Rasidi Ladoja: Àwọn àyípadà ọ̀tun tí yóò bá Ibadan lásìkò mi gẹ́gẹ́bí Olubadan nìwọ̀nyí

Olubadan tuntun, Oba Rasidi Adewolu Ladoja to wọ agbada, fila ati ilẹkẹ

Oríṣun àwòrán, @Yorubaness

Àkọlé àwòrán, O ni gbogbo asiko oun gẹgẹ bii oniṣowo ati oloṣelu ti mura oun silẹ fun ipo tuntun naa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Olubadan tuntun, Oba Rasidi Adewolu Ladoja, ti sọ pe asiko oun lori itẹ Olubadan yoo mu igba ọtun de ba araalu, yoo si mu idagbasoke ba ilu Ibadan lapapọ.

Ninu ifọrọwerọ kan to waye ninu ile rẹ niluu Ibadan lo ti ṣalaye iran rẹ fun ilu Ibadan papapọ.

O ni ki araalu maa reti ayipada ọtun lasiko oun dipo afẹfẹyẹyẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, gbogbo asiko rẹ gẹgẹ bii oniṣowo ati oloṣelu ti mura rẹ silẹ fun ipo tuntun naa.

O ni "Ilu Ibadan ni ogo iha iwọ oorun Naijiria laye atijọ mo si fẹ ki a pada si ipo ti a wa tẹlẹ.

"A ni ọpọ ọmọ kaakiri agbaye ti wọn n gbe ohun rere ṣe amọ awọn kan sọ pe kii ṣe ayanmọ wọn lati sin ilu. Gbogbo iyẹn ni igba ọtun yoo de ba."

Ladoja sọ pe awọn minisiter tẹlẹ bii Frank Nweke Jnr ati Aarẹ WTO, Ngozi Okonjo-Iweala gbe ogo ilu wọn ga, ko si ohun to ni ki awọn ọmọ Ibadan naa ma gbe ogo ilẹ wọn ga.

Gomina tẹlẹri naa juwe ara rẹ gẹgẹ bii ẹni to fẹran igbeaye irẹlẹ dipo igbeaye afẹfẹyẹyẹ.

O ni "Ọpọ eeyan lo ro pe ipo faaji ati afẹfẹyẹyẹ ni ipo Ọba ṣugbọn ero aye atijọ niyẹn.

"Lode oni, a gbọdọ ka aṣọ wa soke ki a si ṣiṣẹ sin araalu… ni temi, ki n jẹun to dara, ki n si gbe igbeaye rere wu mi ju wiwọ aṣọ nla lọ."

Lẹyin naa lo fidi rẹ mulẹ pe Aarẹ Bola Tinubu, awọn gomina atawọn eeyan nlanla mii ni Naijiri ni yoo peju sibi ayẹyẹ iwuye oun yi yoo waye lonii.