Àwọn agbébọn pa ọlọ́pàá, aláboyún, àtàwọn míì, jí ọ̀pọ̀ gbé lọ ní Kwara

Aworan Kọminsan fun ileeṣẹ ọlọpaa, Adekimi Ojo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ibanujẹ nla gbaa lo jẹ ni ilu Motokun ni ijọba ibilẹ Patigi, Ipinlẹ Kwara lọjọ kẹtalelogun osu yii, latari ikolu awọn agbebọn to fi awọn eniyan sinu ẹru ati laasigbo.

Ni ilu Motokun ni awọn agbebọn naa pa obinrin alaboyun kan, awọn marun-un mii farapa yana-yana, wọn si tun gbe eeyan mejidinlogun lọ.

Bí ìkọlù náà ṣe wáyé

BBC Yoruba ba ọkan lara awọn olugbe agbegbe Motokun, ọgbẹni Ahmed Abubakar sọrọ lori ago, o si salaye bi ikọlu naa se sẹlẹ.

Ahmed sọ pe, "awọn agbebọn naa to ogoji niye pẹlu ibọn AK47, wọn wọ ilu Motokun ni nnkan bi ago mẹfa aarọ ọjọ Isẹgun pẹlu ohun irinsẹ alupupu, wọn si n yinbọ.

"Awọn araalu sare pe awọn sọja lati wa doola wọn sugbọn wọn ko yọju si bẹ"

"Awọn agbebọn yii sọsẹ ninu ilu naa fun bi wakati mẹrin, ko si si iranlọwọ lati ibi kan.

"Wọn yinbọn pa obìnrin alaboyun kan nigba to kọ jalẹ lati tẹle wọn, lẹyin naa ni wọn ji eniyan mejidinlogun gbe lọ.

"Ni bayii, awọn araalu n binu, wọn ni ijọba o daabo bo awọn to bo tiyẹ, koda, awọn eniyan ti n sa kuro ni ilu naa lọwọ lọwọ" .

Tẹ o ba gbagbe, iroyin iṣẹlẹ ipaniyan ati ijinigbe ti di lemọ ni agbegbe yii, to bẹẹ ti awọn eniyan ko lee loko mọ, awọn ọja paapa ti dahoro, bẹẹ si ni awọn olugbe o lee sun pẹlu oju mejeji ni didi mọ.

Àjọ ọlọ́pàá fìdí iṣẹlẹ náà múlè

Atẹjade ti agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa ni Kwara, SP Adetoun Ejire-Adeyemi filede fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Adetoun sọ pe, ni ọjọ Isẹgun, ọjọ kẹtalelogun, awọn agbebọn ya wọ ilu Motokun ati ilu Agboro ni ijọba ibilẹ Patigi ni Ipinlẹ Kwara.

"Iwadi fihan pe ni Motokun, eeyan mẹfa ni wọn ji gbe lọ, nigbati eeyan mẹfa farapa.

"O ṣeni laanu pe, arabinrin kan ninu awọn to farapa pada ku si ile iwosan, ti awọn yoku si n gba itọju lọwọ.

‎"Lẹyin ti wọn kuro ni Motokun, wọn gba ilu Agboro lọ nibi ti wọn ti doju kọ ileesẹ aladani kan.

"Ẹmi ọlọpaa kan to wa ni ileesẹ naa bọ lẹyin to ti ja fita-fita nibi ikọlu naa, wọn si tun ba awọn ohun ini ati ẹru jẹ ni ileesẹ naa.

Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá tí dárí ọmọ ogún sí Motokun

Agbẹnusọ naa sọ pe, ọga agba ajọ ọlọpaa ni Kwara, CP Adekimi Ojo ti dari awọn ọmọ ogun ọlọpaa to fi mọ awọn sọja lọ sibi iṣẹlẹ naa, lati rii pe awọn ti wọn ji gbe di riri.

O ba awọn tọrọ naa kan kẹdun, o si gba araalu niyanju lati fọkanbalẹ ki wọn fi ohun gbogbo to ba ru wọn loju lagbegbe to awọn ọlọpaa leti.