Mọ̀ nípa àwọn Olóyè Ogoni mẹ́rin tó kú sórí ìjà fún ilẹ̀ wọn tí Tinubu foyè CON dá lọ́lá

Edward Kobani, Albert Bade, Samuel Orage, ati Theophilus Orage, awọn oloye Ogoni mẹrin

Oríṣun àwòrán, @ThatVyktur/X

Àkọlé àwòrán, Olori ijọba ologun Naijiria nigba naa, Abacha, fẹsun kan onkọwe ati ajafẹtọọ ayika, Ken Saro-Wiwa atawọn akẹgbẹ rẹ mẹjọ mii wi pe awọn lo ṣokunfa iku awọn oloye mẹrin naa.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bola Tinubu ti fi oye CON da awọn ajijagbara ati oloye ilẹ Ogoni mẹrin ti wọn ṣeku pa lọdun 1994 lasiko ijọba ologun Sani Abacha lọla.

Awọn oloye naa, Edward Kobani, Albert Bade, Samuel Orage, ati Theophilus Orage, ja fun atunṣe ati aabo ilẹ Ogoni lọwọ ileeṣẹ ifọporọbi Shell to n wa epo lagbegbe naa.

Olori ijọba ologun Naijiria nigba naa, Abacha, fẹsun kan onkọwe ati ajafẹtọọ ayika, Ken Saro-Wiwa atawọn akẹgbẹ rẹ mẹjọ mii wi pe awọn lo ṣokunfa iku awọn oloye mẹrin naa.

Ken Saro-Wiwa atawọn akẹgbẹ rẹ lawọn o mọwọ mẹsẹ, ṣugbọn ijọba ologun Abacha ṣeku pa wọn lọdun 1995.

Iṣekupani Ken Saro-Wiwa atawọn akẹgbẹ rẹ yii fa nnkan ti ọpọ eeyan kaakiri agbaye koro oju si ijọba Naijiria le lori.

Nile iṣẹ ijọba l'Abuja ni Aarẹ Tinubu ti foye naa dawọn lọla l'Ọjọru, lẹyin ti igbimọ ti ijọba apapọ gbe dide lori ọrọ ilẹ Ogoni eyi ti Ọjọgbọn Don Baridam ṣe alaga rẹ jabọ fun aarẹ lori iṣẹ ti wọn ṣe.

Ṣaaju lọjọ kejila oṣu Kẹfa to kọja ni Aarẹ Tinubu ti kọkọ foye orilẹede Naijiria da Saro-Wiwa atawọn akẹgbẹ rẹ mẹjọ lọla lasiko ayẹyẹ ayajọ ijọba awarawa.

Igbesẹ aarẹ yii ko ṣẹyin ọna lati pari ija to wa laarin idile awọn oloye mẹrin yii ati ẹbi awọn Saro-Wiwa atawọn akẹgbẹ rẹ.

Ta a ni awọn oloye ilẹ Ogoni mẹrin ti Tinubu fi oye CON da lọla?

Edward Kobani

Akọsilẹ fi han wi pe Edward Kobani wa lara awọn igbimọ to buwọlu adehun idasilẹ ipinlẹ Rivers.

O tun fi igba kan ri jẹ akọwe agba ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni orilẹede Naijiria, NANS.

Igba meji ọtọọtọ ni a gbọ pe Oloye Kobani jẹ kọmiṣonna ni ipinlẹ Rivers.

Oloye Konani tun jẹ alakoso agba igbimọ to ṣe ipolongo ibo fun MKO Abiola fun ibo aarẹ ọdun 1993.

Oun tun ni igbakeji akọkọ ẹgbẹ MOSOP nigba aye rẹ.

Iroyin sọ pe baba isalẹ ni Oloye Kobani jẹ fun ọpọ olosẹlu nipinlẹ Rivers, bakan naa lo si gba ọpọ eeyan si iṣẹ ijọba.

Lọjọ kọkanlelogun oṣu Karun un ni wọn ṣeku pa a ni Giokoo, lẹkun Gokana.

Albert Bade

Suage Bade to jẹ ọmọ Albert Bade sọ pe ọmọ ijọ Methodist ni Albert i ṣe nigba aye rẹ.

Suage ni baba oun fakọyọ ninu idanwo ile ẹkọ giga to ṣe lọdun 1958, eyi lo si fun un lanfaani lati gba eto ẹkọ ọfẹ lati lọ kẹkọọ ni fasiti Cambridge ni UK.

''Baba mi fẹran iyawo rẹ, mama mi gan an, o si ṣe itọju ẹbi rẹ daadaa.

Bo tilẹ jẹ pe baba nifẹ ẹbi rẹ, ko gba igba kugba rara.

Ko le ṣe ki o maa gbadura owurọ pẹlu idile rẹ laago mẹfa aarọ lojoojumọ,'' Suage lo sọ bẹẹ.

Albert kii fi akoko ṣere rara, Suage ọmọ rẹ ni ago meje abọ geerege lo maa n de ọfiisi rẹ nigba to fi wa nipo akọwe agba ileeṣẹ ijọba ati lasiko to jẹ kọniṣona nipinlẹ Rivers.

Albert tun ti di ipo akọwe ijọba ipinlẹ Rivers, olori awọn oṣiṣẹ mu ri, bakan naa lo tun jẹ adele alaga ẹgbẹ oṣelu NRC ri nipinlẹ Rivers.

Theophilus ati Samuel Orage

Theophilus ati Samuel Orage wa lara awọn oloye Ogoni mẹrin ti wọn pa ni ifana-fanṣu nilẹ Ogoni lọjọ kọkanlelogun oṣu Karun un ọdun 1994.

Awọn eeyan yii ni wọn n ja fun ẹtọ ati aabo ilẹ wọn wọn latari bi epo rọbi ti ileeṣẹ Shell n wa lori ilẹ wọn ṣe n ṣakoba fawọn eeyan wọn.

Lọsan an gangan ni iroyin fidi rẹ mulẹ pe wọn ṣeku pa awọn mejeeji yii lagbegbe Gokana ni ọdun mọkanlelọgbọn sẹyin bayii.

Ẹwẹ, ọpọ eeyan lati ilẹ Ogoni lo ti fi idunnu wọn si Aarẹ Tinubu lẹyin ti o fi ami ẹyẹ dawọn lọla lati ṣe iranti wọn.

Lọdun 1958 ni wọn ṣawari epo rọbi ni Oloibiri nilẹ Ogoni.

Amọ, lati ọdun 1993 ni ijọba ko ti wa epo mọ nibẹ lẹyin tawọn eeyan ilẹ Ogoni ṣe ifẹhonuhan tako bi ilẹ ati ayika wọn ṣe n bajẹ latari epo rọbi ti wọn n wa nibẹ.

Aarẹ Tinubu ti wa paṣẹ bayii wi pe ki ijọba bẹrẹ epo wiwa pada nibẹ, nigba to sọ fun oludamọran aarẹ lori eto aabo, Nuhu Ribadu ati ileeṣẹ NNPC lati tẹsiwaju pẹlu asọyepọ to n lọ lọwọ pẹlu awọn eeyan ilẹ Ogoni.