to waye loṣu Kẹwaa ọdun 2023.

Awọn kan wa lẹyin Fubara, ṣugbọn ọpọ lo tẹlẹ Wike to wa lẹyin iyọnipo naa.

Wọn dana sun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Rivers, wọn ba awọn apa kan ibẹ jẹ, bẹẹ ni awọn kan n kuro ni PDP lọ si APC, bo tilẹ jẹ pe wọn pada sọ pe awọn ko fi ẹgbẹ silẹ.

Wo awọn iṣẹlẹ lori Baba iṣalẹ to ti waye ṣaaju

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lamidi Adedibu ati Rasidi Ladoja

Ni ipinlẹ Oyo, laarin ọdun 2003 si 2007, ko si ẹni ti ko mọ nipa ija to bẹ silẹ laaarin gomina Oyo nigba naa, Rasidi Ladoja ati agba ọjẹ oloṣelu nipinlẹ, Lamidi Adedibu.

Ifẹ lo kọkọ ba de aarin awọn oloṣelu mejeeji, ko to di pe gbọnmisi omi to waye, ti wọn si kọ ẹyin si ara wọn

Lẹyin-ọ-rẹyin, ile igbimọ aṣofin nigba naa ni ki Gomina Rasidi Ladoja lọ rọkun ni ile, ti wọn si kede Adebayo Alao-Akala gẹgẹ bii gomina.

Iṣẹlẹ yii de ile ẹjọ, ti wọn si da Gomina Ladoja si ipo.

Ọmọ Baba sọrọ nipa aawọ naa, o ni "Ija laarin Sẹnẹtọ Ladoja to jẹ ẹgbọn si mi ati Baba to bi mi, ọmọ ni Sẹnẹtọ Ladọja si baba.

"Awọn oloṣelu, wọn mọ iwa ara wọn, ohun to o de sẹlẹ laarin awọn mejeeji, ko ba ti yanju ti Baba ba si wa laye,

"Awọn eeyan lo tun da sii, nitori pe wọn a gbọ ti ọdọ ẹgbọn mi Ladoja, wọm a lọ sọ fun baba to bi mi, wọn a gbọ ti baba to bi mi, wọn a lọ sọ fun ẹgbọn mi Ladoja."

Ọrọ pọ lẹnu Dokita Abass Adedibu, ẹ wo fọnran yii.

Peter Obi ati Willie Obiano

Peter Obi ati ẹni to gba ipo gomina lọwọ rẹ, WIllie Obiano ni ajọsepọ nla ṣaaju eto idibo ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ lẹyin eto idibo.

Obi ati Obiano jẹ akẹgbẹ ni ile ẹkọ Christ the King College, CKC, Onitsha.

Ajọsepọ yii laaarin awọn mejeeji pada di ọta meji lẹyin ti Obi kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APGA lọ sinu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Lasiko eto idibo ọdun 2017 , Obi leri pe oun yoo fidi ọmọ Obiano janlẹ.

"Mo ma ja fun eto idibo yii, am si gbogbo ara mi ja fun eto idibo yii, ti ma si ri pe ẹgbẹ oṣelu PDP bori eto idibi" o sọ lasiko naa.

Ẹwẹ, lẹyin-ọ-rẹyin, Obi fidi janlẹ pẹlu oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Oseloka Obaze.

Kwankwaso ati Ganduje

Laarin ọdun 1999 si 2015, Rabiu Kwankwaso ati Umar Ganduje jẹ nnkan ti a le pe ni korikosun. Ni ọdun 2003, Ganduje ni igbakeji gomina si Kwankwaso, ati nigba ti wọn jọ padanu ibo. Kwankwaso di minisita fun eto aabo labẹ iṣejọba Olusegun Obasanjo, ti igbakeji rẹ si tẹle lọ si Abuja.

Nigba ti Kwankwaso pada ni ọdun 2011, Ganduje tun ni igbakeji rẹ, ti ko si jẹ ohun iyanlẹnu nigba ti APC fun Ganduje ni tikẹẹti fun ipo gomina lọdun 2015 ṣugbọn ija bẹ silẹ lẹyin eto idibo.

Lori ija, Emir ilu Kano, Sanusi Lamido padanu ipo gẹgẹ bii Emir, ti Kwankwaso si ni lati kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC.

Adams Oshiomhole ati Godwin Obaseki

Adams Oshiomhole ko ipa nla lati ri pe Godwin Obaseki di gomina ipinlẹ Edo lẹyin to kuro ni ipo Gomina lẹyin ọdun.

Obaseki ṣiṣẹ labẹ Oshiomhole gẹgẹ bii alaga to n risi eto iṣuna ipinlẹ Edo, Edo State Economic Team.

Pẹlu bii wọn ti ṣe ni ajọsepọ to lerinrin ṣugbọn ija to waye laaarin wọn kọja nnkan ti a fi ẹnu wi.

Oshiomole lo agbara rẹ gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oṣelu APC lasiko naa lati ma fun Obaseki ni tikẹẹti lati gbe apoti ibo fun saa keji ṣugbọn Obaseki morile ẹgbẹ oṣelu PDP, to si tun bori eto idibo naa.

Tinubu ati Ambode

Ni ọdun 2014, Akinwunmi Ambode gbe apoti ibo gomina ipinlẹ Eko ni ọdun 2015, ti Aarẹ orilẹede Naijiria bayii, Bola Tinubu si fun ni iwuri.

Fun bi ọdun mẹta lẹyin eto idibo, gbogbo nnkan lọ pẹlu alaafia laaarin Tinubu ati Ambode. O ku ọsẹ diẹ si eto idibo abẹle ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, ni itan yii pada fun Ambode.

Gbogbo agbara rẹ lati ja pada lo ja si pabo.

Ambode da lori ọrọ naa, to si padanu eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko sọwọ Babajide Sanwo-Olu.