Ipò ọba ọ̀tọ̀, ipò òṣèlú ọ̀tọ̀! Èyí làwọn àmọ̀rọ̀n tí Obasanjo gba Olubadan tuntun, Rashidi Ladoja

Aworan Olubadan tuntun, Oba Adewolu Ladoja ati Aarẹ nigba kan ri lorilẹede Naijiria, Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo ti ki Olubadan tuntun, Oba Abdul Rasheed Ladoja ku orire iwuye rẹ gẹgẹ bii Olubadan Kẹrinlelogoji ti ilẹ Ibadan.

Obasanjo, ninu ọrọ ikinikuorire to fi sita rọ Ọba Oba Ladoja pe suuru, ọgbọn inu ati kiko akoyawọ jẹ ohun to ṣe pataki lati di ipo naa mu.

O tẹnumọ fun gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri naa pe ko ri daju pe ko da oṣelu ati ipo ọba papọ nigba to ba de ori ipo Olubadan tan.

Ayẹyẹ ifinijoye Olubadan yoo waye lọjọ Ẹti Kẹtadinlọgbọn oṣu kẹsan an ọdun 2025 niluu Ibadan.

"Iyi nla ni pe ki eeyan di ipo agba mu, paapa iru ti ipo Olubadan ti ilẹ Ibadan. O gba ọgbọn ati oye pẹlu suuru lati le ṣe aṣeyọri," Obasanjo sọ ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Kehinde Akinyemi fi sita.

"Ipo olori ilu ko ki da pọ mọ ipo oṣelu.

"Mo gba ladura pe wa ṣe aṣeyọri lagbara Ọlọrun," o fikun .

Olubadan Ikẹrinlelogoji ti ilẹ Ibadan

Ọba Rashidi Adewolu Ladoja ṣapejuwe irin-ajo rẹ si itẹ Olubadan gẹgẹ eyi ti o kun fun idanwo ati ilakọja to lagbara.

Ọba Rashidi Adewolu Ladoja ṣalaye pe ọdun 1944 ni wọn bi oun, ti oun yoo si di Olubadan 44th laipẹ yii.

Ladoja ni Ifa kọ lo n yan Ọba Ibadan, owo si kọ lo n yan Ọba Ibadan, Ọlọrun ni.

"Ọjọ kinni osu kẹwa ọdun 1993 ti mo gba oye gẹgẹ bi jagun Olubadan, ọpọ eeyan lo peju sibẹ.

"Awọn bii Basorun Moshood Kashimawo Abiola, Oloye Lamidi Adedibu, Gomina tẹlẹ Kolapo Olawuti Ishola ati Adebayo Alao Akala.

"Bakan naa, Dokita Dejo Raimi, baba ati iya mi ati awọn eeyan jankan jankan miran bii Jimoh Aliu, Orisabunmi atawọn osere tiata miran, lo peju sibi ayẹyẹ iwuye naa.

"Amọ ọpọ awọn eeyan nla yii lo ti di oloogbe, sugbọn Ọlọrun da ẹmi mi si, ti maa si gba Ade Olubadan laipẹ."