Ìdí tí mo fi ra ọmọ ọlọ́mọ ní ₦3.7m l'Ondo - Afurasí

Ọwọ afurasi kan ninu ahamọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọwọ awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ti tẹ awọn afurasi kan ti wọn maa n ji ọmọ ọlọmọ gbe ta kaakiri ipinlẹ Ondo, Anambra ati Delta.

Ọjọ kẹta oṣu keji ọdun 2025 ni arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Sunday Kingsley ke gbajare tọ awọn olopaa lagbegbe Alagbaka extension nilu Akure lọ pe ki wọn dakun dabọ ba oun wa ọmọ oun, Jesinta Sunday to jẹ ọmọ ọdun mẹrin.

Arakunrin Sunday ni ọmọ oun ti oun ati Iyawo oun jọ n gbe pọ ti di awati.

Wọn gbe ọrọ naa tọ ile ẹjọ majisireeti mọlẹbi (Family Magistrate Court) to wa nilu Akurẹ lọ; ileẹjọ naa si ni ki wọn lọ sọ iya ọmọ naa ti orukọ rẹ njẹ Nneka Onah ati iyawo arakunrin ọhun ti orukọ rẹ njẹ Happiness mọle si ọgba ẹwọn to wa ni ilu Ondo, ki wọn to gba beeli wọn.

Amọṣa iwadii ileeṣẹ ọlọpaa n tẹsiwaju, ti wọn si ba a ja ojuna losu keje, nigba ti baba ọmọ naa tun pada wa si agọ ọlọpaa lati tun wa ta wọn lolobo pe awọn ti kẹẹfin ọmọ to sọnu naa ni ilu Asaba ni ipinlẹ Delta.

Lootọ awọn ọlọpaa ri ọmọ naa nigba ti wọn de ibẹ, koda ọwọ wọn tẹ afurasi kan ti orukọ rẹ n jẹ Amaka Chukwuemeka, ẹni ọgbọn ọdun, to ko alaye ṣe fun awọn agbofinro pe, miliọnu mẹta ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin Naira (₦3.7m) loun ra ọmọ naa.

O tun fi kun un pe ọrẹ oun kan, Chinaza Owoh, ẹni ọdun mejidinlogoji lo mu oun mọ obinrin kan, iyẹn Mabel Esimai ẹni ọdun mejidinlọgọta to fun oun lọmọ naa gẹgẹ bi afun-n-tọ, pẹlu awọn ayederu iwe ofin to de ilana afun-n-tọ lati kin lẹyin.

Arabinrin Mabel pẹlu tun darukọ afurasi miran, Chioma Okechukwu to ni o gbe ọmọ naa fun oun lati wa onibara ti yoo ra a.