Aráùlú lu ọ̀dọ́kùnrin tó jí Cocoa pa l'Ondo, olóko dèrò àtìmọ́lé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti kilọ faraalu lati dẹkun ati maa fi ofin si ọwọ ara wọn.
Ọrọ yii lo jade lẹyin ti wọn mu afurasi lori iku ọdọkunrin kan ti wọn lu pa niluu Akungba-Akoko lori ẹsun pe o ji coacoa.
Alukoro ileeṣẹ naa, Ayanlade Olayinka Olusola sọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin pe adugbo Akunmi ni iṣẹlẹ naa ti waye niluu Akungba.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, nnnkan bii aago meji abọ ọsan ni wọn ke si ọlọpaa pe awọn kan ti lu ọdọkunrin kan bii ẹni maa ku lori ẹsun pe o ji coacoa ninu oko oloko.
Lẹyin ti wọn lu u daadaa tan ni wọn gbe lọ si agọ ọlọpaa amọ ọlọpaa ni ki wọn kọkọ gbe lọ sile iwosan fun itọju latari lilu naa.
Nigba ti yoo fi di aago marun un abọ irọlẹ, ọdọkunrin naa ti dagbere faye.
Lẹyin iku rẹ ni ọlọpaa fi panpẹ ofin gbe ẹni to ni coacoa to tun mu ọrọ rẹ wa si agọ wọn nigba ti wọn gbe oku naa lọ sile igbokupamọsi fun ayẹwo.
Ayanalade sọ pe wọn ti taare ọrọ naa si ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran, CID, to wa niluu Akure fun iwadii ni kikun.
Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Adebowale Lawal, ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa.
Lẹyin naa lo kilọ faraalu lati dẹkun ati maa fi ofin si ọwọ ara wọn ni gbogbo igba ti ọwọ wọn ba tẹ afurasi lori eyikeyi ẹsun.
O ni niṣe lo yẹ ki araalu maa fa afurasi le awọn ọlọpaa lọwọ dipo ki wọn maa da seria fun afurasi funra wọn.
Kọmiṣọna naa tun ba awọn mọlẹbi oloogbe naa kẹdun ọmọ wọn ti wọn padanu.
O tun ṣeleri fun wọn pe iwadii kikun yoo waye lori ọrọ naa ti gbogbo awọn to lọwọ ninu iku ọdọkunrin ọhun yo si foju wina ofin.















