Peter Mutharika padà sipò Ààrẹ Malawi lẹ́ni ọdún 85

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Malawi tẹlẹ, Peter Mutharika ti du ipo Aarẹ orilẹede naa lẹẹkansi, o si ti bori bayii ninu idibo Aarẹ to ṣẹẹẹ to waye nibẹ.
Alaga ajọ eleto idibo orilẹede ọhun, Annabel Mtalimanja kede pe Mutharika fidi Aarẹ to wa lori oye lọwọ, Lazarus Chakwera janlẹ.
Ida 57% gbogbo ibo ti wọn di nibẹ ni Mutharik ko nigba ti Chakwera ni ida 33% ibo ọhun.
Ṣaaju ipadabọ abija rẹ yii ni Mutharika to jẹ ẹni ọdun marundinlaadọrun ti kọkọ tukọ ijọba Malawi laarin ọdun 2014 si ọdun 2020 ki Chawekra to fidi rẹ janlẹ lọdun naa lọhun.
Ni bayii ti Mutharika ti pada sori oye, yoo jogun ọrọ aje to dagẹgẹ, iṣoro aisi epo atawọn gbankọbgi iṣoro mii.
Ẹwẹ, Aarẹ Chakwera ti kede pe oun ti gba pe lootọ loun lulẹ ninu eto idibo naa lẹyin to ti wa nipo Aarẹ lati ọdun 2020.
Ninu ọrọ to sọ lẹyin eto idibo ọhun lo ti sọ pe oun gba pe Mutharika fidi oun janlẹ, lẹyin naa lo ki ku oriire.
O ni "Ninu esi ibo to jade, o han gbangba pe alatako mi, Ọjọgbọn Mutharika lo n lewaju tente, mo si ti pe e lati ki ku oriire fun aṣeyọri yii."
Lẹyin naa lo ke si awọn araalu atawọn alatilẹyin rẹ lati ma fa wahala kankan ki wọn si gba esi ibo naa wọle.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Mutharika ree
Olukọ imọ agbẹjọro ni Arthur Peter Mutharika ni fasiti kan niluu Washington, oun si ni Aarẹ Malawi lati ọdun 2014 si ọdun 2020.
Gẹgẹ bii ohun ti Washington University sọ, Aarẹ Malawi naa ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu awọn fun nnkan bii ọdun mẹrindinlaadọta ko to darapọ mọ ẹka imọ ofin lọdun 1976.
Nigba ti wọn dibo yan ibatan rẹ, Bingu Wa Mutharika lọdun 2004, o ṣiṣẹ gẹgẹ bii olubadanmọran rẹ fun ọdun marun un.
Lọdun 2008, wọn kede rẹ gẹgẹ bii olubadanmọran agba si Bingu Wa Mutharika lori ọrọ ofin ati ọrọ ilẹ okeere.
Mutharika ni miniisita fun ọrọ ilẹ okere laarin ọdun 2011 si 2012.
Nigba ti yoo di ọdun 2014 ni wọn dibo yan Mutharika sipo Aarẹ.
O tẹle ipasẹ ẹgbọn rẹ ti wọn tun dibo yan lọdun 2009 amọ t o jade laye nigba to ṣi wa lori oye lọdun 2012.
Nigba to n ṣe ipolongo ibo, Mutharika ṣeleri lati tun orilẹede naa ṣe ati lati da ireti araalu pada sinu ijọba.
O ni oun yoo da irẹpọ pada si orilẹede naa, oun yoo din bi ijọba ṣe n na owo ku, bẹẹ ni oun yoo din gbese orilẹeede naa ku.















