Wo àwọn ọ̀nà tí o lè máa fi pawó lóríi Facebook

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Isiyaku Muhammed
- Role, BBC Hausa, Abuja
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Lọwọ yii lori opo ayelujara, ọpọ awọn ọdọ to n pe fun pe ki awọn eeyan tẹle wọn lori ayelujara paapa lori Facebook.
Ẹ ti ma n ṣalabapade wọn lori awọn opo kan lori Facebook, ti wọn yoo ma kọ si abẹ ohun ti ẹ ba gbe sita pe 'Tẹle mi ki n tẹle rẹ pada', eyi ma n mu ọpọ binu, ti wọn si ma n fi ọrọ kunbakugbe ransẹ si ara wọn.
Ọrọ nipa tẹle mi ki n tẹle rẹ bẹrẹ nigba ti awọn alaṣẹ ikanni Facebook ka orilẹede Naijiria mọ awọn orilẹede ti wọn yoo ma fun ni owo lori nnkan ti wọn bag be sita lori ayelujara wọn.
Eyi lo fa ti ọpọ awọn ọdọ fi morile ikanni Facebook, ti wọn si bẹrẹ si ni ma jẹ anfani awọn nnkan wọnyi lori loju opo Facebook.
Ẹwẹ, awọn amọye ni pe awọn ofin ati ilana kan wa ti opo Facebook gbe kalẹ fun ẹnikẹni to ba fẹ jẹ anfani yii.
Wo awọn ọna naa
Lati mọ eyi, BBC kan si Abdullahi Salihu Abubukar, ẹni ti ọpọ mọ si Baban Sadiq, onimọ nipọ tech.
O ni ọna orisirisi lo wa lati pa owo wọle paapa ti eeyan naa ba ni ọpọ eeyan to n tẹle oju opo rẹ, to si n gbe ọpọ iroyin to ni itumọ soju opo rẹ, eyi ti awọn alatilẹyin rẹ nifẹ si.
Baban Sadiq ṣalaye awọn nnkan wọnyi:
Facebook Ad Breaks : Ti o ba ni oju opo ti o ni ọpọ fọnran to gun, ati ọpọ eeyan to n tẹle rẹ, o le ma pawo wọle lati ori ipolowo ori Facebook, ti wọn ma fi sinu awọn fidio rẹ.
Bi awọn alatilẹyin ba ṣe n wo awọn ipolowo yii, ni yoo ma pawo.
Brand Partnerships : Bakan naa ni awọn ileeṣẹ le san owo fun eeyan pe ki wọn ba wọn polowo nnkan fun awọn eeyan loju opo ikanni Facebook.
Affiliate Marketing : Eyi da lori ṣiṣe ipolowo ọja fun awọn ileeṣẹ miiran lori ikanni Facebook, ti ẹnikẹni ninu awọn alatilẹyin rẹ ba tẹ link oju opo naa, ti wọn sir a ọja, o ni iye ti wọn yoo fun iwọ to ba wọn gbe sita.
Live rewards (Facebook Stars): Nigba kugba to ba ṣe "Facebook live" tabi "Instagram live", awọn eeyan to n tẹlẹ rẹ le fi irawọ ransẹ si gẹgẹ bi ẹbun, ti o le sọ di owo.
O fikun pe o le lo Facebook lati fi ṣe ipolowo ọja fun ohun to n ta fun ara rẹ.
Ohun tí o gbọ́dọ̀ ṣe láti rí owó gbà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi ileeṣẹ Meta ṣe wi, akọkọ ni pe:
O kere ju, o gbọdọ ti pe ẹni ọdun mejidinlogun (18).
*O gbọdọ maa gbe lorilẹ-ede ti wọn ti mọ ọ pẹlu iṣẹ ti o n ṣe.
*O kere tan, o gbọdọ ni olutẹle (followers) ẹgbẹrun marun-un loju opo naa.
*Eeyan ẹgbẹrun lọna ọgọta (60,000 viewers), o kere tan gbọdọ wo fiimu rẹ laarin ọgọta ọjọ.
Awọn ti wọn ṣe fiimu yii ati awọn ti wọn sanwo fun ipolowo rẹ ko si ninu eeyan ẹgbẹrun lọna ọgọta yii o, ileeṣẹ Meta ko ni i ka wọn mọ ọn.
O kere tan, oju opo rẹ gbọdọ ni aworan marun-un tawọn eeyan le ri.
Ki i ṣe gbogbo aworan lo kunju oṣuwọn, awọn mi-in le ma tẹ Meta lọrun, wọn ko si ni i pawo.
Òfin tó de yíya àwọn àwòrán àti ìpolówó ọjà.
Fun awọn aworan to n ṣafihan iṣẹlẹ bo ṣe waye, o kere tan, o gbọdọ ni ẹgbẹrun mẹwaa olutẹle.
*Wọn ti gbọdọ wo fidio naa fun iṣẹju ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta (600,000 minutes) laarin ọgọta oru, (60 nights).
* O kere tan, aworan marun-un ti iwọ funra rẹ ṣe mẹta ninu rẹ gbọdọ wa niwaju fawọn eeyan lati ri.
* O lodi sofin lati lo ere to ni i ṣe pẹlu iku, ibalopọ, eke ṣiṣe, iroyin ofege ti ki i ṣe otitọ abi iroyin nipa ilera to jẹ irọ gbuu ni.















